কুরআনুল কারীমের অর্থসমূহের অনুবাদ - ইয়োরুবা ভাষায় অনুবাদ * - অনুবাদসমূহের সূচী

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

অর্থসমূহের অনুবাদ আয়াত: (47) সূরা: সূরা আল-মায়েদা
وَلۡيَحۡكُمۡ أَهۡلُ ٱلۡإِنجِيلِ بِمَآ أَنزَلَ ٱللَّهُ فِيهِۚ وَمَن لَّمۡ يَحۡكُم بِمَآ أَنزَلَ ٱللَّهُ فَأُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡفَٰسِقُونَ
Kí àwọn tí A fún ní al-’Injīl ṣèdájọ́ pẹ̀lú ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀ nínú rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí kò bá ṣèdájọ́ pẹ̀lú ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn ni òbìlẹ̀jẹ́.¹
1. Kíyè sí i, tí àwọn onítírà ’Injīl bá lò ó gẹ́gẹ́ bí Allāhu - subhānahu wa ta'ālā - ṣe sọ̀ ọ́ kalẹ̀, dandan ni fún wọn láti tẹ̀lé Ànábì àsìkò yìí, Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -. Nítorí pé, àsọtẹ́lẹ̀ nípa Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - kúkú wà nínú rẹ̀. Bí àpẹ̀ẹrẹ, nínú ìwé Johannu 1:19-21, bíbélì sọ pé: (19) Eyi si ni ẹri Johannu, nigba ti awọn Ju ran awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi lati Jerusalẹmu wa lati bi i leere pe. Tani iwọ ṣe? (20) O si jẹwọ, ko si sẹ; o si jẹwọ pe. Emi ki i ṣe Kristi naa. (21) Wọn si bi i pe, Tani iwọ ha ṣe? Elijah ni ọ bi? O si wipe Bẹẹkọ, Iwọ ni woli naa bi “ẹni tí à ń retí”? O si dahun wipe, Bẹẹkọ. [Complete Jewish Bible àti New Living Translation Bible. Kíyè sí i, àwọn bíbélì yòókú ti yọ “ẹni tí à ń retí” kúrò gẹ́gẹ́ bí ìṣe wọn.] Nítorí irú àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí ló mú kí Waraƙọh ọmọ Naofal, ẹbí ìyáwó àkọ́fẹ́ Ànábì wa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - Kọdījah ọmọ Kuwaelid - kí Allāhu yọ́nú sí i -, ṣe gbà pé òun máa tẹ̀lé Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - nígbàkígbà tí Allāhu bá rán an níṣẹ́ sí àwọn ènìyàn. Àmọ́ ó kú ṣíwájú àsìkò náà.
Síwájú sí i, kàyéfì tí ń bẹ lára àwọn yẹ̀húdí àti nasọ̄rọ̄ ni pé, wọ́n kò yé retí ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ náà. Kódà wọ́n máa ń fi bá àwọn ọ̀ṣẹbọ sọ̀rọ̀ nínú ìwàásù wọn fún wọn. Àmọ́ nígbà tí àsọtẹ́lẹ̀ náà wá sí ìmúṣẹ, ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn l’ó gbúnrí. Wọ́n sì ṣàì gbàgbọ́ nínú Ànábì náà - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -. Èyí ni Allāhu - subhānahu wa ta'ālā - sọ nípa rẹ̀ nínú sūrah al-Baƙọrah; 2:89. Ẹ tún wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah Yūnus; 10:94.
আরবি তাফসীরসমূহ:
 
অর্থসমূহের অনুবাদ আয়াত: (47) সূরা: সূরা আল-মায়েদা
সূরাসমূহের সূচী পৃষ্ঠার নাম্বার
 
কুরআনুল কারীমের অর্থসমূহের অনুবাদ - ইয়োরুবা ভাষায় অনুবাদ - অনুবাদসমূহের সূচী

ইয়োরুবা ভাষায় কুরআনুল কারীমের অর্থসমূহের অনুবাদ। অনুবাদ করেছেন শায়খ আবূ রাহীমাহ মিকাঈল আইকুয়েনী। প্রকাশকাল ১৪৩২হি.।

বন্ধ