কুরআনুল কারীমের অর্থসমূহের অনুবাদ - ইয়োরুবা ভাষায় অনুবাদ * - অনুবাদসমূহের সূচী

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

অর্থসমূহের অনুবাদ আয়াত: (150) সূরা: সূরা আল-বাকারা
وَمِنۡ حَيۡثُ خَرَجۡتَ فَوَلِّ وَجۡهَكَ شَطۡرَ ٱلۡمَسۡجِدِ ٱلۡحَرَامِۚ وَحَيۡثُ مَا كُنتُمۡ فَوَلُّواْ وُجُوهَكُمۡ شَطۡرَهُۥ لِئَلَّا يَكُونَ لِلنَّاسِ عَلَيۡكُمۡ حُجَّةٌ إِلَّا ٱلَّذِينَ ظَلَمُواْ مِنۡهُمۡ فَلَا تَخۡشَوۡهُمۡ وَٱخۡشَوۡنِي وَلِأُتِمَّ نِعۡمَتِي عَلَيۡكُمۡ وَلَعَلَّكُمۡ تَهۡتَدُونَ
Ibikíbi tí o bá jáde lọ, kọjú rẹ sí agbègbè Mọ́sálásí Haram. Àti pé ibikíbi tí ẹ bá wà, ẹ kọjú yín sí agbègbè rẹ̀,¹ nítorí kí àwọn ènìyàn má baà ní àwíjàre lórí yín, àyàfi àwọn tí wọ́n ṣàbòsí nínú wọn (tí wọn kò yé jà yín níyàn). Nítorí náà, ẹ má ṣe páyà wọn. Ẹ páyà Mi, nítorí kí N̄g lè pé ìdẹ̀ra Mi fún yín àti nítorí kí ẹ lè mọ̀nà.
1. Àwọn āyah wọ̀nyí 144, 149 àti 150 ń pa wá láṣẹ láti dojúkọ agbègbè Kaabah lórí ìrun, ìyẹn sì ni agbègbè tí Kaabah wà sí ìlú ẹnì kọ̀ọ̀kan tàbí mọ́sálásí ẹnì kọ̀ọ̀kan. Ohun tó bí “agbègbè” dípò “ọ̀gangan” Kaabah ni pé, kò lè rọrùn rárá fún àwọn tí kò sí nínú mọ́sálásí Haram Mọkkah láti dojúkọ ọ̀gangan Kaabah láti àyè mìíràn lórí ìrun wọn. Èyí sì yọrí sí àtòyípo Kaabah fún ọ̀wọ́ àwọn tó wà nínú mọ́sálásí Kaabah nítorí kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn lè kọjú sí ọ̀gangan Kaabah. Ní ìdà kejì ẹwẹ̀, gbogbo àwọn olùkírun yòókù ní àyè mìíràn máa tò ní àtògbọọrọ. Wàyí, nípasẹ̀ títò ní àtògbọọrọ yìí, (1) ó ṣeé ṣe kí wọ́n dojúkọ orígun kan nínú àwọn orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé nínú ìlú wọn tàbí (2) ó ṣeé ṣe kí wọ́n dojúkọ ààrin orígun méjì nínú orígun méjì ìpìlẹ̀ nínú àwọn orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé nínú ìlú wọn tàbí (3) ó ṣeé ṣe kí wọ́n dojúkọ ààrin orígun méjì tí orígun kan máa jẹ́ orígun ìpìlẹ̀, tí orígun kejì sì máà jẹ́ orígun-ààlà láààrin orígun ìpìlẹ̀ méjì. Àpẹ̀ẹrẹ fún (2) ni ƙiblah fún ìlú Mọdinah onímọ̀ọ́lẹ̀ nítorí pé, ní ti ìlú Mọdinah onímọ̀ọ́lẹ̀, láààrin agbègbè ìlà òòrùn (mọṣriƙ) àti ìwọ̀ òòrùn (mọgrib) ìlú Mọdinah ni agbègbè tí Kaabah wà sí wọn. Àpẹ̀ẹrẹ fún (3) ni ilẹ̀ Yorùbá ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà nítorí pé, láààrin ìlà òòrùn (east) àti àríwá-ìlà òòrùn (north-east) ni agbègbè tí Kaabah wà sí wa. Èyí ni àwọn onímọ̀-ìjìnlẹ̀ nípa orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé fi rinlẹ̀.
আরবি তাফসীরসমূহ:
 
অর্থসমূহের অনুবাদ আয়াত: (150) সূরা: সূরা আল-বাকারা
সূরাসমূহের সূচী পৃষ্ঠার নাম্বার
 
কুরআনুল কারীমের অর্থসমূহের অনুবাদ - ইয়োরুবা ভাষায় অনুবাদ - অনুবাদসমূহের সূচী

ইয়োরুবা ভাষায় কুরআনুল কারীমের অর্থসমূহের অনুবাদ। অনুবাদ করেছেন শায়খ আবূ রাহীমাহ মিকাঈল আইকুয়েনী। প্রকাশকাল ১৪৩২হি.।

বন্ধ