Prijevod značenja časnog Kur'ana - Prijevod na joruba jezik * - Sadržaj prijevodā

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Prijevod značenja Ajet: (73) Sura: Sura et-Tevba
يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّبِيُّ جَٰهِدِ ٱلۡكُفَّارَ وَٱلۡمُنَٰفِقِينَ وَٱغۡلُظۡ عَلَيۡهِمۡۚ وَمَأۡوَىٰهُمۡ جَهَنَّمُۖ وَبِئۡسَ ٱلۡمَصِيرُ
Ìwọ Ànábì, gbógun ti àwọn aláìgbàgbọ́ àti àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí. Kí o sì le mọ́ wọn. Iná Jahanamọ ni ibùgbé wọn. Ìkángun náà sì burú.¹
1. Mẹ́ta ni gbogbo ènìyàn pín sí lórí òṣùwọ̀n ẹ̀sìn. Igun àkọ́kọ́ ni àwa mùsùlùmí tí a jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo. Igun yìí nìkan ló sì máa jèrè ní Ọjọ́ Àjíǹde. Igun kejì ni igun tó jẹ́ ìdàkejì sí igun àkọ́kọ́. Igun tí kì í ṣe mùsùlùmí rárá. Àwọn sì ni igun aláìgbàgbọ́ àti àwọn ọ̀ṣẹbọ.
Wàyí ní ti igun kẹta, àwọn ni igun alágàbàǹgebè. Igun yìí ni igun tí ó ń pe ara rẹ̀ ní mùsùlùmí, tí ó sì ń ṣe ìṣe mùsùlùmí. Wọ́n ń kírun wákàtí márààrún, wọ́n ń dojú kọ Ƙiblah, wọ́n ń gbààwẹ̀ Rọmọdọ̄n, wọ́n ń ṣe hajj, wọ́n sì ń wí kalmọtu-ṣṣahādah, àmọ́ wọn kò faramọ́ àwọn ìgbàgbọ́ òdodo àti àdìsọ́kàn Islām. Ìgbàgbọ́ igun kẹta yìí máa ń bá ti igun kejì lọ ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ìgbà. Ìsọ̀rí méjì sì ni àwọn igun ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí. Ìsọ̀rí àkọ́kọ́ ni igun àwọn ahlul-bid‘ah bí ìjọ Ahmadiyyah, Ìjọ Tijāniyyah, ìjọ Ƙọ̄diriyyah, ìjọ Ṣī‘ah. Ìsọ̀rí kejì ni gbogbo ẹnikẹ́ni tí ó ń pe ara rẹ̀ ní mùsùlùmí àmọ́ tí ó jẹ́ ọ̀rẹ́ àyò àti alátìlẹ́yìn fún àwọn kèfèrí àti àwọn ọ̀ṣẹbọ. Nítorí náà, āyah yìí ń pa àwa mùsùlùmí onígbàgbọ́ òdodo ní àṣẹ láti gbógun ti gbogbo ìjọ méjèèjì. Èyí sì máa jẹ́ nípasẹ̀ ṣíṣe wáàsí tó lágbára fún gbogbo wọn àti dídojú ìjà kọ èyí tí ó bá dojú ìjà kọ wá.
Tefsiri na arapskom jeziku:
 
Prijevod značenja Ajet: (73) Sura: Sura et-Tevba
Indeks sura Broj stranice
 
Prijevod značenja časnog Kur'ana - Prijevod na joruba jezik - Sadržaj prijevodā

Prijevod značenja Plemenitog Kur'ana na joruba jezik - Šejh Ebu Rahima MIhail Akvinski, 1432. godine po Hidžri.

Zatvaranje