Prijevod značenja časnog Kur'ana - Prijevod na joruba jezik * - Sadržaj prijevodā

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Prijevod značenja Ajet: (46) Sura: Sura el-Kasas
وَمَا كُنتَ بِجَانِبِ ٱلطُّورِ إِذۡ نَادَيۡنَا وَلَٰكِن رَّحۡمَةٗ مِّن رَّبِّكَ لِتُنذِرَ قَوۡمٗا مَّآ أَتَىٰهُم مِّن نَّذِيرٖ مِّن قَبۡلِكَ لَعَلَّهُمۡ يَتَذَكَّرُونَ
Ìwọ kò sì sí ní ẹ̀bá àpáta náà, nígbà tí A pèpè, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ nítorí kí o lè ṣèkìlọ̀ fún àwọn ènìyàn tí olùkìlọ̀ kan kò wá bá rí ṣíwájú rẹ nítorí kí wọ́n lè lo ìrántí.¹
1. Ànábì ’Ibrọ̄hīm - kí ọlà Allāhu máa bá a - àti àkọ́bí rẹ̀ Ànábì ’Ismā‘īl - kí ọlà Allāhu máa bá a - dé ìlú Mọkkah ṣíwájú Ànábì wa Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -, àmọ́ kì í ṣe pé Allāhu rán wọn níṣẹ́ sí ará ìlú Mọkkah. Bẹ́ẹ̀ náà ni èyíkéyìí Ànábì Ọlọ́hun tí ìtàn bá sọ nípa rẹ̀ pé ó dé ìlú Mọkkah tàbí ìlú mìíràn nínú àwọn ìlú Lárúbáwá. Ó lè dé ibẹ̀ rí, àmọ́ Allāhu kò rán an níṣẹ́ sí wọn. Bí àpẹ̀ẹrẹ, Ànábì ‘Ismā‘īl gan-an - kí ọlà Allāhu máa bá a - tí wọ́n gbé wá wò láti òpóǹló nínú ìlú Mọkkah, Allāhu – tó ga jùlọ - kò kúkú rán an níṣẹ́ sí ìran Lárúbáwá ní àpapọ̀ tàbí sí ìlú kan nínú ìlú àwọn Lárúbáwá. Àmọ́ Allāhu - tó ga jùlọ - rán an níṣẹ́ sí ọ̀wọ́ ẹbí rẹ̀ nínú ìdílé ìyàwó rẹ̀ tó jẹ́ Lárúbáwá. Ìyẹn sì ni àwọn ènìyàn rẹ̀ àti ìjọ rẹ̀. Èyí wà ní ìbámu sí sūrah Mọryam; 19:54-55.
Bákan náà, tòhun ti bí Ànábì Mūsā - kí ọlà Allāhu máa bá a - ṣe jẹ́ Òjíṣẹ́ tí wọ́n fún ní tírà Taorāt, iṣẹ́ jíjẹ́ rẹ̀ àti òfin rẹ̀ kò kúkú kan àwọn ènìyàn Kidr - kí Allāhu yọ́nú sí i -. Kódà Ànábì Mūsā - kí ọlà Allāhu máa bá a - ìbá tí mọ̀ pé àwọn ènìyàn kan tún wà ní àyè mìíràn lábẹ́ Kidr tí kò bá jẹ́ pé Allāhu pa á láṣẹ láti ṣàbẹ̀wò sí ọ̀dọ̀ rẹ̀.
Wàyí bí a ṣe rí àwọn āyah kan tó ń fi rinlẹ̀ pé kò sí ìjọ tí Allāhu kò rán Ànábì tàbí Òjíṣẹ́ kan sí (gẹ́gẹ́ bí ó ṣe rinlẹ̀ nínú sūrah ar-Ra‘d; 13:7, sūrah an-Nahl; 16:36 àti sūrah Fātir; 35:24) bẹ́ẹ̀ náà l’a rí àwọn āyah mìíràn tó ń fi rinlẹ̀ pé Allāhu kò rán Òjíṣẹ́ tàbí Ànábì kan rí sí àwọn Lárúbáwá (gẹ́gẹ́ bí ó ṣe rinlẹ̀ nínú sūrah al-Ƙọsọs; 28:46, sūrah Saba’; 34:44, sūrah as-Sajdah; 32:3 àti sūrah Yāsīn; 36:6.)
Ẹ rántí àlàyé tí mo mú wá lórí iṣẹ́ jíjẹ́ tí Allāhu fi rán Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ’Isma‘īl - kí ọlà Allāhu máa bá a - àti iṣẹ́ jíjẹ́ tí Allāhu fi rán Òjíṣẹ́ Rẹ̀ Mūsā - kí ọlà Allāhu máa bá a -. Lẹ́yìn náà, àgbọ́yé tó wà nínú àwọn āyah tó wá lórí àìsí Òjíṣẹ́ fún àwọn Lárúbáwá ni pé, kò sí Òjíṣẹ́ kan tí Allāhu gbé dìde láààrin wọn sí gbogbo ìran wọn ní àpapọ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Lárúbáwá ní àǹfààní láti gbọ́ nípa Ànábì ’Ibrọ̄hīm àti ọmọ rẹ̀ Ànábì ’Ismọ̄‘īl pé, Allāhu rán wọn níṣẹ́ sí àwọn ènìyàn kan, àti pé àwọn méjèèjì ni wọ́n mọ Ilé Kaaba ga sókè, àwọn ìran Lárúbáwá tún ní àǹfààní láti rìn kan àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl. Nípasẹ̀ èyí, wọ́n tún gbúròó gbọ́ nípa òǹkà púpọ̀ nínú àwọn Òjíṣẹ́ ọmọ ’Isrọ̄’īl, ní pàtàkì jùlọ nípa Ànábì Mūsā - kí ọlà Allāhu máa bá a -àti Ànábì ‘Īsā - kí ọlà Allāhu máa bá a -, àmọ́ kì í ṣe pé àwọn wọ̀nyí jẹ́ Ànábì Lárúbáwá. Paríparí rẹ̀ ni pé, ìgbà pípẹ́ gbọọrọ tún wà láààrin ìgbà tí Allāhu gbé Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - gun sánmọ̀ lọ láàyè àti ìgbà tí Allāhu gbé Ànábì ìkẹ́yìn dìde, ìyẹn Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -, gẹ́gẹ́ bí èyí ṣe rinlẹ̀ nínú sūrah al-Mọ̄’idah; 5:19.
Ìdí nìyí tí àwọn onímọ̀ ẹ̀sìn fi sọ pé, irúfẹ́ àwọn ènìyàn to ṣẹ̀mí láààrin ìgbà náà ni wọ́n ń pè ní “’ahlu-l-fatrah”. Ọjọ́ Àjíǹde sì ni Allāhu máa tó yanjú ọ̀rọ̀ wọn. Allāhu - tó ga jùlọ - kúkú nímọ̀ nípa ẹni tí ó máa tẹ̀lé Òjíṣẹ́ àti ẹni tí kò níí tẹ̀lé e nínú wọn bí Ó bá jẹ́ pé Allāhu tètè rán Òjíṣẹ́ níṣẹ́ sí wọn. Àpẹ̀ẹrẹ wọn tún ni àwọn ọmọdé tó kú ṣíwájú bíbàlágà. Allāhu ti nímọ̀ nípa ohun tí wọ́n máa ṣe tí wọ́n bá dàgbà. Èyí ni òdodo ọ̀rọ̀ nípa ìdájọ́ àwọn “’ahlu-l-fatrah”, ìyẹn àwọn tó ti kú ṣíwájú iṣẹ́ jíjẹ́ Ànábì Muhammad - kí ọlà Allāhu máa bá a - àti àwọn ènìyàn mìíràn tó ti kú ṣíwájú tiwọn àti ṣíwájú kí Allāhu tó gbé Ànábì dìde fún wọn.
Kíyè sí i, Allāhu Ẹlẹ́dàá ti fi àdámọ́ òye àtinúwá sára gbogbo ẹ̀dá Rẹ̀ láti jìnnà sí jíjọ̀sìn fún òrìṣà nítorí gbogbo ẹ̀dá l’ó ní òye pé kì í ṣe òrìṣà ni ẹlẹ́dàá àwọn, àmọ́ kò sí òye àtinúwá fún ìmọ̀ nípa bí wọ́n máa ṣe jọ́sìn fún Allāhu Ẹlẹ́dàá wọn àfi kí wọ́n ní Òjíṣẹ́ kan tó máa jẹ́ aṣíwájú fún wọn gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ni rere. Ìdí nìyí tí Allāhu fi gbé Ànábì Muhammad - kí ọlà Allāhu máa bá a - dìde ní àrà ọ̀tọ̀. Ìtúmọ̀ “ní àrà ọ̀tọ̀” ni pé, dípò kí ó jẹ́ Ànábì fún ìran Lárúbáwá nìkan gẹ́gẹ́ bí ìkọ̀ọ̀kan àwọn Ànábì tó ṣíwájú rẹ̀ ṣe jẹ́, ńṣe ni Allāhu, nínú ọlá Rẹ̀, ṣe é ni Ànábì gbogbo ayé pátápátá. Allāhu tí Ó ṣe ìṣẹ̀dá Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ní àrà ọ̀tọ̀ nípasẹ̀ àìlo àtọ̀ ọkùnrin kan kan fún ìṣẹ̀dá rẹ̀ ní ìyàtọ̀ sí ìkọ̀ọ̀kan àwọn Òjíṣẹ́ tó ṣíwájú rẹ̀, Allāhu l’Ó kúkú ṣe Ànábì Muhammad ní Òjíṣẹ́ gbogbo ayé, tí kò sì sí Òjíṣẹ́ kan tí Allāhu ṣe bẹ́ẹ̀ rí fún ṣíwájú rẹ̀. Nítorí náà, Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ni Ànábì àti Òjíṣẹ́ àkọ́kọ́ fún ẹbí rẹ̀ àti ìran rẹ̀, ìran Lárúbáwá, gẹ́gẹ́ bí ó tún ṣe jẹ́ Ànábì àti Òjíṣẹ́ Ìkẹ́yìn fún àpapọ̀ Lárúbáwá àti àwọn elédè mìíràn pátápátá. Wallāhu ’a‘lam.
Tefsiri na arapskom jeziku:
 
Prijevod značenja Ajet: (46) Sura: Sura el-Kasas
Indeks sura Broj stranice
 
Prijevod značenja časnog Kur'ana - Prijevod na joruba jezik - Sadržaj prijevodā

Prijevod značenja Plemenitog Kur'ana na joruba jezik - Šejh Ebu Rahima MIhail Akvinski, 1432. godine po Hidžri.

Zatvaranje