قرآن کریم کے معانی کا ترجمہ - یوروبا ترجمہ * - ترجمے کی لسٹ

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

معانی کا ترجمہ آیت: (105) سورت: سورۂ اِسراء
وَبِٱلۡحَقِّ أَنزَلۡنَٰهُ وَبِٱلۡحَقِّ نَزَلَۗ وَمَآ أَرۡسَلۡنَٰكَ إِلَّا مُبَشِّرٗا وَنَذِيرٗا
A sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ pẹ̀lú òdodo. Ó sì sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú òdodo. A kò sì rán ọ níṣẹ́ bí kò ṣe pé (kí o jẹ́) oníròó-ìdùnnú àti olùkìlọ̀.¹
1. Ànábì wa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ni oníròó-ìdùnnú fún èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra, òun náà sì ni olùkìlọ̀ fún èrò inú Iná. Jíjẹ́ tí Ànábì wa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - jẹ́ oníròó-ìdùnnú túmọ̀ sí pé láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni a óò ti máa gbọ́ ìró nípa ìjọ́sìn, ìwà dáradára àti ọ̀nà ìṣẹ̀mí tí a óò fi rí Ọgbà Ìdẹ̀ra wọ̀. Àti pé lára ìró ìdùnnú tí A óò máa gbọ́ láti ọ̀dọ̀ Ànábì ni òdíwọ̀n ẹ̀san tí a lè rí gbà lórí àwọn iṣẹ́ Ọgbà Ìdẹ̀ra. Ní ìdà kejì ẹ̀wẹ̀, jíjẹ́ tí Ànábì wa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - jẹ́ olùkìlọ̀ túmọ̀ sí pé, láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni a óò ti máa gbọ́ ìkìlọ̀ lórí àwọn n̄ǹkan tí ó lè múni wọ inú Iná. Àti pé lára ìkìlọ̀ tí A óò máa gbọ́ láti ọ̀dọ̀ Ànábì ni òdíwọ̀n àti irú ìyà tí ẹ̀dá lè rí lórí àwọn iṣẹ́ Iná. Al-Ƙur’ān àti Hadīth Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ni orísun fún ìmọ̀ nípa ìró-ìdùnnú àti ìkìlọ̀. Nítorí náà, ọ̀kan nínú àwọn abẹ̀sìnjẹ́ (ohun tó ń ba ẹ̀sìn jẹ́) mọ́ mùsùlùmí lọ́wọ́ ni kí ẹlòmíìràn nínú ìjọ rẹ̀ sọra rẹ̀ di oníròó-ìdùnnú àti olùkìlọ̀ nítorí pé, onítọ̀ún ti sọra rẹ̀ di arímìísígbà. Ìmísí sánmọ̀ sì ti dòpin.
عربی تفاسیر:
 
معانی کا ترجمہ آیت: (105) سورت: سورۂ اِسراء
سورتوں کی لسٹ صفحہ نمبر
 
قرآن کریم کے معانی کا ترجمہ - یوروبا ترجمہ - ترجمے کی لسٹ

قرآن کریم کے معانی کا یوروبا ترجمہ۔ ترجمہ شیخ ابو رحیمہ میکائیل ایکویینی نے کیا ہے۔ طباعت سنہ 1432ھ۔

بند کریں