ترجمة معاني القرآن الكريم - الترجمة اليورباوية * - فهرس التراجم

PDF XML CSV Excel API
تنزيل الملفات يتضمن الموافقة على هذه الشروط والسياسات

ترجمة معاني آية: (25) سورة: فصلت
۞ وَقَيَّضۡنَا لَهُمۡ قُرَنَآءَ فَزَيَّنُواْ لَهُم مَّا بَيۡنَ أَيۡدِيهِمۡ وَمَا خَلۡفَهُمۡ وَحَقَّ عَلَيۡهِمُ ٱلۡقَوۡلُ فِيٓ أُمَمٖ قَدۡ خَلَتۡ مِن قَبۡلِهِم مِّنَ ٱلۡجِنِّ وَٱلۡإِنسِۖ إِنَّهُمۡ كَانُواْ خَٰسِرِينَ
Àwa ti yan àwọn alábàárìn kan fún wọn,¹ tí wọ́n ṣe ohun tí ń bẹ níwájú wọn² àti ohun tí ń bẹ ní ẹ̀yìn wọn³ ní ọ̀ṣọ́ fún wọn. Ọ̀rọ̀ náà sì kò lé wọn lórí (gẹ́gẹ́ bí ó ṣe ṣẹlẹ̀) sí àwọn ìjọ tó ṣíwájú wọn nínú àwọn àlùjànǹú àti ènìyàn pé dájúdájú àwọn ni wọ́n jẹ́ ẹni òfò.
1. Ìyẹn ni pé, A ti yan àwọn èṣù ẹlẹ́tàn kan fún wọn tí ó tàn wọ́n jẹ títí di ọjọ́ ikú wọn.
2. “ohun tí ń bẹ níwájú wọn” tí àwọn èṣù wọn ṣe ní ọ̀ṣọ́ fún wọn ni yòdòyìndìn, adùn àti ọ̀ṣọ́ ilé ayé tí ó mú wọn gbàgbé Allāhu.
3. “ohun tí ń bẹ ní ẹ̀yìn wọn” tí àwọn èṣù wọn ṣe ní ọ̀ṣọ́ fún wọn ni pé, kò níí sí àjíǹde, ìṣírò-iṣẹ́ àti ẹ̀san ní Ọjọ́ Àjíǹde. Wọ́n sì ń wí pé, “Lẹ́yìn ikú, sàréè ni!” Wọn kò sì mọ̀ pé, àjíǹde, ìṣírò-iṣẹ́ àti ẹ̀san ń bẹ lẹ́yìn sàréè. Ìdí nìyí tí wọn fi gbàgbé Allāhu pátápátá.
التفاسير العربية:
 
ترجمة معاني آية: (25) سورة: فصلت
فهرس السور رقم الصفحة
 
ترجمة معاني القرآن الكريم - الترجمة اليورباوية - فهرس التراجم

ترجمة معاني القرآن الكريم إلى اللغة اليوربا، ترجمها الشيخ أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني. طبعة عام 1432هـ .

إغلاق