Prijevod značenja časnog Kur'ana - Prijevod na joruba jezik * - Sadržaj prijevodā

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Prijevod značenja Ajet: (59) Sura: Sura et-Tevba
وَلَوۡ أَنَّهُمۡ رَضُواْ مَآ ءَاتَىٰهُمُ ٱللَّهُ وَرَسُولُهُۥ وَقَالُواْ حَسۡبُنَا ٱللَّهُ سَيُؤۡتِينَا ٱللَّهُ مِن فَضۡلِهِۦ وَرَسُولُهُۥٓ إِنَّآ إِلَى ٱللَّهِ رَٰغِبُونَ
Àti pé (ìbá lóore fún wọn) tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú wọ́n yọ́nú sí ohun tí Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ fún wọn, kí wọ́n sì sọ pé: “Allāhu tó wa. Allāhu yó sì fún wa nínú oore àjùlọ Rẹ̀ àti pé Òjíṣẹ́ Rẹ̀ (sì máa pín ọrẹ)¹, dájúdájú ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni àwa ń wá oore sí.”
1. N̄ǹkan tí āyah yìí ń sọ ni pé, Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - lẹ́tọ̀ọ́ sí pípín àwọn ọrẹ tí Allāhu pín kàn án nínú àwọn oore ayé àrígbámú yálà nípasẹ̀ ọrọ̀ ogun, zakāh gbígbà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Èyí rí bẹ́ẹ̀ ní ìbámu sí āyah 58 tí ó ṣíwájú rẹ̀ àti āyah 60 tí ó tẹ̀lé e. Kì í ṣe pé Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ló ń pín oore ayé tàbí oore àjùlọ fún àwọn ẹ̀dá.
Tefsiri na arapskom jeziku:
 
Prijevod značenja Ajet: (59) Sura: Sura et-Tevba
Indeks sura Broj stranice
 
Prijevod značenja časnog Kur'ana - Prijevod na joruba jezik - Sadržaj prijevodā

Prijevod značenja Plemenitog Kur'ana na joruba jezik - Šejh Ebu Rahima MIhail Akvinski, 1432. godine po Hidžri.

Zatvaranje