Wọ́n ń bi ọ́ léèrè nípa ọrọ̀ ogun. Sọ pé: “Ọrọ̀ ogun jẹ́ ti Allāhu àti ti Òjíṣẹ́. Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu. Kí ẹ sì ṣe àtúnṣe n̄ǹkan tí ń bẹ láààrin yín. Ẹ tẹ̀lé ti Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.
Àwọn onígbàgbọ́ òdodo ni àwọn tó jẹ́ pé nígbà tí wọ́n bá fi (ìyà) Allāhu ṣe ìrántí (fún wọn), ọkàn wọn yóò wárìrì, nígbà tí wọ́n bá sì ké àwọn āyah Rẹ̀ fún wọn, wọn yóò lékún ní ìgbàgbọ́ òdodo. Olúwa wọn sì ni wọ́n ń gbáralé.
Ẹ̀yin kọ́ lẹ pa wọ́n, ṣùgbọ́n Allāhu l’Ó pa wọ́n. Àti pé ìwọ kọ́ lo jùkò nígbà tí o jùkò, àmọ́ dájúdájú Allāhu l’Ó jùkò[1] nítorí kí (Allāhu) lè fi àmìwò dáadáa kan àwọn onígbàgbọ́ òdodo láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni. Dájúdájú Allāhu ni Olùgbọ́, Onímọ̀.
1. Ìyẹn ni pé, àṣẹ Allāhu - subhānahu wa ta'ālā - tó ń bẹ lára òkò tí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - jù lu àwọn kèfèrí l’ó gba ẹ̀mí wọn.
Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu mọ oore kan lára wọn ni, ìbá jẹ́ kí wọ́n gbọ́. Tí (Allāhu) bá sì fún wọn gbọ́ ni, dájúdájú wọn máa pẹ̀yìn dà, wọn yó sì máa gbúnrí.
Nígbà tí A bá ń ké àwọn āyah Wa fún wọn, wọ́n á wí pé: “A kúkú ti gbọ́. Tí ó bá jẹ́ pé a bá fẹ́ ni. àwa náà ìbá sọ irú èyí. Kí ni èyí bí kò ṣe àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́.”
Ẹ jà wọ́n lógun títí kò fi níí sí ìfòòró (ìbọ̀rìṣà) mọ́, gbogbo ẹ̀sìn yó sì lè jẹ́ ti Allāhu pátápátá. Nítorí náà, tí wọ́n bá jáwọ́ (nínú àìgbàgbọ́), dájúdájú Allāhu ni Olùríran nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Ìyẹn nítorí pé dájúdájú Allāhu kò níí ṣe ìyípadà ìdẹ̀ra tí Ó ṣe fún ìjọ kan títí wọn yóò fi ṣe ìyípadà n̄ǹkan tí ń bẹ lọ́dọ̀ ara wọn. Dájúdájú Allāhu sì ni Olùgbọ́, Onímọ̀.
(Ìṣesí àwọn aláìmoore) dà bí ìṣesí àwọn ènìyàn Fir‘aon àti àwọn tó ṣíwájú wọn, tí wọ́n pe àwọn āyah Olúwa wọn nírọ́. Nítorí náà, A pa wọ́n run nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn; A sì tẹ àwọn ènìyàn Fir‘aon rì sínú agbami. Gbogbo wọn sì jẹ́ alábòsí.
yálà tí ọwọ́ yín bá bà wọ́n lójú ogun, (ẹ fi ìyà tó le koko jẹ wọ́n,) kí ẹ lè (fi ìbẹ̀rù ìyà naa) tú àwọn ọmọlẹ́yìn wọn ká nítorí kí wọ́n lè lo ìrántí;
Allāhu pa ọkàn wọn pọ̀ mọ́ra wọn. Tí ó bá jẹ́ pé o ná gbogbo n̄ǹkan tí ń bẹ lórí ilẹ̀ pátápátá, ìwọ kò lè pa ọkàn wọn pọ̀ mọ́ra wọn. Ṣùgbọ́n Allāhu pa ọkàn wọn pọ̀ mọ́ra wọn, dájúdájú Òun ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
Kò yẹ fún Ànábì kan láti ní ẹrú ogun títí ọwọ́ rẹ̀ máa fi ba àwọn ọ̀tá rẹ̀ lórí ilẹ̀ dáadáa ní ti pípa.[1] Ẹ̀yin ń fẹ́ ìgbádùn ayé, Allāhu sì ń fẹ́ ọ̀run. Allāhu sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
Dájúdájú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n gbé ìlú wọn jù sílẹ̀, tí wọ́n sì fi dúkìá wọn àti ẹ̀mí wọn jagun lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, àti àwọn tó gbà wọ́n sọ́dọ̀ (nínú ìlú), tí wọ́n sì ràn wọ́n lọ́wọ́; àwọn wọ̀nyẹn, apá kan wọn l’ọ̀rẹ́ apá kan (tó lè jogún ara wọn). Àwọn tó gbàgbọ́, tí wọn kò sì gbé ìlú wọn jù sílẹ̀, kò lẹ́tọ̀ọ́ fún yín láti mú wọn lọ́rẹ̀ẹ́ níbì kan kan (tó lè mu yín jogún ara yín), títí wọn yóò fi gbé ìlú wọn jù sílẹ̀.[1] Tí wọ́n bá sì wá ìrànlọ́wọ́ yín (lórí ọ̀tá) nípa ẹ̀sìn, ìrànlọ́wọ́ náà di dandan fún yín àyàfi lórí ìjọ kan tí àdéhùn ń bẹ láààrin ẹ̀yin àti àwọn. Allāhu sì ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
1. Ní ìbẹ̀rẹ̀ hijrah ṣíṣe sọ ogún jíjẹ di ẹ̀tọ́ láti inú ẹbí kan fún ẹni tó ṣe hijrah. Àìṣe hijrah sì sọ ogún jíjẹ di èèwọ̀ láti inú ẹbí kan náà fún ẹni tí kò ṣe hijrah, wọn ìbáà dìjọ jẹ́ mùsùlùmí. Fífi hijrah sọ ogún jíjẹ di ẹ̀tọ́ sì wà bẹ́ẹ̀ títí wọ́n fi ṣí ìlú Mọkkah. Wọn kò si fi hijrah ṣíṣe pín ogún fún ẹnikẹ́ni mọ́ ní ìbámu sí āyah 75 nínú sūrah yìí. Lẹ́yìn náà, àwọn āyah ogún pípín fún àwọn ẹbí sọ̀kalẹ̀ nínú sūrah an-Nisā’.
Àwọn aláìgbàgbọ́; apá kan wọn ni alátìlẹ́yìn apá kan. Àfi kí ẹ̀yin náà ṣe bẹ́ẹ̀ ni ìfòòró àti ìbàjẹ́ tó tóbi kò fi níí wà lórí ilẹ̀.
Contents of the translations can be downloaded and re-published, with the following terms and conditions:
1. No modification, addition, or deletion of the content.
2. Clearly referring to the publisher and the source (QuranEnc.com).
3. Mentioning the version number when re-publishing the translation.
4. Keeping the transcript information inside the document.
5. Notifying the source (QuranEnc.com) of any note on the translation.
6. Updating the translation according to the latest version issued from the source (QuranEnc.com).
7. Inappropriate advertisements must not be included when displaying translations of the meanings of the Noble Quran.
অনুসন্ধানের ফলসমূহ:
API specs
Endpoints:
Sura translation
GET / https://quranenc.com/api/v1/translation/sura/{translation_key}/{sura_number} description: get the specified translation (by its translation_key) for the speicified sura (by its number)
Parameters: translation_key: (the key of the currently selected translation) sura_number: [1-114] (Sura number in the mosshaf which should be between 1 and 114)
Returns:
json object containing array of objects, each object contains the "sura", "aya", "translation" and "footnotes".
GET / https://quranenc.com/api/v1/translation/aya/{translation_key}/{sura_number}/{aya_number} description: get the specified translation (by its translation_key) for the speicified aya (by its number sura_number and aya_number)
Parameters: translation_key: (the key of the currently selected translation) sura_number: [1-114] (Sura number in the mosshaf which should be between 1 and 114) aya_number: [1-...] (Aya number in the sura)
Returns:
json object containing the "sura", "aya", "translation" and "footnotes".