Check out the new design

Përkthimi i kuptimeve të Kuranit Fisnik - Përkthimi në gjuhën joruba - Ebu Rahime Majkëll * - Përmbajtja e përkthimeve

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Përkthimi i kuptimeve Surja: El Isra   Ajeti:
وَإِمَّا تُعۡرِضَنَّ عَنۡهُمُ ٱبۡتِغَآءَ رَحۡمَةٖ مِّن رَّبِّكَ تَرۡجُوهَا فَقُل لَّهُمۡ قَوۡلٗا مَّيۡسُورٗا
Tí o bá ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ wọn (ìyẹn àwọn aláìní) láti wá ìkẹ́ kan tí ò ń retí láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ, bá wọn sọ ọ̀rọ̀ ẹ̀lẹ̀.
Tefsiret në gjuhën arabe:
وَلَا تَجۡعَلۡ يَدَكَ مَغۡلُولَةً إِلَىٰ عُنُقِكَ وَلَا تَبۡسُطۡهَا كُلَّ ٱلۡبَسۡطِ فَتَقۡعُدَ مَلُومٗا مَّحۡسُورًا
Má di ọwọ́ rẹ mọ́ ọrùn rẹ (má ya ahun), má sì tẹ́ ẹ sílẹ̀ tán pátápátá (má ya àpà), kí o má baà jókòó kalẹ̀ ní ẹni èébú (tí o bá jẹ́ ahun), ẹni tí kò níí sí lọ́wọ́ rẹ̀ mọ́ (tí o bá jẹ́ àpà).
Tefsiret në gjuhën arabe:
إِنَّ رَبَّكَ يَبۡسُطُ ٱلرِّزۡقَ لِمَن يَشَآءُ وَيَقۡدِرُۚ إِنَّهُۥ كَانَ بِعِبَادِهِۦ خَبِيرَۢا بَصِيرٗا
Dájúdájú Olúwa rẹ l’Ó ń tẹ́ arísìkí sílẹ̀ fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Ó sì ń díwọ̀n rẹ̀ (fún ẹlòmíìràn). Dájúdájú Ó ń jẹ́ Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀, Olùríran nípa àwọn ẹrúsìn Rẹ̀.
Tefsiret në gjuhën arabe:
وَلَا تَقۡتُلُوٓاْ أَوۡلَٰدَكُمۡ خَشۡيَةَ إِمۡلَٰقٖۖ نَّحۡنُ نَرۡزُقُهُمۡ وَإِيَّاكُمۡۚ إِنَّ قَتۡلَهُمۡ كَانَ خِطۡـٔٗا كَبِيرٗا
Ẹ má pa àwọn ọmọ yín nítorí ìpáyà òṣì. Àwa l’À ń pèsè fún àwọn àti ẹ̀yin. Dájúdájú pípa wọ́n jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tó tóbi.
Tefsiret në gjuhën arabe:
وَلَا تَقۡرَبُواْ ٱلزِّنَىٰٓۖ إِنَّهُۥ كَانَ فَٰحِشَةٗ وَسَآءَ سَبِيلٗا
Ẹ má ṣe súnmọ́ àgbèrè. Dájúdájú ó jẹ́ ìwà burúkú. Ó sì burú ní ojú ọ̀nà.
Tefsiret në gjuhën arabe:
وَلَا تَقۡتُلُواْ ٱلنَّفۡسَ ٱلَّتِي حَرَّمَ ٱللَّهُ إِلَّا بِٱلۡحَقِّۗ وَمَن قُتِلَ مَظۡلُومٗا فَقَدۡ جَعَلۡنَا لِوَلِيِّهِۦ سُلۡطَٰنٗا فَلَا يُسۡرِف فِّي ٱلۡقَتۡلِۖ إِنَّهُۥ كَانَ مَنصُورٗا
Ẹ má pa ẹ̀mí tí Allāhu ṣe (pípa rẹ̀) ní èèwọ̀ àyàfi ní ọ̀nà ẹ̀tọ́.[1] Ẹni tí wọ́n bá pa ní ìpa àbòsí, dájúdájú A ti fún alámòjúútó rẹ̀ ní agbára (láti gbẹ̀san). Nítorí náà, kí ẹnikẹ́ni má ṣe tayọ ẹnu-ààlà níbi ìpànìyàn (nítorí pé) dájúdájú A máa ran (ẹbí òkú) lọ́wọ́ (láti gbẹ̀san).²
1. Àwọn ọ̀nà ẹ̀tọ́ tí ó lè mú kí ìjọba ’Islām pa ènìyàn ni kí ènìyàn jẹ̀bi ẹ̀sùn àgbèrè lẹ́yìn tí onítọ̀ún ti ní ọkọ tàbí aya, ìpànìyàn lọ́nà àìtọ́ àti fífi ẹ̀sìn ’Islām sílẹ̀. 2. Ọ̀nà ìgbẹ̀san fún ẹ̀sùn ìpànìyàn wà nínú sūrah an-Nisā’; 4: 92-93 àti sūrah al-Mọ̄’idah; 5:45.
Tefsiret në gjuhën arabe:
وَلَا تَقۡرَبُواْ مَالَ ٱلۡيَتِيمِ إِلَّا بِٱلَّتِي هِيَ أَحۡسَنُ حَتَّىٰ يَبۡلُغَ أَشُدَّهُۥۚ وَأَوۡفُواْ بِٱلۡعَهۡدِۖ إِنَّ ٱلۡعَهۡدَ كَانَ مَسۡـُٔولٗا
Ẹ má ṣe súnmọ́ dúkìá ọmọ òrukàn, àyàfi ní ọ̀nà tó dára jùlọ, títí ó fi máa dàgbà dáadáa. Kí ẹ sì mú àdéhùn ṣẹ. Dájúdájú àdéhùn jẹ́ ohun tí A ó bèèrè nípa rẹ̀.
Tefsiret në gjuhën arabe:
وَأَوۡفُواْ ٱلۡكَيۡلَ إِذَا كِلۡتُمۡ وَزِنُواْ بِٱلۡقِسۡطَاسِ ٱلۡمُسۡتَقِيمِۚ ذَٰلِكَ خَيۡرٞ وَأَحۡسَنُ تَأۡوِيلٗا
Ẹ wọn òṣùwọ̀n kún nígbà tí ẹ bá wọ̀n ọ́n. Ẹ fi ìwọ̀n tó tọ́[1] wọ̀n ọ́n. Ìyẹn lóore jùlọ, ó sì dára jùlọ ní ìkángun.
1. Ìyẹn òṣùwọ̀n tí kò tẹ̀ tí kò wọ́.
Tefsiret në gjuhën arabe:
وَلَا تَقۡفُ مَا لَيۡسَ لَكَ بِهِۦ عِلۡمٌۚ إِنَّ ٱلسَّمۡعَ وَٱلۡبَصَرَ وَٱلۡفُؤَادَ كُلُّ أُوْلَٰٓئِكَ كَانَ عَنۡهُ مَسۡـُٔولٗا
Má ṣe tẹ̀lé ohun tí ìwọ kò nímọ̀ nípa rẹ̀. Dájúdájú ìgbọ́rọ̀, ìríran àti ọkàn; ìkọ̀ọ̀kan ìwọ̀nyẹn ni A óò bèèrè nípa rẹ̀.
Tefsiret në gjuhën arabe:
وَلَا تَمۡشِ فِي ٱلۡأَرۡضِ مَرَحًاۖ إِنَّكَ لَن تَخۡرِقَ ٱلۡأَرۡضَ وَلَن تَبۡلُغَ ٱلۡجِبَالَ طُولٗا
Má ṣe rìn lórí ilẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga; dájúdájú ìwọ kò lè dá ilẹ̀ lu, ìwọ kò sì lè ga tó àpáta.
Tefsiret në gjuhën arabe:
كُلُّ ذَٰلِكَ كَانَ سَيِّئُهُۥ عِندَ رَبِّكَ مَكۡرُوهٗا
Gbogbo ìyẹn, aburú rẹ̀ jẹ́ ohun ìkórira lọ́dọ̀ Olúwa rẹ.
Tefsiret në gjuhën arabe:
 
Përkthimi i kuptimeve Surja: El Isra
Përmbajtja e sureve Numri i faqes
 
Përkthimi i kuptimeve të Kuranit Fisnik - Përkthimi në gjuhën joruba - Ebu Rahime Majkëll - Përmbajtja e përkthimeve

Përkthyer nga Shejh Ebu Rahime Majkëll Ejkojini.

Mbyll