ترجمهٔ معانی قرآن کریم - ترجمه ى یوروبایی * - لیست ترجمه ها

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

ترجمهٔ معانی آیه: (15) سوره: سوره فتح
سَيَقُولُ ٱلۡمُخَلَّفُونَ إِذَا ٱنطَلَقۡتُمۡ إِلَىٰ مَغَانِمَ لِتَأۡخُذُوهَا ذَرُونَا نَتَّبِعۡكُمۡۖ يُرِيدُونَ أَن يُبَدِّلُواْ كَلَٰمَ ٱللَّهِۚ قُل لَّن تَتَّبِعُونَا كَذَٰلِكُمۡ قَالَ ٱللَّهُ مِن قَبۡلُۖ فَسَيَقُولُونَ بَلۡ تَحۡسُدُونَنَاۚ بَلۡ كَانُواْ لَا يَفۡقَهُونَ إِلَّا قَلِيلٗا
Àwọn olùsásẹ́yìn fún ogun (Hudaebiyyah) ń wí pé: “Nígbà tí ẹ bá ń lọ síbi ọrọ̀-ogun (Kọebar) nítorí kí ẹ lè rí i kó, ẹ fi wá sílẹ̀ kí á lè tẹ̀lé yín lọ.” (Àwọn olùsásẹ́yìn wọ̀nyí) sì ń gbèrò láti yí ọ̀rọ̀ Allāhu padà ni.¹ (Ìwọ Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -) sọ (fún àwọn olùsásẹ́yìn fún ogun Hudaebiyyah) pé: “Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ tẹ̀lé wa. Báyẹn ni Allāhu ṣe sọ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀.” Àwọn olùsásẹ́yìn náà sì ń wí pé: “Rárá (kò rí bẹ́ẹ̀), ẹ̀ ń ṣe kèéta wa ni.”² Rárá (ẹ̀yin kò ṣe kèéta wọn, àmọ́), wọ́n kì í gbọ́ àgbọ́yé (ọ̀rọ̀) àfi díẹ̀.
1. Ohun tí Allāhu sọ fún Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ni pé, ọ̀wọ́ àwọn tí wọ́n bá dìjọ lọ sí ogun Sulhul-Hudaebaiyyah nìkan ni kí wọ́n dìjọ lọ sí ogun Kọebar. Àmọ́ àwọn munāfiki wọ̀nyí sá sẹ́yìn fún ogun Sulhul-Hudaebaiyyah, wọ́n sì fẹ́ lọ sí ogun Kọebar nítorí pé, wọ́n ti ní àfojúsùn sí ọrọ̀ ogun nìkan. Ọ̀rọ̀ wọn dà bí ọ̀rọ̀ ẹni tí ó gbọ́ gùnyà-gúnyán, tí ó bẹ́ sájà pì. Àmọ́ ó gbọ́ mùyàn-múyán, tí ó bẹ́ sílẹ̀ pì.
2. Ẹ wo bí àwọn olùsásẹ́yìn, àwọn munāfiki ṣe ń fi ẹ̀sùn burúkú kan Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo. Wọ́n ní wọ́n ń ṣe kèéta àwọn ni! Ṣé ó sì rọrùn fún Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - láti ṣe kèéta àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, ẹni tí Allāhu fi ìwà tó ga jùlọ ròyìn? Ìbẹ̀rẹ̀ orí burúkú ni fún ẹ̀dá kan nígbà náà láti fi ẹ̀sùn kan Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -.
تفسیرهای عربی:
 
ترجمهٔ معانی آیه: (15) سوره: سوره فتح
فهرست سوره ها شماره صفحه
 
ترجمهٔ معانی قرآن کریم - ترجمه ى یوروبایی - لیست ترجمه ها

ترجمه ى معانی قرآن کریم به زبان یوروبایی. مترجم: شیخ ابو رحیمه میکائیل ایکوینی. سال چاپ: 1432هجرى قمرى.

بستن