Kur'an-ı Kerim meal tercümesi - Yorba Dilinde Kur'an-ı Kerim Meali * - Mealler fihristi

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Anlam tercümesi Ayet: (15) Sure: Sûretu'l-Feth
سَيَقُولُ ٱلۡمُخَلَّفُونَ إِذَا ٱنطَلَقۡتُمۡ إِلَىٰ مَغَانِمَ لِتَأۡخُذُوهَا ذَرُونَا نَتَّبِعۡكُمۡۖ يُرِيدُونَ أَن يُبَدِّلُواْ كَلَٰمَ ٱللَّهِۚ قُل لَّن تَتَّبِعُونَا كَذَٰلِكُمۡ قَالَ ٱللَّهُ مِن قَبۡلُۖ فَسَيَقُولُونَ بَلۡ تَحۡسُدُونَنَاۚ بَلۡ كَانُواْ لَا يَفۡقَهُونَ إِلَّا قَلِيلٗا
Àwọn olùsásẹ́yìn fún ogun (Hudaebiyyah) ń wí pé: “Nígbà tí ẹ bá ń lọ síbi ọrọ̀-ogun (Kọebar) nítorí kí ẹ lè rí i kó, ẹ fi wá sílẹ̀ kí á lè tẹ̀lé yín lọ.” (Àwọn olùsásẹ́yìn wọ̀nyí) sì ń gbèrò láti yí ọ̀rọ̀ Allāhu padà ni. (Ìwọ Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -) sọ (fún àwọn olùsásẹ́yìn fún ogun Hudaebiyyah) pé: “Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ tẹ̀lé wa. Báyẹn ni Allāhu ṣe sọ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀.” Àwọn olùsásẹ́yìn náà sì ń wí pé: “Rárá (kò rí bẹ́ẹ̀), ẹ̀ ń ṣe kèéta wa ni.”² Rárá (ẹ̀yin kò ṣe kèéta wọn, àmọ́), wọ́n kì í gbọ́ àgbọ́yé (ọ̀rọ̀) àfi díẹ̀.
1. Ẹ wo bí àwọn olùsásẹ́yìn, àwọn munāfiki ṣe ń fi ẹ̀sùn burúkú kan Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo. Wọ́n ní wọ́n ń ṣe kèéta àwọn ni! Ṣé ó sì rọrùn fún Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - láti ṣe kèéta àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, ẹni tí Allāhu fi ìwà tó ga jùlọ ròyìn? Ìbẹ̀rẹ̀ orí burúkú ni fún ẹ̀dá kan nígbà náà láti fi ẹ̀sùn kan Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -.
Arapça tefsirler:
 
Anlam tercümesi Ayet: (15) Sure: Sûretu'l-Feth
Surelerin fihristi Sayfa numarası
 
Kur'an-ı Kerim meal tercümesi - Yorba Dilinde Kur'an-ı Kerim Meali - Mealler fihristi

Yorba Dilinde Kur'an-ı Kerim Meali- Tercüme Şeyh Ebu Rahime Mikail İykuviyni, Basım Yılı hicri 1432.

Kapat