Prijevod značenja časnog Kur'ana - Prijevod na joruba jezik * - Sadržaj prijevodā

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Prijevod značenja Ajet: (185) Sura: Sura el-A'araf
أَوَلَمۡ يَنظُرُواْ فِي مَلَكُوتِ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَمَا خَلَقَ ٱللَّهُ مِن شَيۡءٖ وَأَنۡ عَسَىٰٓ أَن يَكُونَ قَدِ ٱقۡتَرَبَ أَجَلُهُمۡۖ فَبِأَيِّ حَدِيثِۭ بَعۡدَهُۥ يُؤۡمِنُونَ
Ṣé wọn kò wo ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ pẹ̀lú gbogbo n̄ǹkan tí Allāhu dá? Àmọ́ sá ó lè jẹ́ pé Àkókò ikú wọn ti súnmọ́. Nígbà náà, ọ̀rọ̀ wo ni wọn yóò gbàgbọ́ lẹ́yìn rẹ̀?¹
1. Gbólóhùn yìí "Nígbà náà, “hadīth wo” ọ̀rọ̀ wo ni wọn yóò gbàgbọ́ lẹ́yìn rẹ̀?" àti irú rẹ̀ tó wà nínú sūrah al-Mursalāt; 77:50 àti sūrah al-Jāthiyah; 45:6, àwọn kan lérò pé ó ń túmọ̀ sí pé, a ò gbọ́dọ̀ gbàgbọ́ nínú hadīth Ànábì kan kan, áḿbọ̀sìbọ́sí pé a óò máa fi ṣe ẹ̀rí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn.
Èsì: Wọ́n ti dojú ìtúmọ̀ āyah náà rú mọ́ra wọn lọ́wọ́ pátápátá. Ní àkọ́kọ́ ná, ọ̀rọ̀ arọ́pò-orúkọ tó wà nínú àpólà ọ̀rọ̀-orúkọ yìí “ba‘dahu” (lẹ́yìn rẹ̀) ń dúró fún n̄ǹkan méjì. Ìkíní: Ó dúró fún “ọjọ́ ikú àti ọjọ́ Àjíǹde”. Ìkejì: Ó ń dúró fún al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé.
Tí ó bá dúró fún “ọjọ́ ikú àti ọjọ́ Àjíǹde”, ìtúmọ̀ gbólóhùn “fabi ’ayyi hadīthin ba‘dahu yu’minūn” máa túmọ̀ sí pé, “ọ̀rọ̀ wo nínú ọ̀rọ̀ al-Ƙur’ān ni wọn yóò gbàgbọ́ lẹ́yìn tí ọjọ́ ikú wọn bá dé tàbí lẹ́yìn tí ọjọ́ Àjíǹde bá ṣẹlẹ̀? Bí wọ́n bá padà gba ọ̀rọ̀ al-Ƙu’ān gbọ́ lọ́jọ́ ikú wọn tàbí lọ́jọ́ Àjíǹde, kò lè wúlò fún wọn mọ́, kò sì lè rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ mọ́ nítorí pé, kò sí ìronúpìwàdà mọ́ tí ikú bá ti dé bá ẹ̀dá, kò sì sí ìronúpìwàdà mọ́ fún ẹ̀dá lọ́jọ́ Àjíǹde.” Èyí gan-an ni ìtúmọ̀ “fabi ’ayyi hadīthin ba‘dahu yu’minūn” nínú sūrah yìí àti nínú sūrah al-Mursalāt; 77:50 nítorí pé, ọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ ikú ló ṣíwájú nínú āyah tí à ń tọsẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ yìí . Bákan náà, ọ̀rọ̀ nípa àwọn tó pe ọjọ́ Àjíǹde nírọ́ ló ṣíwájú gbólóhùn náà nínú sūrah al-Mursalāt.
Tí ó bá sì jẹ́ pé ọ̀rọ̀ arọ́pò-orúkọ náà ń dúró fún al-Ƙur’ān, ìtúmọ̀ gbólóhùn “fabi ’ayyi hadīthin ba‘dahu yu’minūn” máa túmọ̀ sí pé, ọ̀rọ̀ irọ́ wo ni wọn yóò gbàgbọ́ lẹ́yìn tí al-Ƙur’ān ti mú ọ̀rọ̀ òdodo wá? Ṣé àwọn ìròrí ìgbà àìmọ́kan àti àwọn àṣà àìmọ́kan èyí tí ìran ẹnì kọ̀ọ̀kan jogún bá láti ọ̀dọ̀ àwọn bàbá ńlá wọn tí wọn kì í ṣe Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun, ṣé àwọn ìròrí wọn àti àwọn àṣà ìbọ̀rìṣà wọn ni wọn yóò máa lò lẹ́yìn al-Ƙur’ān? Èyí gan-an ni ìtúmọ̀ “fabi ’ayyi hadīthin ba‘dahu yu’minūn” nínú sūrah al-Jāthiyah; 45:6 nítorí pé gbólóhùn tó ṣíwájú rẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ āyah náà ń sọ̀rọ̀ nípa bí al-Ƙur’ān ṣe jẹ́ ọ̀rọ̀ òdodo. Èyí wá túmọ̀ sí pé, bí ènìyàn kò bá gbàgbọ́ nínú ọ̀rọ̀ òdodo al-Ƙur’ān, ọ̀rọ̀ irọ́ oríṣiríṣi l’ó máa kù ú kù tí ó máa gbàgbọ́ nínú rẹ̀.
Nítorí náà, “fabi ’ayyi hadīthin ba‘dahu yu’minūn” kò fi ọ̀nà kan kan túmọ̀ sí pé kí á má gbàgbọ́ nínú hadīth Ànábì wa Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà máa bá a -. Ẹnikẹ́ni kò wulẹ̀ lè gbọ́ àgbọ́yé al-Ƙur’ān àfi pẹ̀lú ìtọ́sọ́nà àwọn hadīth Ànábì wa Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà máa bá a -. Tí ẹnì kan bá sì ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn hadīth Ànábì wa Muhammad tó fẹsẹ̀ rinlẹ̀, onítọ̀ún ti wọ ipò kèfèrí títí ó máa fi ronú pìwàdà.
Tefsiri na arapskom jeziku:
 
Prijevod značenja Ajet: (185) Sura: Sura el-A'araf
Indeks sura Broj stranice
 
Prijevod značenja časnog Kur'ana - Prijevod na joruba jezik - Sadržaj prijevodā

Prijevod značenja Plemenitog Kur'ana na joruba jezik - Šejh Ebu Rahima MIhail Akvinski, 1432. godine po Hidžri.

Zatvaranje