Prijevod značenja časnog Kur'ana - Prijevod na joruba jezik * - Sadržaj prijevodā

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Prijevod značenja Ajet: (7) Sura: Sura el-Hudžurat
وَٱعۡلَمُوٓاْ أَنَّ فِيكُمۡ رَسُولَ ٱللَّهِۚ لَوۡ يُطِيعُكُمۡ فِي كَثِيرٖ مِّنَ ٱلۡأَمۡرِ لَعَنِتُّمۡ وَلَٰكِنَّ ٱللَّهَ حَبَّبَ إِلَيۡكُمُ ٱلۡإِيمَٰنَ وَزَيَّنَهُۥ فِي قُلُوبِكُمۡ وَكَرَّهَ إِلَيۡكُمُ ٱلۡكُفۡرَ وَٱلۡفُسُوقَ وَٱلۡعِصۡيَانَۚ أُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلرَّٰشِدُونَ
Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú Òjíṣẹ́ Allāhu wà lààrin yín.¹ Tí ó bá jẹ́ pé ó ń tẹ̀lé yín níbi ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú ọ̀rọ̀ (tó ń ṣẹlẹ̀) ni, dájúdájú ẹ̀yin ìbá ti kó ara yín sínú wàhálà. Ṣùgbọ́n Allāhu jẹ́ kí ẹ nífẹ̀ẹ́ sí ìgbàgbọ́ òdodo. Ó ṣe é ní ọ̀ṣọ́ sínú ọkàn yín. Ó sì jẹ́ kí ẹ kórira àìgbàgbọ́, ìwà burúkú àti ìyapa àṣẹ. Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn olùmọ̀nà.
1. Nítorí gbólóhùn yìí “Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú Òjíṣẹ́ Allāhu wà lààrin yín”, àwọn onibidiah bí ìjọ Tijaniyyah àti ìjọ Ahmadiyyah lérò pé a sì lè rí Ànábì wa Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - lẹ́yìn ikú rẹ̀ lójú ayé. Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Àmọ́ gbólóhùn náà dúró sórí “láààrin àsìkò ìṣẹ̀mí Ànábì wa Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - láààrin àwọn Sọhābah rẹ̀”. Irú gbólóhùn tó tún lọ bẹ́ẹ̀ ni èyí tó wà nínú sūrah al-Mujādilah; 58:12.
Tefsiri na arapskom jeziku:
 
Prijevod značenja Ajet: (7) Sura: Sura el-Hudžurat
Indeks sura Broj stranice
 
Prijevod značenja časnog Kur'ana - Prijevod na joruba jezik - Sadržaj prijevodā

Prijevod značenja Plemenitog Kur'ana na joruba jezik - Šejh Ebu Rahima MIhail Akvinski, 1432. godine po Hidžri.

Zatvaranje