Prijevod značenja časnog Kur'ana - Prijevod na joruba jezik * - Sadržaj prijevodā

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Prijevod značenja Ajet: (104) Sura: Sura el-Bekara
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَا تَقُولُواْ رَٰعِنَا وَقُولُواْ ٱنظُرۡنَا وَٱسۡمَعُواْۗ وَلِلۡكَٰفِرِينَ عَذَابٌ أَلِيمٞ
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má sọ pé “rọ̄‘inā”. (Àmọ́) ẹ sọ pé “unṭḥurnā”¹, kí ẹ sì máa tẹ́tí gbọ́ (ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn). Ìyà ẹlẹ́ta-eléro sì wà fún àwọn aláìgbàgbọ́.
1. Rọ̄‘inā jẹ́ ọ̀rọ̀ méjì; “rọ̄‘i” àti “nā”. “Nā” jẹ́ ọ̀rọ̀ arọ́pò-orúkọ ẹnì kíní ọ̀pọ̀ “wa”. “Rọ̄‘i” ní ìtúmọ̀ méjì nínú èdè Lárúbáwá àti èdè Isrā’īl. Bákan náà, “rọ̄‘i” lè jẹ́ ọ̀rọ̀-orúkọ tàbí ọ̀rọ̀-ìṣe àṣẹ nínú èdè méjèèjì. Nígbà tí wọ́n bá lo “rọ̄‘i” ní ìlò ọ̀rọ̀-orúkọ, ìtúmọ̀ rẹ̀ ni “òmùgọ̀” nítorí pé ó jẹ́ ọ̀rọ̀ ìṣẹ̀dá láti ara “ru‘ūnah” agọ̀. Àmọ́ nígbà tí wọ́n bá lo “rọ̄‘i” ní ìlò ọ̀rọ̀-ìṣe àṣẹ, ìtúmọ̀ rẹ̀ ni “kíyè sí (i), wò (ó),” nítorí pé ó jẹ́ ọ̀rọ̀ ìṣẹ̀dá láti ara “ri‘ānah” kíkíyèsí tàbí mímójútó kiní kan / ẹnì kan. Ìgbàkígbà tí àwọn yẹhudi bá lo “rọ̄‘i” fún àwọn Ànábì wọn, ìlò ọ̀rọ̀-orúkọ ni wọ́n ń gbàlérò.
Ìyẹn túmọ̀ sí pé, tí wọ́n bá sọ fún àwọn Ànábì wọn pé “rọ̄‘inā”, ohun tí wọ́n ń gbà lérò ni pé “òmùgọ̀ wa!”. Àmọ́ nígbà tí àwọn Sọhābah - kí Allāhu yọ́nú sí wọn - bá lò “rọ̄‘inā” fún Ànábì - kí ọlà Allāhu máa bá a -, ìlò ọ̀rọ̀-ìṣe àṣẹ ni wọ́n ń gbàlérò. Ìyẹn túmọ̀ sí pé àwọn Sọhābah ń sọ pé “kí Ànábì kíyè sí wa”. Nítorí kí àwọn yẹhudi má baà ṣe lérò pé irú wọn ni àwọn Sọhābah ni Allāhu fi kọ lílo ọ̀rọ̀ yẹn fún àwọn Sọhābah - kí Allāhu yọ́nú sí wọn -, Ó sì fún wọn ní ọ̀rọ̀ mìíràn tí ó gbé ìtúmọ̀ àti èròǹgbà rere wọn jáde, tí kò sì jẹmọ́ èdè abunikù. Èyí sì ni “unṭḥurnā”. Èyí rí bẹ́ẹ̀ kí àwa mùsùlùmí lè mọ̀ pé ìlò èdè wa àti ìṣe wa kò gbọdọ̀ jọ tàwọn aláìgbàgbọ́.
Tefsiri na arapskom jeziku:
 
Prijevod značenja Ajet: (104) Sura: Sura el-Bekara
Indeks sura Broj stranice
 
Prijevod značenja časnog Kur'ana - Prijevod na joruba jezik - Sadržaj prijevodā

Prijevod značenja Plemenitog Kur'ana na joruba jezik - Šejh Ebu Rahima MIhail Akvinski, 1432. godine po Hidžri.

Zatvaranje