Kur'an-ı Kerim meal tercümesi - Yorba Dilinde Kur'an-ı Kerim Meali * - Mealler fihristi

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Anlam tercümesi Sure: Sûretu'l-Hakkâh   Ayet:

Suuratul-Haaqqah

ٱلۡحَآقَّةُ
Ìṣẹ̀lẹ̀ Òdodo náà!
Arapça tefsirler:
مَا ٱلۡحَآقَّةُ
Kí ni Ìṣẹ̀lẹ̀ Òdodo náà?
Arapça tefsirler:
وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا ٱلۡحَآقَّةُ
Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Ìṣẹ̀lẹ̀ Òdodo náà?
Arapça tefsirler:
كَذَّبَتۡ ثَمُودُ وَعَادُۢ بِٱلۡقَارِعَةِ
Àwọn ìjọ Thamūd àti ìjọ ‘Ād pe Àjíǹde (ajámọláya bí àrá) ní irọ́.¹
1. Nínú àwọn orúkọ fún Ọjọ́ Àjíǹde ni Ìṣẹ̀lẹ̀ Òdodo náà àti Ajámọláyà bí àrá.
Arapça tefsirler:
فَأَمَّا ثَمُودُ فَأُهۡلِكُواْ بِٱلطَّاغِيَةِ
Ní ti ìjọ Thamūd, wọ́n fi igbe tó tayọ ẹnu-ààlà pa wọ́n rẹ́.
Arapça tefsirler:
وَأَمَّا عَادٞ فَأُهۡلِكُواْ بِرِيحٖ صَرۡصَرٍ عَاتِيَةٖ
Ní ti ìjọ ‘Ād, wọ́n fi atẹ́gùn líle tó tayọ ẹnu-ààlà pa wọ́n rẹ́.
Arapça tefsirler:
سَخَّرَهَا عَلَيۡهِمۡ سَبۡعَ لَيَالٖ وَثَمَٰنِيَةَ أَيَّامٍ حُسُومٗاۖ فَتَرَى ٱلۡقَوۡمَ فِيهَا صَرۡعَىٰ كَأَنَّهُمۡ أَعۡجَازُ نَخۡلٍ خَاوِيَةٖ
Ó dẹ ẹ́ sí wọn fún òru méje àti ọ̀sán mẹ́jọ láì dáwọ́ dúró. O sì máa rí ìjọ náà tí wọ́n ti kú sínú rẹ̀ bí ẹni pé kùkùté igi dàbínù tó ti luhò nínú ni wọ́n.¹
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah Fussilat; 41:16.
Arapça tefsirler:
فَهَلۡ تَرَىٰ لَهُم مِّنۢ بَاقِيَةٖ
Ǹjẹ́ o rí ẹnì kan nínú wọn tó ṣẹ́ kù bí?
Arapça tefsirler:
وَجَآءَ فِرۡعَوۡنُ وَمَن قَبۡلَهُۥ وَٱلۡمُؤۡتَفِكَٰتُ بِٱلۡخَاطِئَةِ
Fir‘aon àti àwọn tó ṣíwájú rẹ̀ àti àwọn ìlú tí wọ́n dojú rẹ̀ bolẹ̀ dé pẹ̀lú àwọn àṣìṣe.
Arapça tefsirler:
فَعَصَوۡاْ رَسُولَ رَبِّهِمۡ فَأَخَذَهُمۡ أَخۡذَةٗ رَّابِيَةً
Wọ́n yapa Òjíṣẹ́ Olúwa wọn. Ó sì gbá wọn mú ní ìgbámú tóléken̄kà.
Arapça tefsirler:
إِنَّا لَمَّا طَغَا ٱلۡمَآءُ حَمَلۡنَٰكُمۡ فِي ٱلۡجَارِيَةِ
Dájúdájú nígbà tí omi tayọ ẹnu-ààlà. A gbe yín gun ọkọ̀ ojú-omi.
Arapça tefsirler:
لِنَجۡعَلَهَا لَكُمۡ تَذۡكِرَةٗ وَتَعِيَهَآ أُذُنٞ وَٰعِيَةٞ
Nítorí kí Á lè fi ṣe ìrántí fún yín àti nítorí kí etí tó ń ṣọ́ n̄ǹkan lè ṣọ́ ọ.
Arapça tefsirler:
فَإِذَا نُفِخَ فِي ٱلصُّورِ نَفۡخَةٞ وَٰحِدَةٞ
Nígbà tí wọ́n bá fọn fèrè oníwo fún ikú ní fífọn ẹyọ kan,
Arapça tefsirler:
وَحُمِلَتِ ٱلۡأَرۡضُ وَٱلۡجِبَالُ فَدُكَّتَا دَكَّةٗ وَٰحِدَةٗ
tí wọ́n gbé ilẹ̀ àti àpáta sókè, tí wọ́n sì rún méjèèjì wómúwómú ní rírún ẹ̀ẹ̀ kan,
Arapça tefsirler:
فَيَوۡمَئِذٖ وَقَعَتِ ٱلۡوَاقِعَةُ
ní ọjọ́ yẹn ni Ìṣẹ̀lẹ̀ máa ṣẹlẹ̀.
Arapça tefsirler:
وَٱنشَقَّتِ ٱلسَّمَآءُ فَهِيَ يَوۡمَئِذٖ وَاهِيَةٞ
Àti pé sánmọ̀ yó fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ. Ó sì máa fúyẹ́ gẹgẹ ní ọjọ́ yẹn.
Arapça tefsirler:
وَٱلۡمَلَكُ عَلَىٰٓ أَرۡجَآئِهَاۚ وَيَحۡمِلُ عَرۡشَ رَبِّكَ فَوۡقَهُمۡ يَوۡمَئِذٖ ثَمَٰنِيَةٞ
Àwọn mọlāika sì máa wà ní àwọn ẹ̀gbẹ́ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Àti pé ní ọjọ́ yẹn, lókè wọn, àwọn (mọlāika) mẹ́jọ ni wọ́n máa ru Ìtẹ́ Olúwa rẹ.
Arapça tefsirler:
يَوۡمَئِذٖ تُعۡرَضُونَ لَا تَخۡفَىٰ مِنكُمۡ خَافِيَةٞ
Ní ọjọ́ yẹn, wọn yóò máa ṣẹ́rí yín wá (fún ìṣírò-iṣẹ́). Kò sì níí sí àṣírí yín kan tó máa pamọ́ (fún Wa).
Arapça tefsirler:
فَأَمَّا مَنۡ أُوتِيَ كِتَٰبَهُۥ بِيَمِينِهِۦ فَيَقُولُ هَآؤُمُ ٱقۡرَءُواْ كِتَٰبِيَهۡ
Nítorí náà, ní ti ẹni tí wọ́n bá fún ní tírà rẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ó máa sọ pé: “Ẹ gbà, ẹ ka tírà mi wò.
Arapça tefsirler:
إِنِّي ظَنَنتُ أَنِّي مُلَٰقٍ حِسَابِيَهۡ
Dájúdájú èmi ti mọ àmọ̀dájú pé dájúdájú èmi yóò bá ìṣírò-iṣẹ́ mi pàdé.”
Arapça tefsirler:
فَهُوَ فِي عِيشَةٖ رَّاضِيَةٖ
Nítorí náà, ó máa wà nínú ìṣẹ̀mí tó máa yọ́nú sí
Arapça tefsirler:
فِي جَنَّةٍ عَالِيَةٖ
nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra gíga.
Arapça tefsirler:
قُطُوفُهَا دَانِيَةٞ
Àwọn èso rẹ̀ (sì) máa wà ní àrọ́wọ́tó.
Arapça tefsirler:
كُلُواْ وَٱشۡرَبُواْ هَنِيٓـَٔۢا بِمَآ أَسۡلَفۡتُمۡ فِي ٱلۡأَيَّامِ ٱلۡخَالِيَةِ
Ẹ jẹ, kí ẹ sì mu pẹ̀lú ìgbàdún nítorí ohun tí ẹ tì síwájú nínú àwọn ọjọ́ tí ó ti ré kọjá.
Arapça tefsirler:
وَأَمَّا مَنۡ أُوتِيَ كِتَٰبَهُۥ بِشِمَالِهِۦ فَيَقُولُ يَٰلَيۡتَنِي لَمۡ أُوتَ كِتَٰبِيَهۡ
Ní ti ẹni tí wọ́n bá sì fún ní tírà rẹ̀ ní ọwọ́ òsì rẹ̀, ó máa wí pé: “Háà! Kí wọ́n sì má fún mi ni tírà mi!¹
1. Àwọn nasọ̄rọ̄ sọ pé, “Āyah yìí ń sọ pé ọwọ́ òsì ni àwọn aláìgbàgbọ́ máa fi gba ìwé iṣẹ́ wọn, àmọ́ sūrah al-’Inṣiƙọ̄ƙ; 84:10 ń sọ pé láti ẹ̀yìn ni wọ́n máa ti gbà á.” Wọ́n ní, “Ìtakora nìyẹn!”
Èsì: Ìtakora tófẹ́jọbẹ́ẹ̀ ni, kì í ṣe ìtakora tóríbẹ́ẹ̀. Àlàyé rẹ̀ nìyí, méjéèjì ló máa ṣẹlẹ̀ sí wọn nítorí pé, ọwọ́ òsì ni aláìgbàgbọ́ máa tì bọ inú igbá-àyà rẹ̀ bọ́ sí ẹ̀yìn rẹ̀ láti fi gba ìwé iṣẹ́ rẹ̀.
Arapça tefsirler:
وَلَمۡ أَدۡرِ مَا حِسَابِيَهۡ
Àti pé kí èmi sì má mọ ohun tí ìṣírò-iṣẹ́ mi jẹ́.
Arapça tefsirler:
يَٰلَيۡتَهَا كَانَتِ ٱلۡقَاضِيَةَ
Háà! Kí ikú sì jẹ́ òpin (ọ̀rọ̀ ẹ̀dá).
Arapça tefsirler:
مَآ أَغۡنَىٰ عَنِّي مَالِيَهۡۜ
Dúkìá mi kò sì rọ̀ mí lọ́rọ̀.
Arapça tefsirler:
هَلَكَ عَنِّي سُلۡطَٰنِيَهۡ
Agbára mi sì ti parun.”
Arapça tefsirler:
خُذُوهُ فَغُلُّوهُ
Ẹ mú un, kí ẹ dè é ní ọwọ́ mọ́ ọrùn.
Arapça tefsirler:
ثُمَّ ٱلۡجَحِيمَ صَلُّوهُ
Lẹ́yìn náà, inú iná Jẹhīm ni kí ẹ mú un wọ̀.
Arapça tefsirler:
ثُمَّ فِي سِلۡسِلَةٖ ذَرۡعُهَا سَبۡعُونَ ذِرَاعٗا فَٱسۡلُكُوهُ
Lẹ́yìn náà, inú ẹ̀wọ̀n tí gígùn rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin gígùn thar‘u¹ ni kí ẹ kì í sí.
1. Gígùn “Thar‘u” kan ni gígùn láti ìlú Mọkkah sí ibi tí ó jìnnà jùlọ sí ìlú Mọkkah.
Arapça tefsirler:
إِنَّهُۥ كَانَ لَا يُؤۡمِنُ بِٱللَّهِ ٱلۡعَظِيمِ
Dájúdájú òun kì í gbàgbọ́ nínú Allāhu, Atóbi.
Arapça tefsirler:
وَلَا يَحُضُّ عَلَىٰ طَعَامِ ٱلۡمِسۡكِينِ
Kì í sì gba ènìyàn níyànjú láti bọ́ àwọn mẹ̀kúnnù.
Arapça tefsirler:
فَلَيۡسَ لَهُ ٱلۡيَوۡمَ هَٰهُنَا حَمِيمٞ
Nítorí náà, kò níí sí ọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ kan fún un níbí yìí ní òní.
Arapça tefsirler:
وَلَا طَعَامٌ إِلَّا مِنۡ غِسۡلِينٖ
Kò sì níí sí oúnjẹ kan (fún un) bí kò ṣe (oúnjẹ) àwọnúwẹ̀jẹ̀.
Arapça tefsirler:
لَّا يَأۡكُلُهُۥٓ إِلَّا ٱلۡخَٰطِـُٔونَ
Kò sí ẹni tí ó máa jẹ ẹ́ bí kò ṣe àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.
Arapça tefsirler:
فَلَآ أُقۡسِمُ بِمَا تُبۡصِرُونَ
Nítorí náà, Èmi ń fi ohun tí ẹ̀ ń fojú rí búra
Arapça tefsirler:
وَمَا لَا تُبۡصِرُونَ
àti ohun tí ẹ ò fojú rí.
Arapça tefsirler:
إِنَّهُۥ لَقَوۡلُ رَسُولٖ كَرِيمٖ
Dájúdájú al-Ƙur’ān ni ọ̀rọ̀ (tí A fi rán) Òjíṣẹ́, alápọ̀n-ọ́nlé.¹
1. “Ọ̀rọ̀ òjíṣẹ́” ni ìtúmọ̀ “ƙọolu rọsūl, àmọ́ al-Ƙur’ān kì í ṣe ọ̀rọ̀ Òjíṣẹ́ bí kò ṣe “Ọ̀rọ̀ Allāhu”. Àgbékalẹ̀ irúfẹ́ ọ̀rọ̀ yìí ni ṣíṣe àfitì ọ̀rọ̀ sí ọ̀dọ̀ alágbàsọ. Bákan náà, āyah yìí jọ āyah 19 nínú sūrah at-Tẹkwīr ní ìsọ, àmọ “Òjíṣẹ́” tí wọ́n gbàlérò nínú āyah ti sūrah al-Hāƙƙọh ni Òjíṣẹ́ abara, ìyẹn Ànábì wa Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -, Òjíṣẹ́ mọlāika ni wọ́n sì gbàlérò nínú āyah ti sūrah at-Tẹkwīr. Sàkánì ti ìkọ̀ọ̀kan ti jẹyọ l’ó ṣàfi hàn èyí bẹ́ẹ̀.
Arapça tefsirler:
وَمَا هُوَ بِقَوۡلِ شَاعِرٖۚ قَلِيلٗا مَّا تُؤۡمِنُونَ
Kì í ṣe ọ̀rọ̀ eléwì. Ohun tí ẹ gbàgbọ́ kéré púpọ̀.
Arapça tefsirler:
وَلَا بِقَوۡلِ كَاهِنٖۚ قَلِيلٗا مَّا تَذَكَّرُونَ
Kì í sì ṣe ọ̀rọ̀ adábigba. Díẹ̀ lẹ̀ ń lò nínú ìrántí.
Arapça tefsirler:
تَنزِيلٞ مِّن رَّبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ
Wọ́n sọ̀ ọ́ kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
Arapça tefsirler:
وَلَوۡ تَقَوَّلَ عَلَيۡنَا بَعۡضَ ٱلۡأَقَاوِيلِ
Tí ó bá jẹ́ pé (Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ) dá àdápa apá kan ọ̀rọ̀ náà mọ́ Wa ni,
Arapça tefsirler:
لَأَخَذۡنَا مِنۡهُ بِٱلۡيَمِينِ
Àwa ìbá gbá a mú lọ́wọ́ ọ̀tún.
Arapça tefsirler:
ثُمَّ لَقَطَعۡنَا مِنۡهُ ٱلۡوَتِينَ
Lẹ́yìn náà, Àwa ìbá já isan ọrùn rẹ̀.
Arapça tefsirler:
فَمَا مِنكُم مِّنۡ أَحَدٍ عَنۡهُ حَٰجِزِينَ
Kò sì sí ẹnì kan nínú yín tí ó máa gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ (Wa).
Arapça tefsirler:
وَإِنَّهُۥ لَتَذۡكِرَةٞ لِّلۡمُتَّقِينَ
Dájúdájú (al-Ƙur’ān) ni ìrántí fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu).
Arapça tefsirler:
وَإِنَّا لَنَعۡلَمُ أَنَّ مِنكُم مُّكَذِّبِينَ
Dájúdájú Àwa sì mọ̀ pé àwọn tó ń pe al-Ƙur’ān ní irọ́ wà nínú yín.
Arapça tefsirler:
وَإِنَّهُۥ لَحَسۡرَةٌ عَلَى ٱلۡكَٰفِرِينَ
Dájúdájú al-Ƙur’ān máa jẹ́ àbámọ̀ ńlá fún àwọn aláìgbàgbọ́.
Arapça tefsirler:
وَإِنَّهُۥ لَحَقُّ ٱلۡيَقِينِ
Dájúdájú al-Ƙur’ān ni òdodo tó dájú.
Arapça tefsirler:
فَسَبِّحۡ بِٱسۡمِ رَبِّكَ ٱلۡعَظِيمِ
Nítorí náà, ṣàfọ̀mọ́ fún orúkọ Olúwa Rẹ, Atóbi.
Arapça tefsirler:
 
Anlam tercümesi Sure: Sûretu'l-Hakkâh
Surelerin fihristi Sayfa numarası
 
Kur'an-ı Kerim meal tercümesi - Yorba Dilinde Kur'an-ı Kerim Meali - Mealler fihristi

Yorba Dilinde Kur'an-ı Kerim Meali- Tercüme Şeyh Ebu Rahime Mikail İykuviyni, Basım Yılı hicri 1432.

Kapat