Қуръони Карим маъноларининг таржимаси - Йўрубача таржима * - Таржималар мундарижаси

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Маънолар таржимаси Оят: (114) Сура: Анъом сураси
أَفَغَيۡرَ ٱللَّهِ أَبۡتَغِي حَكَمٗا وَهُوَ ٱلَّذِيٓ أَنزَلَ إِلَيۡكُمُ ٱلۡكِتَٰبَ مُفَصَّلٗاۚ وَٱلَّذِينَ ءَاتَيۡنَٰهُمُ ٱلۡكِتَٰبَ يَعۡلَمُونَ أَنَّهُۥ مُنَزَّلٞ مِّن رَّبِّكَ بِٱلۡحَقِّۖ فَلَا تَكُونَنَّ مِنَ ٱلۡمُمۡتَرِينَ
Ṣé n̄ǹkan mìíràn ni kí n̄g wá ní olùdájọ́ lẹ́yìn Allāhu ni? Òun sì ni Ẹni tí Ó sọ Tírà kalẹ̀ fún yín tí wọ́n fi ṣàlàyé ìdájọ́.¹ Àwọn tí A sì fún ní tírà mọ̀ pé, dájúdájú wọ́n sọ̀ ọ́ kalẹ̀ pẹ̀lú òdodo láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Nítorí náà, o ò gbọdọ̀ wà lára àwọn oníyèméjì.
1. Irú gbólóhùn yìí wà nínú sūrah Yūsuf; 12:111 àti sūrah an-Nahl; 16:89. Wàyí, àwọn n̄nkan titun titun àti àwọn n̄ǹkan ìgbàlódé tó ń ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn al-Ƙur’ān, tí Allāhu kò sì sọ̀rọ̀ nípa wọn ńkọ́? Kíyè sí i, al-Ƙur’ān dúró fún òṣùwọ̀n (fọ́múlà) àti ìdájọ́ tí a ó fi máa ṣe ìyàtọ̀ láààrin ìmọ̀ àti ìròrí, ohun rere àti aburú, ẹ̀tọ́ àti èèwọ̀, ìjọ́sìn àti ìranù, ìtẹ̀lé àṣẹ àti ìyapa àṣẹ, iṣẹ́ Ọgbà Ìdẹ̀ra àti iṣẹ́ Iná. Sunnah Ànábì wa Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - sì dúró fún àlàyé al-Ƙur’ān.
Арабча тафсирлар:
 
Маънолар таржимаси Оят: (114) Сура: Анъом сураси
Суралар мундарижаси Бет рақами
 
Қуръони Карим маъноларининг таржимаси - Йўрубача таржима - Таржималар мундарижаси

Қуръон Карим маъноларининг йўрубача таржимаси. Мутаржим: шайх Абу Раҳима Микоил Айквайний, 1432 ҳ. йили нашрдан чиққан.

Ёпиш