Prijevod značenja časnog Kur'ana - Prijevod na joruba jezik * - Sadržaj prijevodā

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Prijevod značenja Ajet: (62) Sura: Sura el-Bekara
إِنَّ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَٱلَّذِينَ هَادُواْ وَٱلنَّصَٰرَىٰ وَٱلصَّٰبِـِٔينَ مَنۡ ءَامَنَ بِٱللَّهِ وَٱلۡيَوۡمِ ٱلۡأٓخِرِ وَعَمِلَ صَٰلِحٗا فَلَهُمۡ أَجۡرُهُمۡ عِندَ رَبِّهِمۡ وَلَا خَوۡفٌ عَلَيۡهِمۡ وَلَا هُمۡ يَحۡزَنُونَ
Dájúdájú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo àti àwọn yẹhudi àti àwọn nasọ̄rọ̄ àti àwọn sọ̄bi’u; ẹnikẹ́ni tí ó bá ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rere, ẹ̀san wọn ń bẹ fún wọn ní ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Kò sí ìbẹ̀rù fún wọn. Wọn kò sì níí banújẹ́.¹
1. Irú āyah yìí wà nínú sūrah al-Mọ̄’idah; 5:69 àti sūrah al-Hajj; 22:17.
Àgbọ́yé āyah yìí nìyí:
Ìkíní: Kò sí ẹ̀sìn kan lọ́dọ̀ Allāhu àfi ’Islām (Ẹ wo sūrah āli-’Imrọ̄n; 3:19 àti 85 àti sūrah al-Mọ̄’dah; 5:3.)
Ìkejì: Kò sí Ànábì tàbí Òjíṣẹ́ kan tí Allāhu rán níṣẹ́ rí pẹ̀lú ẹ̀sìn mìíràn àfi ’Islām. (Ẹ wo sūrah al-Baƙọrah; 2:130 -140, āl 'Imrọ̄n; 3:51-52 àti 84) Ẹ tún wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah Yūnus; 10:90.
Síwájú sí i, okùnfà ìsọ̀kalẹ̀ āyah yìí ni pé, nígbà tí Salmọ̄n Farisiy - kí Allāhu yọ́nú sí i - gba ’Islām, ó sọ̀rọ̀ nípa ìrun kíkí, ààwẹ̀ gbígbà àti ìjọ́sìn àwọn ènìyàn rẹ̀ kan tí wọ́n jẹ́ yẹ̀húdí àti nasọ̄rọ̄, àti ìrètí wọn nínú Ànábì ìkẹ́yìn tí wọ́n ń retí nígbà yẹn. Ó sọ̀rọ̀ wọn fún Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - dáadáa. Kò fi ẹbọ ṣíṣe kún un. Kò fi mẹ́ta lọ́kan kún un. Kò sì fi pípe ẹnì kan ní ọmọ Ọlọ́hun kún un. Ànábí - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - kọ́kọ́ sọ pé, wọ́n máa wọ inú Iná. Inú Salmọ̄n bàjẹ́ gan-an. Lẹ́yìn náà, āyah yìí sọ̀kalẹ̀, ìyẹn āyah tí à ń tọsẹ rẹ̀ lọ́wọ́.
Àlàyé lórí ìsọ̀kalẹ̀ āyah náà nìyí, ní ti èsì àkọ́kọ́ tí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - fún Salmọ̄n, ìyẹn dúró lé àwọn āyah kan nínú al-Ƙur’ān tí ó ń fi rinlẹ̀ pé, ẹnikẹ́ni kò gbọ́dọ̀ tẹ̀lé ànábì kan kan mọ́ nínú àwọn Ànábì tó ṣíwájú Ànábì wa Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - níkété tí Allāhu ti gbé Ànábì wa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - dìde ní Òjíṣẹ́ sí gbogbo ayé ní ìbámu sí sūrah āl ‘Imrọ̄n; 3:31-32 àti al-’A‘rọ̄f; 7:158. Nínú hadīth Muslim láti ọ̀dọ̀ bàbá Huraerah - kí Allāhu yọ́nú sí i -, láti ọ̀dọ̀ Òjíṣẹ́ Allāhu - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -, dájúdájú Òjíṣẹ́ Allāhu sọ pé: “Èmi fi Ẹni tí ẹ̀mí Muhammad wà ní ọwọ́ Rẹ̀ búra; ẹnì kan nínú ìjọ yìí, yẹhudi tàbí nasọ̄rọ̄, kò níí gbọ́ nípa mi, lẹ́yìn náà kí ó kú láì gbàgbọ́ nínú ohun tí Wọ́n fi rán mi níṣẹ́, àfi kí ó wà nínú àwọn èrò Iná.”
Ní ti āyah tí à ń tọsẹ rẹ̀ lọ́wọ́ àti àwọn irú rẹ̀ méjèèjì tí mo tọ́ka sí nínú sūrah al-Mọ̄’idah; 5:69 àti sūrah al- Hajj; 22:17, ìwọ̀nyẹn dúró lé ìdájọ́ ẹni tí ó kú nínú wọn lórí ìgbàgbọ́ òdodo nínú Allāhu pé Òun ni Ọlọ́hun ọ̀kan ṣoṣo tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àti iṣẹ́ rere nípa títẹ̀lé Ànábì àsìkò tiwọn ṣíwájú ìgbédìde Ànábì mìíràn.
Kíyè sí i, èyí kò wá túmọ̀ sí pé, ẹ̀sìn kan ń jẹ́ yẹhūdiyyah tàbí nasrọ̄niyyah tàbí sọ̄bi’iyyah ní ọ̀dọ̀ Allāhu. Ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ni pé, ni ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ àwọn orúkọ wọ̀nyẹn, wọ́n jẹ́ àlàjẹ́ fún àwọn mùsùlùmí lẹ́yìn ìpapòdà Ànábì Mūsā - kí ọlà Allāhu máa bá a - àti lẹ́yìn gbígbé Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - gun sánmọ̀ lọ. Àmọ́ wọ́n padà gbé orúkọ ’Islām jù sílẹ̀ pátápátá, wọ́n sì fi àwọn àlàjẹ́ wọ̀nyẹn rọ́pò rẹ̀. Lẹ́yìn náà, olúkùlùkù wọn yí ẹ̀sìn ’Islām wọn padà sí ohun mìíràn pátápátá. Ìgbàgbọ́ wọn sì padà di àìgbàgbọ́ mọ́ wọn lọ́wọ́. Èyí ni Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - tọ́ka sí nínú sūrah āl ‘Imrọ̄n; 3:19, sūrah aṣ-Ṣūrọ̄; 42:13-14, al-Jāthiyah; 45:16-17 àti sūrah al-Bayyinnah; 98:1-8. Ẹ tún ka āyah 111-112 níwájú nínú sūrah al Baƙọrah.
Ẹ̀kọ́ pàtàkì tí āyah tí à ń tọsẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ fẹ́ kọ́ àwa mùsùlùmí ni ìwọ̀nyí:
Ìkíní: Kí á má ṣe fi orúkọ mìíràn jìrọ̀ orúkọ ẹ̀sìn wa, ’Islām.
Ìkejì: Bí a bá tún sọra wa ní orúkọ àlàjẹ́ mìíràn lẹ́yìn “mùsùlùmí”, ohun tí ń jẹ́ “Islām” kò gbọ́dọ̀ kúrò nínú ayé wa.
Ìkẹta: Ọ̀tọ̀ ni orúkọ, ọ̀tọ̀ ni ìgbàgbọ́ àti iṣẹ́. Méjèèjì ni a bùkátà sí. Àmọ́ ìgbàgbọ́ àti iṣẹ́ ló máa sọni ní orúkọ. Nítorí náà, bí ènìyàn bá pe ara rẹ̀ ní mùsùlùmí lórí ahọ́n, àmọ́ kò ṣe ohun tí ń jẹ́ ’Islām níbi àdìsọ́kàn àti ìjọ́sìn àti ìwà rere, pípe ara rẹ̀ ní mùsùlùmí kò níí rọ̀ ọ́ lọ́rọ̀ kan kan níbi ìyà Iná. Èyí ló mú kí “wa lathīna āmọnū” jẹyọ pọ̀ pẹ̀lú àwọn yẹ̀húdí àti àwọn nasọ̄rọ̄ nínú āyah náà. W-Allāhu ’a‘lam.
Tefsiri na arapskom jeziku:
 
Prijevod značenja Ajet: (62) Sura: Sura el-Bekara
Indeks sura Broj stranice
 
Prijevod značenja časnog Kur'ana - Prijevod na joruba jezik - Sadržaj prijevodā

Prijevod značenja Plemenitog Kur'ana na joruba jezik - Šejh Ebu Rahima MIhail Akvinski, 1432. godine po Hidžri.

Zatvaranje