Check out the new design

Prijevod značenja časnog Kur'ana - Prijevod na joruba jezik - Ebu Rahime Mikail * - Sadržaj prijevodā

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Prijevod značenja Sura: El-En'am   Ajet:
وَقَالُواْ هَٰذِهِۦٓ أَنۡعَٰمٞ وَحَرۡثٌ حِجۡرٞ لَّا يَطۡعَمُهَآ إِلَّا مَن نَّشَآءُ بِزَعۡمِهِمۡ وَأَنۡعَٰمٌ حُرِّمَتۡ ظُهُورُهَا وَأَنۡعَٰمٞ لَّا يَذۡكُرُونَ ٱسۡمَ ٱللَّهِ عَلَيۡهَا ٱفۡتِرَآءً عَلَيۡهِۚ سَيَجۡزِيهِم بِمَا كَانُواْ يَفۡتَرُونَ
Wọ́n tún wí pé: “Èèwọ̀ ni àwọn ẹran-ọ̀sìn àti n̄ǹkan oko wọ̀nyí. Ẹnì kan kò gbọdọ̀ jẹ ẹ́ àfi ẹni tí a bá fẹ́, pẹ̀lú ọ̀rọ̀ wọn láì ní ẹ̀rí lọ́wọ́.” - Àwọn ẹran-ọ̀sìn kan tún ń bẹ tí wọ́n ṣe ẹ̀yìn wọn ní èèwọ̀ (fún gígùn àti ẹrù rírù), àwọn ẹran kan tún ń bẹ tí wọn kì í fi orúkọ Allāhu pa. (Wọ́n fi àwọn n̄ǹkan wọ̀nyí) dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu ni. Ó sì máa san wọ́n ní ẹ̀san ohun tí wọ́n ń dá ní àdápa irọ́.
Tefsiri na arapskom jeziku:
وَقَالُواْ مَا فِي بُطُونِ هَٰذِهِ ٱلۡأَنۡعَٰمِ خَالِصَةٞ لِّذُكُورِنَا وَمُحَرَّمٌ عَلَىٰٓ أَزۡوَٰجِنَاۖ وَإِن يَكُن مَّيۡتَةٗ فَهُمۡ فِيهِ شُرَكَآءُۚ سَيَجۡزِيهِمۡ وَصۡفَهُمۡۚ إِنَّهُۥ حَكِيمٌ عَلِيمٞ
Wọ́n tún wí pé: “Ohun tí ń bẹ nínú ikùn àwọn ẹran-ọ̀sìn wọ̀nyí jẹ́ ti àwọn ọkùnrin wa nìkan, ó sì jẹ́ èèwọ̀ fún àwọn obìnrin wa.” Tí ó bá sì jẹ́ òkú ọmọ-ẹran, akẹgbẹ́ sì ni wọn nínú (ìpín) rẹ̀.[1] (Allāhu) yóò san wọ́n ní ẹ̀san irọ́ (ẹnu) wọn. Dájúdájú Òun ni Ọlọ́gbọ́n, Onímọ̀.
[1] Ìyẹn ni pé, bí ẹran-ọ̀sìn wọn bá bí ọlẹ̀ rẹ̀ ní ààyè, ọmọ ẹran náà máa jẹ́ ti ọkùnrin nìkan, wọn kò sì níí jẹ́ kí obìnrin ní ìpín kan nínú rẹ̀. Bí ó bá jẹ́ òkúmọ, ọkùnrin àti obìnrin sì dìjọ máa pín in.
Tefsiri na arapskom jeziku:
قَدۡ خَسِرَ ٱلَّذِينَ قَتَلُوٓاْ أَوۡلَٰدَهُمۡ سَفَهَۢا بِغَيۡرِ عِلۡمٖ وَحَرَّمُواْ مَا رَزَقَهُمُ ٱللَّهُ ٱفۡتِرَآءً عَلَى ٱللَّهِۚ قَدۡ ضَلُّواْ وَمَا كَانُواْ مُهۡتَدِينَ
Àwọn tó fi agọ̀ àti àìmọ̀ pa àwọn ọmọ wọn kúkú ti ṣòfò; wọ́n tún ṣe ohun tí Allāhu pa lésè fún wọn ní èèwọ̀, ní ti dídá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu. Wọ́n kúkú ti ṣìnà, wọn kò sì jẹ́ olùmọ̀nà.
Tefsiri na arapskom jeziku:
۞ وَهُوَ ٱلَّذِيٓ أَنشَأَ جَنَّٰتٖ مَّعۡرُوشَٰتٖ وَغَيۡرَ مَعۡرُوشَٰتٖ وَٱلنَّخۡلَ وَٱلزَّرۡعَ مُخۡتَلِفًا أُكُلُهُۥ وَٱلزَّيۡتُونَ وَٱلرُّمَّانَ مُتَشَٰبِهٗا وَغَيۡرَ مُتَشَٰبِهٖۚ كُلُواْ مِن ثَمَرِهِۦٓ إِذَآ أَثۡمَرَ وَءَاتُواْ حَقَّهُۥ يَوۡمَ حَصَادِهِۦۖ وَلَا تُسۡرِفُوٓاْۚ إِنَّهُۥ لَا يُحِبُّ ٱلۡمُسۡرِفِينَ
(Allāhu) Òun ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn (n̄ǹkan) ọgbà oko èyí tí ẹ̀ ń fọwọ́ ara yín gbìn àti èyí tó ń lalẹ̀ hù àti dàbínù àti irúgbìn tí (adùn) jíjẹ rẹ̀ yàtọ̀ síra wọn, àti èso zaetūn àti èso rummọ̄n tó jọra wọn àti èyí tí kò jọra wọn. Ẹ jẹ nínú èso rẹ̀ nígbà tí ó bá so, kí ẹ sì yọ Zakāh rẹ̀ ní ọjọ́ ìkórè rẹ̀. Kí ẹ sì má yàpà. Dájúdájú (Allāhu) kò nífẹ̀ẹ́ àwọn àpà.
Tefsiri na arapskom jeziku:
وَمِنَ ٱلۡأَنۡعَٰمِ حَمُولَةٗ وَفَرۡشٗاۚ كُلُواْ مِمَّا رَزَقَكُمُ ٱللَّهُ وَلَا تَتَّبِعُواْ خُطُوَٰتِ ٱلشَّيۡطَٰنِۚ إِنَّهُۥ لَكُمۡ عَدُوّٞ مُّبِينٞ
Ó sì ń bẹ nínú àwọn ẹran-ọ̀sìn, èyí tó lè ru ẹrù àti èyí tí kò lè ru ẹrù. Ẹ jẹ nínú ohun tí Allāhu pa lésè fún yín. Kí ẹ sì má ṣe tẹ̀lé àwọn ojú-ẹsẹ̀ aṣ-Ṣaetọ̄n;[1] dájúdájú òun ni ọ̀tá pọ́nńbélé fún yín.
[1] Àwọn ojú-ẹsẹ̀ aṣ-Ṣaetọ̄n nínú āyah yìí ni sísọ àwọn ẹran-ọ̀sìn kan di èèwọ̀ fún jíjẹ àti gígùn láì jẹ́ pé Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ló ṣe é ní èèwọ̀.
Tefsiri na arapskom jeziku:
 
Prijevod značenja Sura: El-En'am
Indeks sura Broj stranice
 
Prijevod značenja časnog Kur'ana - Prijevod na joruba jezik - Ebu Rahime Mikail - Sadržaj prijevodā

Preveo šejh Ebu Rahime Mikail Ajkoniji.

Zatvaranje