ترجمة معاني القرآن الكريم - الترجمة اليورباوية * - فهرس التراجم

PDF XML CSV Excel API
تنزيل الملفات يتضمن الموافقة على هذه الشروط والسياسات

ترجمة معاني آية: (66) سورة: آل عمران
هَٰٓأَنتُمۡ هَٰٓؤُلَآءِ حَٰجَجۡتُمۡ فِيمَا لَكُم بِهِۦ عِلۡمٞ فَلِمَ تُحَآجُّونَ فِيمَا لَيۡسَ لَكُم بِهِۦ عِلۡمٞۚ وَٱللَّهُ يَعۡلَمُ وَأَنتُمۡ لَا تَعۡلَمُونَ
Ẹ̀yin ni ìwọ̀nyí tí ẹ̀ ń jiyàn nípa ohun tí ẹ nímọ̀ nípa rẹ̀! Kí ni ó tún ń mu yín jiyàn nípa ohun tí ẹ ò nímọ̀ nípa rẹ̀?¹ Allāhu nímọ̀. Ẹ̀yin kò sì nímọ̀.
1. Ìyẹn ni pé, ’Islām tí Ànábì Mūsā - kí ọlà Allāhu máa bá a - àti ’Islām tí Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - mú wá, ó ti dojúrú pátápátá mọ́ àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl lọ́wọ́, tòhun ti bí wọ́n ṣe bá àwọn Ànábì méjèèjì lògbà pọ̀. Nítorí náà, kí ni wọ́n fẹ́ wá rí sọ nípa ’Islām tí Ànábì ’Ibrọ̄hīm - kí ọlà Allāhu máa bá a - mú wá, ẹni tí wọn kò bá láyé, bí kò ṣe ìsọkúsọ irú èyí tí wọ́n ń sọ nípa àwọn Ànábì tiwọn, Ànábì Mūsā àti Ànábì ‘Īsā - kí ọlà Allāhu máa bá àwọn méjèèjì -.
التفاسير العربية:
 
ترجمة معاني آية: (66) سورة: آل عمران
فهرس السور رقم الصفحة
 
ترجمة معاني القرآن الكريم - الترجمة اليورباوية - فهرس التراجم

ترجمة معاني القرآن الكريم إلى اللغة اليوربا، ترجمها الشيخ أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني. طبعة عام 1432هـ .

إغلاق