Prijevod značenja časnog Kur'ana - Prijevod na joruba jezik * - Sadržaj prijevodā

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Prijevod značenja Ajet: (190) Sura: Sura el-A'araf
فَلَمَّآ ءَاتَىٰهُمَا صَٰلِحٗا جَعَلَا لَهُۥ شُرَكَآءَ فِيمَآ ءَاتَىٰهُمَاۚ فَتَعَٰلَى ٱللَّهُ عَمَّا يُشۡرِكُونَ
Ṣùgbọ́n nígbà tí Allāhu fún àwọn méjèèjì ní ọmọ rere, wọ́n sọ (àwọn ẹ̀dá kan) di akẹgbẹ́ fún Un nípasẹ̀ ohun tí Ó fún àwọn méjèèjì. Allāhu sì ga tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I.¹
1. Ta ni ọkọ àti ìyàwó nínú āyah yìí? Kí sì ni ẹbọ tí wọ́n ṣe nípasẹ̀ ọmọ wọn? Àwọn onímọ̀-ẹ̀sìn pín sí méjì lórí ìbéèrè àkọ́kọ́.
Igun kan nínú àwọn onímọ̀ ’Islām fi rinlẹ̀ pé Ànábì Ādam - kí ọlà Allāhu máa bá a - àti ìyá wa, Hawā’ - kí Allāhu yọ́nú sí i - ni àwọn ọkọ àti ìyàwó tí āyah náà ń tọ́ka sí ní ìbámu sí āyah 189 tó síwájú.
Igun kejì sọ pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé āyah 189 tó síwájú ń tọ́ka sí Ànábì Ādam - kí ọlà Allāhu máa bá a - àti ìyá wa, Hawā’ - kí Allāhu yọ́nú sí i -, àwọn àrọ́mọdọ́mọ wọn ni āyah 190 ń tọ́ka sí. Wọ́n ní ìdí nìyí tí ọ̀rọ̀-ìṣe tó parí āyah 190 fi wá pẹ̀lú ẹ̀hun ọ̀pọ̀, èyí tí ó ń fi hàn pé tọkọ tìyàwó yẹn kò mọ ní ènìyàn méjì pèrè. Wọ́n fi kún un pé, ìbá jẹ́ pé Ànábì Ādam - kí ọlà Allāhu máa bá a - àti ìyá wa, Hawā’ - kí Allāhu yọ́nú sí i - ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀ sí ni, ẹ̀hun èjì tí ó máa dúró fún ọ̀wọ́ àwọn méjèèjì nìkan ni kò bá parí āyah náà gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀ nínú āyah 189 tó ṣíwájú.
Ẹbọ tí wọ́n ṣe nípasẹ̀ ọmọ wọn ni sísọ ọmọ náà ni orúkọ tí ó fi àìmoore hàn sí Allāhu. Bí àpẹ̀ẹrẹ, kí Allāhu fún ènìyàn lọ́mọ, kí ènìyàn wá sọ ọmọ náà ni “ ‘abdu-ṣṣams, ‘abdul-ƙọmọr” dípò “ ‘abdullāh, ‘abdur-Rahmọ̄n” àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Wàyí, wọ́n ṣe àfitì ìtàn kan sí ọ̀dọ̀ ọmọ ‘Abbās - kí Allāhu yọ́nú sí àwọn méjèèjì -. Ìtàn náà wà nínú àwọn tírà tafsīr kan, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ibn Kathīr ka ìtàn náà mọ́ ara ìtàn irọ́ àwọn ọmọ Isrọ̄’īl. Àmọ́ ìtàn tí ẹnu kùn yìí kúkú ni àwọn tí wọ́n gbà pé Ànábì Ādam àti ìyá wa Hawā’ ni tọkọ tìyàwó tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀ sí rí mú lò láti fi túmọ̀ = = āyah náà. Kókó ìtàn náà ni pé, nígbà tí ìyá wa Hawā’ - kí Allāhu yọ́nú sí i - lóyún, Èṣù wá ba á ní àwòrán ènìyàn, ó sì sọ fún un pé, “Tí kò bá fẹ́ bí àwòrán ẹranko lọ́mọ tàbí tí kò bá fẹ́ kí ọmọ náà kú ní òpóǹló, kí ó sọ ọmọ náà ní “ ‘abdul-hārith”. Hawā’ - kí Allāhu yọ́nú sí i - kò dá a lóhùn, kò sì tẹ̀lé àṣẹ rẹ̀. Ó bí ọmọ. Ọmọ náà sì kú. Ó tún ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀ nígbà kejì. Àmọ́ nígbà tí ó lóyún ìkẹta, kò fẹ́ kí ó kú. Wọ́n sì sọ ọmọ náà ní “ ‘abdul-hārith”! Èyí ni Allāhu - Ọba tó ga jùlọ - pè ní ẹbọ nítorí pé, wọ́n tẹ̀lé àṣẹ tó yapa sí àṣẹ Allāhu pé wọn kò gbọ́dọ̀ tẹ̀lé ọ̀rọ̀ Èṣù. Kì í ṣe pé wọ́n gbé ẹbọ fún Èṣù láti fi wá ààbò fún ọmọ náà. Láti ìgbà náà ló ti di èèwọ̀ pọ́nńbélé nínú ìlànà ìsọmọlórúkọ láti ṣe àfitì “ẹrú” sí ọ̀dọ̀ ẹlòmíìràn lẹ́yìn Allāhu. Ànábì Ādam - kí ọlà Allāhu máa bá a - àti ìyá wa Hawā’ - kí Allāhu yọ́nú sí i - sì tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Allāhu lórí bí àwọn méjèèjì ṣe tẹ̀lé àṣẹ Èṣù níbi sísọ ọmọ wọn ní orúkọ tí Èṣù mú wá fún wọn, kì í ṣe pé wọ́n bímọ tán wọ́n wá ń bọ Èṣù bí àwọn kan ṣe máa ń bọ ìbejì. Allāhu sì tẹ́wọ́ gba ìronùpìwàdà wọn.
Tí àwọn nasọ̄rọ̄ bá wá tàbùkù Ànábì Ādam - kí ọlà Allāhu máa bá a - àti ìyá wa Hawā’ nípa èyí, ṣebí wọ́n sọ pé, Ànábì 'Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - tẹ̀lé àṣẹ Èṣù ni Èṣù fi rí òun náà mú lọ káàkiri láti dán olúwa wọn wò! Ànábì 'Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - kúkú tẹ̀lé àṣẹ Èsù nínú àwọn ìwé wọn, àmọ́ kò forí balẹ̀ fún Èṣù rárá. Ìyẹn wà nínú ìwé Luku 4: 1-13. Nítorí náà, Allāhu nìkan ṣoṣo ni kò lè ṣàṣìṣe.
Tefsiri na arapskom jeziku:
 
Prijevod značenja Ajet: (190) Sura: Sura el-A'araf
Indeks sura Broj stranice
 
Prijevod značenja časnog Kur'ana - Prijevod na joruba jezik - Sadržaj prijevodā

Prijevod značenja Plemenitog Kur'ana na joruba jezik - Šejh Ebu Rahima MIhail Akvinski, 1432. godine po Hidžri.

Zatvaranje