للإطلاع على الموقع بحلته الجديدة

ترجمة معاني القرآن الكريم - الترجمة اليورباوية - أبو رحيمة ميكائيل * - فهرس التراجم

PDF XML CSV Excel API
تنزيل الملفات يتضمن الموافقة على هذه الشروط والسياسات

ترجمة معاني سورة: الإسراء   آية:
وَإِمَّا تُعۡرِضَنَّ عَنۡهُمُ ٱبۡتِغَآءَ رَحۡمَةٖ مِّن رَّبِّكَ تَرۡجُوهَا فَقُل لَّهُمۡ قَوۡلٗا مَّيۡسُورٗا
Tí o bá ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ wọn (ìyẹn àwọn aláìní) láti wá ìkẹ́ kan tí ò ń retí láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ, bá wọn sọ ọ̀rọ̀ ẹ̀lẹ̀.
التفاسير العربية:
وَلَا تَجۡعَلۡ يَدَكَ مَغۡلُولَةً إِلَىٰ عُنُقِكَ وَلَا تَبۡسُطۡهَا كُلَّ ٱلۡبَسۡطِ فَتَقۡعُدَ مَلُومٗا مَّحۡسُورًا
Má di ọwọ́ rẹ mọ́ ọrùn rẹ (má ya ahun), má sì tẹ́ ẹ sílẹ̀ tán pátápátá (má ya àpà), kí o má baà jókòó kalẹ̀ ní ẹni èébú (tí o bá jẹ́ ahun), ẹni tí kò níí sí lọ́wọ́ rẹ̀ mọ́ (tí o bá jẹ́ àpà).
التفاسير العربية:
إِنَّ رَبَّكَ يَبۡسُطُ ٱلرِّزۡقَ لِمَن يَشَآءُ وَيَقۡدِرُۚ إِنَّهُۥ كَانَ بِعِبَادِهِۦ خَبِيرَۢا بَصِيرٗا
Dájúdájú Olúwa rẹ l’Ó ń tẹ́ arísìkí sílẹ̀ fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Ó sì ń díwọ̀n rẹ̀ (fún ẹlòmíìràn). Dájúdájú Ó ń jẹ́ Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀, Olùríran nípa àwọn ẹrúsìn Rẹ̀.
التفاسير العربية:
وَلَا تَقۡتُلُوٓاْ أَوۡلَٰدَكُمۡ خَشۡيَةَ إِمۡلَٰقٖۖ نَّحۡنُ نَرۡزُقُهُمۡ وَإِيَّاكُمۡۚ إِنَّ قَتۡلَهُمۡ كَانَ خِطۡـٔٗا كَبِيرٗا
Ẹ má pa àwọn ọmọ yín nítorí ìpáyà òṣì. Àwa l’À ń pèsè fún àwọn àti ẹ̀yin. Dájúdájú pípa wọ́n jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tó tóbi.
التفاسير العربية:
وَلَا تَقۡرَبُواْ ٱلزِّنَىٰٓۖ إِنَّهُۥ كَانَ فَٰحِشَةٗ وَسَآءَ سَبِيلٗا
Ẹ má ṣe súnmọ́ àgbèrè. Dájúdájú ó jẹ́ ìwà burúkú. Ó sì burú ní ojú ọ̀nà.
التفاسير العربية:
وَلَا تَقۡتُلُواْ ٱلنَّفۡسَ ٱلَّتِي حَرَّمَ ٱللَّهُ إِلَّا بِٱلۡحَقِّۗ وَمَن قُتِلَ مَظۡلُومٗا فَقَدۡ جَعَلۡنَا لِوَلِيِّهِۦ سُلۡطَٰنٗا فَلَا يُسۡرِف فِّي ٱلۡقَتۡلِۖ إِنَّهُۥ كَانَ مَنصُورٗا
Ẹ má pa ẹ̀mí tí Allāhu ṣe (pípa rẹ̀) ní èèwọ̀ àyàfi ní ọ̀nà ẹ̀tọ́.[1] Ẹni tí wọ́n bá pa ní ìpa àbòsí, dájúdájú A ti fún alámòjúútó rẹ̀ ní agbára (láti gbẹ̀san). Nítorí náà, kí ẹnikẹ́ni má ṣe tayọ ẹnu-ààlà níbi ìpànìyàn (nítorí pé) dájúdájú A máa ran (ẹbí òkú) lọ́wọ́ (láti gbẹ̀san).[2]
[1] Àwọn ọ̀nà ẹ̀tọ́ tí ó lè mú kí ìjọba ’Islām pa ènìyàn ni kí ènìyàn jẹ̀bi ẹ̀sùn àgbèrè lẹ́yìn tí onítọ̀ún ti ní ọkọ tàbí aya, ìpànìyàn lọ́nà àìtọ́ àti fífi ẹ̀sìn ’Islām sílẹ̀. [2] Ọ̀nà ìgbẹ̀san fún ẹ̀sùn ìpànìyàn wà nínú sūrah an-Nisā’; 4: 92-93 àti sūrah al-Mọ̄’idah; 5:45.
التفاسير العربية:
وَلَا تَقۡرَبُواْ مَالَ ٱلۡيَتِيمِ إِلَّا بِٱلَّتِي هِيَ أَحۡسَنُ حَتَّىٰ يَبۡلُغَ أَشُدَّهُۥۚ وَأَوۡفُواْ بِٱلۡعَهۡدِۖ إِنَّ ٱلۡعَهۡدَ كَانَ مَسۡـُٔولٗا
Ẹ má ṣe súnmọ́ dúkìá ọmọ òrukàn, àyàfi ní ọ̀nà tó dára jùlọ, títí ó fi máa dàgbà dáadáa. Kí ẹ sì mú àdéhùn ṣẹ. Dájúdájú àdéhùn jẹ́ ohun tí A ó bèèrè nípa rẹ̀.
التفاسير العربية:
وَأَوۡفُواْ ٱلۡكَيۡلَ إِذَا كِلۡتُمۡ وَزِنُواْ بِٱلۡقِسۡطَاسِ ٱلۡمُسۡتَقِيمِۚ ذَٰلِكَ خَيۡرٞ وَأَحۡسَنُ تَأۡوِيلٗا
Ẹ wọn òṣùwọ̀n kún nígbà tí ẹ bá wọ̀n ọ́n. Ẹ fi ìwọ̀n tó tọ́[1] wọ̀n ọ́n. Ìyẹn lóore jùlọ, ó sì dára jùlọ ní ìkángun.
[1] Ìyẹn òṣùwọ̀n tí kò tẹ̀ tí kò wọ́.
التفاسير العربية:
وَلَا تَقۡفُ مَا لَيۡسَ لَكَ بِهِۦ عِلۡمٌۚ إِنَّ ٱلسَّمۡعَ وَٱلۡبَصَرَ وَٱلۡفُؤَادَ كُلُّ أُوْلَٰٓئِكَ كَانَ عَنۡهُ مَسۡـُٔولٗا
Má ṣe tẹ̀lé ohun tí ìwọ kò nímọ̀ nípa rẹ̀. Dájúdájú ìgbọ́rọ̀, ìríran àti ọkàn; ìkọ̀ọ̀kan ìwọ̀nyẹn ni A óò bèèrè nípa rẹ̀.
التفاسير العربية:
وَلَا تَمۡشِ فِي ٱلۡأَرۡضِ مَرَحًاۖ إِنَّكَ لَن تَخۡرِقَ ٱلۡأَرۡضَ وَلَن تَبۡلُغَ ٱلۡجِبَالَ طُولٗا
Má ṣe rìn lórí ilẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga; dájúdájú ìwọ kò lè dá ilẹ̀ lu, ìwọ kò sì lè ga tó àpáta.
التفاسير العربية:
كُلُّ ذَٰلِكَ كَانَ سَيِّئُهُۥ عِندَ رَبِّكَ مَكۡرُوهٗا
Gbogbo ìyẹn, aburú rẹ̀ jẹ́ ohun ìkórira lọ́dọ̀ Olúwa rẹ.
التفاسير العربية:
 
ترجمة معاني سورة: الإسراء
فهرس السور رقم الصفحة
 
ترجمة معاني القرآن الكريم - الترجمة اليورباوية - أبو رحيمة ميكائيل - فهرس التراجم

ترجمها الشيخ أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني.

إغلاق