Prijevod značenja časnog Kur'ana - Prijevod na joruba jezik * - Sadržaj prijevodā

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Prijevod značenja Ajet: (55) Sura: Sura Gafir
فَٱصۡبِرۡ إِنَّ وَعۡدَ ٱللَّهِ حَقّٞ وَٱسۡتَغۡفِرۡ لِذَنۢبِكَ وَسَبِّحۡ بِحَمۡدِ رَبِّكَ بِٱلۡعَشِيِّ وَٱلۡإِبۡكَٰرِ
Nítorí náà, ṣe sùúrù. Dájúdájú àdéhùn Allāhu ni òdodo. Tọrọ àforíjìn fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ.¹ Kí o sì ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ẹyìn fún Olúwa rẹ² ní ìrọ̀lẹ́ àti ní òwúrọ̀ kùtùkùtù.
1. Irú gbólóhùn yìí tún wà nínú sūrah Muhammad; 47:19. Ẹ̀̀ṣẹ̀ wo ni Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - dá? Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - kì i ṣé ẹlẹ́ṣẹ̀ tàbí ọ̀daràn tàbí olùyapa àṣẹ Allāhu - Ọba Aláforíjìn -. Àmọ́ nítorí pé, Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - kì í ṣe mọlāika, kì í sì ṣe ọlọ́hun, ó ṣeé ṣe kí ó ṣe ìṣe kan tí Allāhu máa sọ di ní ẹ̀ṣẹ̀ fún un. Irúfẹ́ àwọn ìṣe náà kò tàbùkù ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ànábì àti Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun. Kò sì yọ ọ́ kúrò nípò àwòkọ́ṣe rere fún gbogbo ẹ̀dá.
Allāhu kì í kúkú ṣe Ọba alábòsí, Ó ṣàfi hàn ẹ̀ṣẹ̀ tí Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - dá.
Àṣìṣe kìíní tó di ẹ̀ṣẹ̀: Títú tí Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - tú àwọn ẹrú ogun Badr sílẹ̀ dípò pípa wọ́n, ó di ẹ̀ṣẹ̀ sí i lọ́rùn nítorí pé, àwọn tí Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - tú sílẹ̀ wọ̀nyí, àwọn ni olórí àwọn ọ̀ṣẹbọ nínú ìlú Mọkkah. Wọ́n sì ti pa àwọn mùsùlùmí kan nípakúpa ṣíwájú kí ọwọ́ tó tẹ àwọn náà lójú ogun Badr. Àmọ́ ohun tí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - rò tó fi tú wọn sílẹ̀ ni pé, àwùjọ mùsùlùmí bùkátà sí owó àti ẹ̀kọ́ mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà. Wọ́n sì gba owó ìtúsílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ẹrú kan nínú àwọn ẹrú ogun náà, nígbà tí àwọn ẹrú mìíràn rí ìtúsílẹ̀ gbà nípasẹ̀ kíkọ́ àwọn Sọhābah kan ní ẹ̀kọ́ mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà. Ní òdodo ni pé, ìgbésẹ̀ yìí dára. Àmọ́ Allāhu kà á kún àṣìṣe. Ó sì jẹ́ kí ó di mímọ̀ fún un pé, pípa wọ́n lásìkò náà l’ó lóore ju títú wọn sílẹ̀ wọn lọ nítorí pé, àìpa wọ́n l’ó padà bí àwọn ogun mìíràn.
Ńṣe ni àwọn ọ̀ṣẹbọ náà lọ túnra mú. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé àwọn ogun mìíràn dìde. Wọn ìbá ti pa wọ́n nígbà àkọ́kọ́, ogun ìbá ti dáwọ́ dúró. Èyí ni Allāhu sọ nípa rẹ̀ nínú sūrah al-’Anfāl; 8:67 - 71. Allāhu sì padà yọ̀ǹda ìtúsílẹ̀ ẹrú ogún pẹ̀lú owó ìtúsílẹ̀ tàbí ní ọ̀fẹ́ fún Ànábì Rẹ̀ - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - nínú sūrah Muhammad; 47:4.
Àṣìṣe kejì tó di ẹ̀ṣẹ̀: Àìtètè gbà kí Zaed ọmọ Hārithah - kí Allāhu yọ́nú sí i - kọ Zaenab ọmọ Jahṣ - kí Allāhu yọ́nú sí i - sílẹ̀ lẹ́yìn tí Allāhu ti sọ ọ́ di mímọ̀ fún Ànábì Rẹ̀ - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - pé Zaed ti lẹ́tọ̀ọ́ láti kọ̀ ọ́ sílẹ̀ níwọ̀n ìgbà tí kò bùkátà sí i mọ́. Ohun tí ó sì mú kí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - kóra ró ni pé, ó ń páyà pé àwọn aláìsàn-ọkàn yóò máa sọ pé, “Ó gba ìyàwó lọ́wọ́ ọmọ rẹ̀, ó sì fi ṣaya!”. Ọ̀rọ̀ kò sì rí bẹ́ẹ̀ nítorí pé, Zaed ọmọ Hārithah - kí Allāhu yọ́nú sí i - kì í ṣe ọmọbíbí inú Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -. Àti pé kò sí èèwọ̀ nínú kí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - fẹ́ Zaenab ọmọ Jahṣ lẹ́yìn tí Allāhu ti pa á láṣẹ fún un láti fi ṣaya. Èyí ni Allāhu sọ nípa rẹ̀ nínú sūrah al-’Ahzāb; 33:37-38. Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - sì ṣẹ́rí padà síbi ohun tí Allāhu yàn fún un.
Àṣìṣe kẹta tó di ẹ̀ṣẹ̀: Sísọ tí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - sọ fún ọ̀kan nínú àwọn ìyàwó rẹ̀ pé òun kò níí fi ẹrúbìnrin rẹ̀ kan ṣaya. Sísọ bẹ́ẹ̀ jẹ́ àṣìṣe fún un nítorí pé, ohun tí Allāhu ṣe ní ẹ̀tọ́ fún un ni ó fẹ́ ṣe ní èèwọ̀ fún ẹ̀mí ara rẹ̀ láti fi wá ìyọ́nú ìyàwó rẹ̀ kan. Èyí ni Allāhu sọ nípa rẹ̀ nínú sūrah at-Tahrīm; 66:1.
Àṣìṣe kẹ́rin tó di ẹ̀ṣẹ̀: Fífajúro tí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - fajú ro sí afọ́jú kan tí Allāhu ti ṣípayá ọkàn rẹ̀ fún gbígba ’Islām. Ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nip é, Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - wà pẹ̀lú ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ, tí ó ń ṣe wáàsí fún lọ́wọ́ nígbà tí afọ́jú yìí ń sáré bọ́ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - sì ti kó ọ̀rọ̀ ẹni tí ó ń bá sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ léyà tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí kò fi fẹ́ kí afọ́jú tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé di òun lọ́wọ́. Ṣíṣẹ bẹ́ẹ̀ l’ó di ẹ̀ṣẹ̀ sí i lọ́rùn gẹ́gẹ́ bí Allāhu ṣe fi ìdí èyí náà múlẹ̀ nínú sūrah ‘Abas; 80:1-11.
Ìwọ̀nyẹn ni àwọn àṣìṣe tó di ẹ̀ṣẹ̀ sí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - lọ́rùn. Kì í ṣe pé Ànábì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ ńla kan tàbí ọ̀daràn. Tòhun tí bí ó ṣe mọ yìí, Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - kò yé tọrọ àforíjìn lórí rẹ̀ títí di ọjọ́ ikú rẹ̀. Kódà Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - kò lè má tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Allāhu lórí ìwọ̀nyẹn nígbà ọgọ́rùn-ún lójúmọ́.
Ẹ̀kọ́ pàtàkì tí ó yẹ kí èyí kọ́ èmi àti ẹ̀yin ni pé, a kò gbọ́dọ̀ fojú bín-íntín wo èyíkéyìí àṣìṣe tàbí ẹ̀ṣẹ̀. A gbọ́dọ̀ kún fún títọrọ àforíjìn ni lọ́dọ̀ Allāhu, Aláforíjìn. Kò sí ohun tó dára tó rírí àforíjìn gbà lọ́dọ̀ Allāhu lórí gbogbo àṣìṣe wa ṣíwájú ọjọ́ ikú wa, irú àforíjìn yìí ni Allāhu ṣe fún Ànábì wa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -, tí Allāhu sì sọ ọ́ di mímọ̀ fún gbogbo ayé nínú sūrah al-Fath; 48:1 - 2.
Ìyẹn ni abala èyí tó jẹmọ́ àṣìṣe Ànábì wa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - lẹ́yìn tí ó di Ànábì àti Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -.
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah aṣ-Ṣẹrh; 94:3 fún abala kejì, èyí tó jẹmọ́ àṣìṣe rẹ̀ ṣíwájú kí ó tó di Ànábì àti Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -.
2. Ìyẹn ni pé, ṣe àfọ̀mọ́ Allāhu kúrò níbi gbogbo àdínkù àti àbùkù, kí o sì yìn Ín lógo pé, Ó pé tán pátápátá.
Tefsiri na arapskom jeziku:
 
Prijevod značenja Ajet: (55) Sura: Sura Gafir
Indeks sura Broj stranice
 
Prijevod značenja časnog Kur'ana - Prijevod na joruba jezik - Sadržaj prijevodā

Prijevod značenja Plemenitog Kur'ana na joruba jezik - Šejh Ebu Rahima MIhail Akvinski, 1432. godine po Hidžri.

Zatvaranje