Prijevod značenja časnog Kur'ana - Prijevod na joruba jezik * - Sadržaj prijevodā

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Prijevod značenja Ajet: (255) Sura: Sura el-Bekara
ٱللَّهُ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ ٱلۡحَيُّ ٱلۡقَيُّومُۚ لَا تَأۡخُذُهُۥ سِنَةٞ وَلَا نَوۡمٞۚ لَّهُۥ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِۗ مَن ذَا ٱلَّذِي يَشۡفَعُ عِندَهُۥٓ إِلَّا بِإِذۡنِهِۦۚ يَعۡلَمُ مَا بَيۡنَ أَيۡدِيهِمۡ وَمَا خَلۡفَهُمۡۖ وَلَا يُحِيطُونَ بِشَيۡءٖ مِّنۡ عِلۡمِهِۦٓ إِلَّا بِمَا شَآءَۚ وَسِعَ كُرۡسِيُّهُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَۖ وَلَا يَـُٔودُهُۥ حِفۡظُهُمَاۚ وَهُوَ ٱلۡعَلِيُّ ٱلۡعَظِيمُ
Allāhu, kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun, Alààyè, Alámòjúútó-ẹ̀dá. Òògbé kì í ta Á. Àti pé oorun kì í kùn Ún. TiRẹ̀ ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀. Ta ni ẹni tí ó máa ṣìpẹ̀ lọ́dọ̀ Rẹ̀ àfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Rẹ̀?¹ Ó mọ ohun tí ń bẹ níwájú wọn àti ohun tí ń bẹ lẹ́yìn wọn. Wọn kò sì ní ìmọ̀ àmọ̀tán nípa kiní kan nínú ìmọ̀ Rẹ̀ àfi ohun tí Ó bá fẹ́ (fi mọ̀ wọ́n). Àga Rẹ̀ gbààyè ju àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀.² Ṣíṣọ́ sánmọ̀ àti ilẹ̀ kò sì dá A lágara. Allāhu ga, Ó tóbi.³
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Baƙọrah; 2:48.
2. Ọ̀nà méjì ni “kursiyy” tó jẹyọ nínú gbólóhùn yìí “Àga Rẹ̀ gbààyè ju àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀.” túmọ̀ sí. Ìtúmọ̀ kìíní ni pé, “kursiyy” túmọ̀ sí àga gẹ́gẹ́ bí mo ṣe túmọ̀ rẹ̀ sókè yẹn. Ìtúmọ̀ kejì ni pé, “kursiyy” túmọ̀ sí ibùgbẹ́sẹ̀lé Allāhu - tó ga jùlọ - ìyẹn ni pé, àyè tí Allāhu - tó ga jùlọ - gbé ẹsẹ̀ Rẹ̀ méjèèjì le. Àpapọ̀ ìtúmọ̀ kìíní kejì ni pé, Allāhu gúnwà sí orí “al-‘Arṣ” ìtẹ́ ọlá Rẹ̀. Ó sì gbé ẹsẹ̀ Rẹ̀ méjèèjì lé orí “al-kursiyy” àga Rẹ̀. Àgá náà sì fẹjú ju àpapọ̀ àwọn sánmọ̀ méjèèjè àti àwọn ilẹ̀ méjèèjè.
عن السدي:"وسع كرسيه السموات والأرض"، فإن السموات والأرض في جوف الكرسي، والكرسي بين يدي العرش، وهو موضع قدميه.
Láti ọ̀dọ̀ Suddiy, ó sọ pé, “Àga Rẹ̀ gbààyè ju àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀.” Nítorí pé dájúdájú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ wà láààrin gbùngbùn àga náà, àga náà sì wà ní iwájú Ìtẹ́ ọlá náà, òhun (ìyẹn àga náà) ni àyè tí Allāhu - tó ga jùlọ - gbé ẹsẹ̀ Rẹ̀ méjèèjì lé.” (Tọbariy àti Ibn Kathir)
3. Ọ̀kan pàtàkì nínú āyah ìṣọ́ tó nípọn ju ẹ̀wù irin ni āyah al-Kursiyy. Nítorí náà, ó tọ sunnah fún mùsùlùmí láti máa ké āyah náà lẹ́yìn ìparí ìrun ọ̀ran-anyàn kọ̀ọ̀kan, àárọ̀ àti ìrọ̀lẹ́, lásìkò tí ó bá fẹ́ sùn àti ní gbogbo àyè tí ó bá wà bí inú ilé àti inú ṣọ́ọ̀bù láti lé àwọn Èṣù àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ dànù tefétefé pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu Ọba Olùṣọ́ gbogbo ẹ̀dá.
Tefsiri na arapskom jeziku:
 
Prijevod značenja Ajet: (255) Sura: Sura el-Bekara
Indeks sura Broj stranice
 
Prijevod značenja časnog Kur'ana - Prijevod na joruba jezik - Sadržaj prijevodā

Prijevod značenja Plemenitog Kur'ana na joruba jezik - Šejh Ebu Rahima MIhail Akvinski, 1432. godine po Hidžri.

Zatvaranje