Prijevod značenja časnog Kur'ana - Prijevod na joruba jezik * - Sadržaj prijevodā

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Prijevod značenja Ajet: (31) Sura: Sura en-Nur
وَقُل لِّلۡمُؤۡمِنَٰتِ يَغۡضُضۡنَ مِنۡ أَبۡصَٰرِهِنَّ وَيَحۡفَظۡنَ فُرُوجَهُنَّ وَلَا يُبۡدِينَ زِينَتَهُنَّ إِلَّا مَا ظَهَرَ مِنۡهَاۖ وَلۡيَضۡرِبۡنَ بِخُمُرِهِنَّ عَلَىٰ جُيُوبِهِنَّۖ وَلَا يُبۡدِينَ زِينَتَهُنَّ إِلَّا لِبُعُولَتِهِنَّ أَوۡ ءَابَآئِهِنَّ أَوۡ ءَابَآءِ بُعُولَتِهِنَّ أَوۡ أَبۡنَآئِهِنَّ أَوۡ أَبۡنَآءِ بُعُولَتِهِنَّ أَوۡ إِخۡوَٰنِهِنَّ أَوۡ بَنِيٓ إِخۡوَٰنِهِنَّ أَوۡ بَنِيٓ أَخَوَٰتِهِنَّ أَوۡ نِسَآئِهِنَّ أَوۡ مَا مَلَكَتۡ أَيۡمَٰنُهُنَّ أَوِ ٱلتَّٰبِعِينَ غَيۡرِ أُوْلِي ٱلۡإِرۡبَةِ مِنَ ٱلرِّجَالِ أَوِ ٱلطِّفۡلِ ٱلَّذِينَ لَمۡ يَظۡهَرُواْ عَلَىٰ عَوۡرَٰتِ ٱلنِّسَآءِۖ وَلَا يَضۡرِبۡنَ بِأَرۡجُلِهِنَّ لِيُعۡلَمَ مَا يُخۡفِينَ مِن زِينَتِهِنَّۚ وَتُوبُوٓاْ إِلَى ٱللَّهِ جَمِيعًا أَيُّهَ ٱلۡمُؤۡمِنُونَ لَعَلَّكُمۡ تُفۡلِحُونَ
Sọ fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin pé kí wọ́n rẹ ojú wọn nílẹ̀, kí wọ́n sì ṣọ́ abẹ́ wọn. Wọn kò gbọ́dọ̀ ṣàfi hàn ọ̀ṣọ́ wọn àfi èyí tí ó bá hàn nínú rẹ̀¹. Kí wọ́n fi ìbòrí wọn bo igbá-àyà wọn.² Àti pé wọn kò gbọ́dọ̀ ṣàfi hàn ọ̀ṣọ́ wọn àfi fún àwọn ọkọ wọn tàbí àwọn bàbá wọn tàbí àwọn bàbá ọkọ wọn tàbí àwọn ọmọkùnrin wọn tàbí àwọn ọmọkùnrin ọkọ wọn tàbí àwọn arákùnrin wọn tàbí àwọn ọmọkùnrin arákùnrin wọn tàbí àwọn ọmọkùnrin arábìnrin wọn tàbí àwọn obìnrin (ẹgbẹ́) wọn tàbí àwọn ẹrúkùnrin wọn tàbí àwọn tó ń tẹ̀lé obìnrin fún iṣẹ́ rírán, tí wọ́n jẹ́ ọkùnrin akúra tàbí àwọn ọmọdé tí kò dá ìhòhò àwọn obìnrin mọ̀.³ Wọn kò gbọ́dọ̀ fi ẹsẹ̀ wọn rin ìrin-kokokà nítorí kí àwọn (ènìyàn) lè mọ ohun tí wọ́n fi pamọ́ (sára) nínú ọ̀ṣọ́ wọn. Kí gbogbo yín sì ronú pìwàdà sọ́dọ̀ Allāhu, ẹ̀yin onígbàgbọ́ òdodo nítorí kí ẹ lè jèrè.4
1. Ìyapa-ẹnu wà lórí “àfi èyí tí ó bá hàn nínú rẹ̀” nítorí pé àgbọ́yé méjì ni àwọn onímọ̀ ẹ̀sìn mú wá lórí rẹ̀.
Àgbọ́yé kìíní ni pé, ojú àti ọwọ́ obìnrin ni ìtúmọ̀ “àfi èyí tí ó bá hàn nínú rẹ̀.” Ojú ni iwájú orí. Ọwọ́ sì ni ọmọníka àti àtẹ́lẹwọ́. Àgbọ́yé kejì ni pé, ohun tí wọ́n bá rí lára obìnrin lẹ́yìn tí ó ti fi aṣọ jilbāb bo gbogbo ara rẹ̀ tán pátápátá láì yọ ojú àti ọwọ́ sílẹ̀ ni ìtúmọ̀ “àfi èyí tí ó bá hàn nínú rẹ̀.”
Pẹ̀lú àgbọ́yé kejì yìí, èyí tí ó bá hàn nínú rẹ̀ kò lè tayọ rírí aṣọ jilbāb tí obìnrin wọ̀ jáde àti rírí ọ̀wọ́ abala ara tí ó bá ṣèèsì ṣí sílẹ̀ nípasẹ̀ atẹ́gùn.
Àgbọ́yé méjèèjì wọ̀nyí ló kúkú wọlé, àmọ́ àyè tí àgbọ́yé kìíní kejì ti wúlò ló yàtọ̀ síra wọn.
Bí “àfi èyí tí ó bá hàn nínú rẹ̀” bá túmọ̀ sí ojú àti ọwọ́ obìnrin, ìyẹn ní àsìkò tí irú obìnrin bẹ́ẹ̀ bá wà nínú yàrá pẹ̀lú ọ̀wọ́ àwọn ìsọ̀rí àwọn ènìyàn tí Allāhu - tó ga jùlọ - kà kalẹ̀ nínú āyah yìí. Àgbọ́yé yìí ló sì tẹ̀ṣùwọ̀n jùlọ nítorí pé, nínú āyah yìí kan náà ni a ti rí ojútùú ọ̀rọ̀ náà. Irúfẹ́ ìmúra náà sì ni obìnrin gbọ́dọ̀ lò lórí ìrun kíkí nínú yàrá rẹ̀.
Àmọ́ bí “àfi èyí tí ó bá hàn nínú rẹ̀” bá túmọ̀ sí ohun tí wọ́n bá rí lára obìnrin lẹ́yìn tí ó ti fi aṣọ jilbāb bo gbogbo ara rẹ̀ tán pátápátá, láì yọ ojú àti ọwọ́ sílẹ̀, ìyẹn ní àsìkò tí irú obìnrin bẹ́ẹ̀ bá wà ní ìta ilé, òde àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Kíyè sí i, tí āyah yìí kò bá dárúkọ jilbāb, sūrah al-’Ahzāb; 33:59 ti dárúkọ rẹ̀. Àlòpọ̀ mọ́ra wọn sì ni àwọn āyah, a ò gbọdọ̀ lòkan dákan sí. Bákan náà, tí āyah yìí kò bá dárúkọ ojú àti ọwọ́ fún bíbò ní òde tàbí bíbò ní ọ̀dọ̀ àwọn ọkùnrin mìíràn yàtọ̀ sí àwọn ìsọ̀rí ènìyàn tí āyah yìí kà sílẹ̀, sunnah Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ti fi rinlẹ̀ pé ẹ̀há híhá kó ojú àti ọwọ́ bíbò sínú. Ibi tí ọ̀rọ̀ fífi jilbāb bo ojú àti ọwọ́ mọ́ra wọn pátápátá lè ṣẹ́kù sí báyìí ni ipò tí ṣíṣe bẹ́ẹ̀ wà nínú ìdájọ́ ẹ̀sìn. Ṣé dandan ni tàbí sunnah? Ìyẹn ni pé, ṣe àìbojú bọwọ́ mọ́ jilbāb lè já sí ìyà ní ọ̀run tàbí àìṣe rẹ̀ kò la ìyà kan kan lọ tayọ pípàdánù ẹ̀san rẹ̀ ní ọ̀run?
Dandan ni fífi jilbāb bo ojú àti ọwọ́ mọ́ra wọn pátápátá nítorí pé, ìwà ẹ̀ṣẹ̀ ni fún àwọn obìnrin tí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀ àfi àwọn arúgbó lóbìnrin nìkan, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe rinlẹ̀ nínú āyah 60 níwájú nínú sūrah yìí. Àmọ́ àì lo jilbāb kò sọ ni di kèfèrí, àfi tí onítọ̀ún bá takò ó.
2. Ní ìbámu sí āyah yìí ìbòrí obìnrin gbọdọ̀ bó gbogbo orí, ọrùn, èjìká àti igbá àyà obìnrin pátápátá. Èyí tún kó ojú bíbò sínú. Èyí sì ni àgbọ́yé àwọn obìnrin àkọ́kọ́ níkété tí āyah yìí sọ̀kalẹ̀. (kitāb at-Tafsīr, al-Bukọ̄riy).
3. Ọmọdé tí kò dá ìhòhò àwọn obìnrin mọ̀ ni ọmọ kékeré tí kò mọ ohun tí wọ́n ń pè ní obìnrin nítorí kíkéré ọjọ́ orí rẹ̀ ṣíwájú bíbàlágà rẹ̀. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah an-Nisā’; 4:6.
4. Kíyè sí i, nínú àwọn tí ẹlẹ́hàá lè ṣíjú fún ni irú àwọn ìsọ̀rí ènìyàn tó jẹyọ nínú āyah yìí àmọ́ tí àwọn ènìyàn náà jẹ́ ẹbí ìyá tó fún un ní ọyàn mú ní kékeré nígbà tí kò tí ì já lẹ́nu ọyàn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àṣà gbígbé ọmọ fún obìnrin mìíràn láti fún un lọ́yàn mu kò wọ́ pọ̀ láààrin àwa ọmọ Yorùbá, a gbọ́dọ̀ mọ àwọn ìdájọ́ tó jẹmọ́ ọn bí ó bá ṣẹlẹ̀. Bí àpẹ̀ẹrẹ, ẹlẹ́hàá lè ṣíjú fún ọmọkùnrin ìyá tó fún un lọ́yàn mu nítorí pé, arákùnrin rẹ̀ ni nípasẹ̀ ọyàn.
Tefsiri na arapskom jeziku:
 
Prijevod značenja Ajet: (31) Sura: Sura en-Nur
Indeks sura Broj stranice
 
Prijevod značenja časnog Kur'ana - Prijevod na joruba jezik - Sadržaj prijevodā

Prijevod značenja Plemenitog Kur'ana na joruba jezik - Šejh Ebu Rahima MIhail Akvinski, 1432. godine po Hidžri.

Zatvaranje