ترجمة معاني القرآن الكريم - الترجمة اليورباوية * - فهرس التراجم

PDF XML CSV Excel API
تنزيل الملفات يتضمن الموافقة على هذه الشروط والسياسات

ترجمة معاني آية: (173) سورة: البقرة
إِنَّمَا حَرَّمَ عَلَيۡكُمُ ٱلۡمَيۡتَةَ وَٱلدَّمَ وَلَحۡمَ ٱلۡخِنزِيرِ وَمَآ أُهِلَّ بِهِۦ لِغَيۡرِ ٱللَّهِۖ فَمَنِ ٱضۡطُرَّ غَيۡرَ بَاغٖ وَلَا عَادٖ فَلَآ إِثۡمَ عَلَيۡهِۚ إِنَّ ٱللَّهَ غَفُورٞ رَّحِيمٌ
Ohun tí (Allāhu) ṣe ní èèwọ̀ fún yín ni òkúǹbete¹, ẹ̀jẹ̀², ẹran ẹlẹ́dẹ̀ àti ohun tí wọ́n pe orúkọ mìíràn lé lórí yàtọ̀ sí (orúkọ) Allāhu. Ṣùgbọ́n ẹni tí ìnira (ebi) bá mú (jẹ ẹran èèwọ̀), tí kì í ṣe ẹni tó ń wá èèwọ̀ kiri àti olùtayọ-ẹnu-ààlà, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún un. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.³
1. Òkúǹbete ni ẹran tí ó kú fúnra rẹ̀. Kíyè sí i, ẹ̀tọ́ ni òkúǹbete ẹran odò ní tirẹ̀ ní ìbámu sí sūrah al-Mā’idah; 5:96.
2. Ìyẹn ẹ̀jẹ̀ tí ó tú jáde lára ẹran yálà nípasẹ̀ dídúńbú, gígún tàbí títalọ́fà ní ìbámu sí sūrah al-’Ani‘ām; 6:145. Kì í ṣe ẹ̀jẹ̀ tí ó ṣẹ́kù sára ẹran tí wọ́n ti kun tàbí ẹ̀jẹ̀ tí ó wà nínú ẹ̀dọ̀ àti àmọ́.
3. Ìnira ebi ni pé, kí ènìyàn bọ́há sí àyè kan, tí kò ti lè rí òdíwọ̀n ohun jíjẹ tàbí ohun mímu halāl tí ó kéré jùlọ láti fi gbé ẹ̀mí ara rẹ̀ ró. Àmọ́ ní ti ìnira àìsàn, mùsùlùmí kò gbọdọ̀ lo n̄ǹkan harām láti fi tọ́jú ara rẹ̀, bí ó tilẹ̀ wù kí ó rí, kódà kó fẹ́ já sí ikú. Harām kì í ṣe sábàbí ìlera. Nítorí náà, ìnira ebi ni làlúrí. Ìnira àìsàn kì í ṣe làlúrí.
التفاسير العربية:
 
ترجمة معاني آية: (173) سورة: البقرة
فهرس السور رقم الصفحة
 
ترجمة معاني القرآن الكريم - الترجمة اليورباوية - فهرس التراجم

ترجمة معاني القرآن الكريم إلى اللغة اليوربا، ترجمها الشيخ أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني. طبعة عام 1432هـ .

إغلاق