Translation of the Meanings of the Noble Qur'an - Yoruba translation * - Translations’ Index

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Translation of the meanings Surah: Al-Hajj   Ayah:

Suuratul-Hajj

يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ ٱتَّقُواْ رَبَّكُمۡۚ إِنَّ زَلۡزَلَةَ ٱلسَّاعَةِ شَيۡءٌ عَظِيمٞ
Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ bẹ̀rù Olúwa yín. Dájúdájú ìmì tìtì Àkókò náà, n̄ǹkan ńlá ni.
Arabic explanations of the Qur’an:
يَوۡمَ تَرَوۡنَهَا تَذۡهَلُ كُلُّ مُرۡضِعَةٍ عَمَّآ أَرۡضَعَتۡ وَتَضَعُ كُلُّ ذَاتِ حَمۡلٍ حَمۡلَهَا وَتَرَى ٱلنَّاسَ سُكَٰرَىٰ وَمَا هُم بِسُكَٰرَىٰ وَلَٰكِنَّ عَذَابَ ٱللَّهِ شَدِيدٞ
(Àkókò náà ni) ọjọ́ tí ẹ máa rí i tí gbogbo obìnrin tó ń fún ọmọ lọ́mú mu yóò gbàgbé ọmọ tí ó ń fún lọ́mú àti pé gbogbo aboyún yó sì máa bí oyún wọn. Ìwọ yó sì rí àwọn ènìyàn tí ọtí yóò máa pa wọ́n. Ọtí kò sì pa wọ́n, ṣùgbọ́n ìyà Allāhu (tó) le (ló fà á).
Arabic explanations of the Qur’an:
وَمِنَ ٱلنَّاسِ مَن يُجَٰدِلُ فِي ٱللَّهِ بِغَيۡرِ عِلۡمٖ وَيَتَّبِعُ كُلَّ شَيۡطَٰنٖ مَّرِيدٖ
Ó sì ń bẹ nínú àwọn ènìyàn ẹni tó ń jiyàn nípa (ẹ̀sìn) Allāhu láì ní ìmọ̀. Ó sì ń tẹ̀lé gbogbo èṣù olórí kunkun.
Arabic explanations of the Qur’an:
كُتِبَ عَلَيۡهِ أَنَّهُۥ مَن تَوَلَّاهُ فَأَنَّهُۥ يُضِلُّهُۥ وَيَهۡدِيهِ إِلَىٰ عَذَابِ ٱلسَّعِيرِ
Wọ́n kọ ọ́ lé (Èṣù) lórí pé dájúdájú ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé e, ó máa ṣì í lọ́nà. Ó sì máa tọ́ ọ sí ọ̀nà ìyà Iná tó ń jo.
Arabic explanations of the Qur’an:
يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ إِن كُنتُمۡ فِي رَيۡبٖ مِّنَ ٱلۡبَعۡثِ فَإِنَّا خَلَقۡنَٰكُم مِّن تُرَابٖ ثُمَّ مِن نُّطۡفَةٖ ثُمَّ مِنۡ عَلَقَةٖ ثُمَّ مِن مُّضۡغَةٖ مُّخَلَّقَةٖ وَغَيۡرِ مُخَلَّقَةٖ لِّنُبَيِّنَ لَكُمۡۚ وَنُقِرُّ فِي ٱلۡأَرۡحَامِ مَا نَشَآءُ إِلَىٰٓ أَجَلٖ مُّسَمّٗى ثُمَّ نُخۡرِجُكُمۡ طِفۡلٗا ثُمَّ لِتَبۡلُغُوٓاْ أَشُدَّكُمۡۖ وَمِنكُم مَّن يُتَوَفَّىٰ وَمِنكُم مَّن يُرَدُّ إِلَىٰٓ أَرۡذَلِ ٱلۡعُمُرِ لِكَيۡلَا يَعۡلَمَ مِنۢ بَعۡدِ عِلۡمٖ شَيۡـٔٗاۚ وَتَرَى ٱلۡأَرۡضَ هَامِدَةٗ فَإِذَآ أَنزَلۡنَا عَلَيۡهَا ٱلۡمَآءَ ٱهۡتَزَّتۡ وَرَبَتۡ وَأَنۢبَتَتۡ مِن كُلِّ زَوۡجِۭ بَهِيجٖ
Ẹ̀yin ènìyàn, tí ẹ bá wà nínú iyèméjì nípa àjíǹde, dájúdájú Àwa ṣẹ̀dá yín láti inú erùpẹ̀, lẹ́yìn náà láti inú àtọ̀, lẹ́yìn náà láti inú ẹ̀jẹ̀ dídì, lẹ́yìn náà láti inú bááṣí ẹran tí ó pé ní ẹ̀dá àti èyí tí kò pé ní ẹ̀dá nítorí kí A lè ṣàlàyé (agbára Wa) fún yín. A sì ń mú ohun tí A bá fẹ́ dúró sínú àpò ìbímọ títí di gbèdéke àkókò kan. Lẹ́yìn náà, A óò mu yín jáde ní òpóǹló. Lẹ́yìn náà, (ẹ óò máa ṣẹ̀mí lọ) nítorí kí ẹ lè sánn̄gun dópin agbára yín. Ẹni tí wọ́n máa pa (ní kékeré) wà nínú yín. Ó sì wà nínú yín ẹni tí wọ́n máa dá (ìṣẹ̀mí) rẹ̀ sí di àsìkò ogbó kùjọ́kùjọ́ nítorí kí ó má lè mọ́ n̄ǹkan kan mọ́ lẹ́yìn tí ó ti mọ̀ ọ́n. Àti pé o máa rí ilẹ̀ ní gbígbẹ. Nígbà tí A bá sì sọ òjò kalẹ̀ lé e lórí, ó máa yíra padà. Ó máa gbèrú. Ó sì máa mú gbogbo oríṣiríṣi irúgbìn tó dára jáde.
Arabic explanations of the Qur’an:
ذَٰلِكَ بِأَنَّ ٱللَّهَ هُوَ ٱلۡحَقُّ وَأَنَّهُۥ يُحۡيِ ٱلۡمَوۡتَىٰ وَأَنَّهُۥ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٞ
Ìyẹn (rí bẹ́ẹ̀) nítorí pé dájúdájú Allāhu, Òun ni Òdodo. Dájúdájú Òun l’Ó ń sọ àwọn òkú di alààyè. Dájúdájú Òun sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَأَنَّ ٱلسَّاعَةَ ءَاتِيَةٞ لَّا رَيۡبَ فِيهَا وَأَنَّ ٱللَّهَ يَبۡعَثُ مَن فِي ٱلۡقُبُورِ
Àti pé dájúdájú Àkókò náà ń bọ̀. Kò sí iyèméjì nínú rẹ̀. Dájúdájú Allāhu yóò gbé àwọn tó ń bẹ nínú sàréè dìde.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَمِنَ ٱلنَّاسِ مَن يُجَٰدِلُ فِي ٱللَّهِ بِغَيۡرِ عِلۡمٖ وَلَا هُدٗى وَلَا كِتَٰبٖ مُّنِيرٖ
Ó ń bẹ nínú àwọn ènìyàn ẹni tó ń jiyàn nípa (ẹ̀sìn) Allāhu láì ní ìmọ̀ (al-Ƙur’ān) àti ìmọ̀nà (sunnah Ànábì) àti tírà (onímọ̀-ẹ̀sìn) tó ń tan ìmọ́lẹ̀ (sí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn).
Arabic explanations of the Qur’an:
ثَانِيَ عِطۡفِهِۦ لِيُضِلَّ عَن سَبِيلِ ٱللَّهِۖ لَهُۥ فِي ٱلدُّنۡيَا خِزۡيٞۖ وَنُذِيقُهُۥ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ عَذَابَ ٱلۡحَرِيقِ
Ó ń ṣègbéraga (sí òdodo, ó ń gbúnrí kúrò níbi òdodo) nítorí kí ó lè kó ìṣìnà bá àwọn ènìyàn lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu. Àbùkù ń bẹ fún un nílé ayé. Ní Ọjọ́ Àjíǹde, A sì máa fún un ní ìyà Iná jónijóni tọ́ wò.
Arabic explanations of the Qur’an:
ذَٰلِكَ بِمَا قَدَّمَتۡ يَدَاكَ وَأَنَّ ٱللَّهَ لَيۡسَ بِظَلَّٰمٖ لِّلۡعَبِيدِ
Ìyẹn (rí bẹ́ẹ̀) nítorí ohun tí ọwọ́ rẹ̀ tì síwájú. Dájúdájú Allāhu kò níí ṣàbòsí sí àwọn ẹrúsìn Rẹ̀.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَمِنَ ٱلنَّاسِ مَن يَعۡبُدُ ٱللَّهَ عَلَىٰ حَرۡفٖۖ فَإِنۡ أَصَابَهُۥ خَيۡرٌ ٱطۡمَأَنَّ بِهِۦۖ وَإِنۡ أَصَابَتۡهُ فِتۡنَةٌ ٱنقَلَبَ عَلَىٰ وَجۡهِهِۦ خَسِرَ ٱلدُّنۡيَا وَٱلۡأٓخِرَةَۚ ذَٰلِكَ هُوَ ٱلۡخُسۡرَانُ ٱلۡمُبِينُ
Ó tún wà nínú àwọn ènìyàn ẹni tó ń jọ́sìn fún Allāhu lórí ahọ́n. Tí rere bá ṣẹlẹ̀ sí i, ó máa fi ọkàn balẹ̀ (sínú ẹ̀sìn). Tí ìfòòró bá sì ṣẹlẹ̀ sí i, ó máa yíjú rẹ̀ padà kúrò nínú ẹ̀sìn. Ó ṣòfò láyé àti lọ́run. Ìyẹn sì ni òfò pọ́nńbélé.
Arabic explanations of the Qur’an:
يَدۡعُواْ مِن دُونِ ٱللَّهِ مَا لَا يَضُرُّهُۥ وَمَا لَا يَنفَعُهُۥۚ ذَٰلِكَ هُوَ ٱلضَّلَٰلُ ٱلۡبَعِيدُ
Ó ń pè lẹ́yìn Allāhu ohun tí kò lè kó ìnira bá a, tí kò sì lè ṣe é ní oore; ìyẹn ni ìṣìnà tó jìnnà (sí ìmọ̀nà).
Arabic explanations of the Qur’an:
يَدۡعُواْ لَمَن ضَرُّهُۥٓ أَقۡرَبُ مِن نَّفۡعِهِۦۚ لَبِئۡسَ ٱلۡمَوۡلَىٰ وَلَبِئۡسَ ٱلۡعَشِيرُ
Ó ń pe ohun tí ìnira rẹ̀ súnmọ́ ju àǹfààní rẹ̀ lọ. Dájúdájú (òrìṣà) burú ní aláfẹ̀yìntì, ó sì burú ní alásùn-únmọ́.
Arabic explanations of the Qur’an:
إِنَّ ٱللَّهَ يُدۡخِلُ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ جَنَّٰتٖ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُۚ إِنَّ ٱللَّهَ يَفۡعَلُ مَا يُرِيدُ
Dájúdájú Allāhu yóò mú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Dájúdájú Allāhu ń ṣe ohun tí Ó bá fẹ́.
Arabic explanations of the Qur’an:
مَن كَانَ يَظُنُّ أَن لَّن يَنصُرَهُ ٱللَّهُ فِي ٱلدُّنۡيَا وَٱلۡأٓخِرَةِ فَلۡيَمۡدُدۡ بِسَبَبٍ إِلَى ٱلسَّمَآءِ ثُمَّ لۡيَقۡطَعۡ فَلۡيَنظُرۡ هَلۡ يُذۡهِبَنَّ كَيۡدُهُۥ مَا يَغِيظُ
Ẹnikẹ́ni tí ó bá lérò pé Allāhu kò níí ran (Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -) lọ́wọ́ láyé àti lọ́run, kí ó na okùn sí sánmọ̀ (àjà ilé rẹ̀) lẹ́yìn náà kí ó gé e (ìyẹn ni pé, kí ó pokùn so). Kí ó wò ó nígbà náà bóyá ète rẹ̀ lè mú (àrànṣe) tó ń bínú sí kúrò (lọ́dọ̀ Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -).¹
1. Ìyẹn ni pé, abínú-ẹni kò lè pa kádàrá-ẹni dà. Ó kàn fẹ́ han ara rẹ̀ léémọ̀ ni.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَكَذَٰلِكَ أَنزَلۡنَٰهُ ءَايَٰتِۭ بَيِّنَٰتٖ وَأَنَّ ٱللَّهَ يَهۡدِي مَن يُرِيدُ
Báyẹn ni A ṣe sọ̀ ọ́ kalẹ̀ ní àwọn āyah tó yanjú. Dájúdájú Allāhu ń tọ́ ẹni tí Ó bá fẹ́ sí ọ̀nà.
Arabic explanations of the Qur’an:
إِنَّ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَٱلَّذِينَ هَادُواْ وَٱلصَّٰبِـِٔينَ وَٱلنَّصَٰرَىٰ وَٱلۡمَجُوسَ وَٱلَّذِينَ أَشۡرَكُوٓاْ إِنَّ ٱللَّهَ يَفۡصِلُ بَيۡنَهُمۡ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِۚ إِنَّ ٱللَّهَ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ شَهِيدٌ
Dájúdájú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo àti àwọn tó di yẹhudi àti àwọn sọ̄bi’ūn àti àwọn nasọ̄rọ̄ àti àwọn mọjūs àti àwọn tó ṣẹbọ, dájúdájú Allāhu yóò ṣèdájọ́ láààrin wọn ní Ọjọ́ Àjíǹde. Dájúdájú Allāhu ni Arínú-róde gbogbo n̄ǹkan.¹
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Baƙọrah; 2:62 àti ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah Yūnus; 10:90.
Arabic explanations of the Qur’an:
أَلَمۡ تَرَ أَنَّ ٱللَّهَ يَسۡجُدُۤ لَهُۥۤ مَن فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَن فِي ٱلۡأَرۡضِ وَٱلشَّمۡسُ وَٱلۡقَمَرُ وَٱلنُّجُومُ وَٱلۡجِبَالُ وَٱلشَّجَرُ وَٱلدَّوَآبُّ وَكَثِيرٞ مِّنَ ٱلنَّاسِۖ وَكَثِيرٌ حَقَّ عَلَيۡهِ ٱلۡعَذَابُۗ وَمَن يُهِنِ ٱللَّهُ فَمَا لَهُۥ مِن مُّكۡرِمٍۚ إِنَّ ٱللَّهَ يَفۡعَلُ مَا يَشَآءُ۩
Ṣé o ò wòye pé dájúdájú Allāhu ni àwọn tó ń bẹ nínú àwọn sánmọ̀ àti àwọn tó ń bẹ lórí ilẹ̀, àti òòrùn, òṣùpá, àwọn ìràwọ̀, àwọn àpáta, àwọn igi, àwọn n̄ǹkan ẹlẹ́mìí àti ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú àwọn ènìyàn ń forí kanlẹ̀ fún? Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ sì ni ìyà ti kò lé lórí. Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá fi àbùkù kàn, kò sí ẹnì kan tí ó máa ṣe àpọ́nlé rẹ̀. Dájúdájú Allāhu ń ṣe ohun tí Ó bá fẹ́.¹
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah ar-Ra‘d; 13:15.
Arabic explanations of the Qur’an:
۞ هَٰذَانِ خَصۡمَانِ ٱخۡتَصَمُواْ فِي رَبِّهِمۡۖ فَٱلَّذِينَ كَفَرُواْ قُطِّعَتۡ لَهُمۡ ثِيَابٞ مِّن نَّارٖ يُصَبُّ مِن فَوۡقِ رُءُوسِهِمُ ٱلۡحَمِيمُ
Àwọn oníjà méjì (kan) nìyí, wọ́n ń takò ara wọn nípa Olúwa wọn. Nítorí náà, àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, wọ́n máa gé aṣọ Iná fún wọn, wọ́n yó sì máa da omi tó gbóná gan-an lé wọn lórí láti òkè orí wọn.
Arabic explanations of the Qur’an:
يُصۡهَرُ بِهِۦ مَا فِي بُطُونِهِمۡ وَٱلۡجُلُودُ
Wọ́n máa fi yọ́ ohun tí ń bẹ nínú ikùn wọn àti awọ ara wọn.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَلَهُم مَّقَٰمِعُ مِنۡ حَدِيدٖ
Àwọn òdùrọ irin (ìyà) sì wà fún wọn pẹ̀lú.
Arabic explanations of the Qur’an:
كُلَّمَآ أَرَادُوٓاْ أَن يَخۡرُجُواْ مِنۡهَا مِنۡ غَمٍّ أُعِيدُواْ فِيهَا وَذُوقُواْ عَذَابَ ٱلۡحَرِيقِ
Ìgbàkígbà tí wọ́n bá fẹ́ jáde kúrò nínú rẹ̀ látara ìbànújẹ́, wọ́n á dá wọn padà sínú rẹ̀. (A óò sọ pé): “Ẹ tọ́ ìyà Iná jónijóni wò.”
Arabic explanations of the Qur’an:
إِنَّ ٱللَّهَ يُدۡخِلُ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ جَنَّٰتٖ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُ يُحَلَّوۡنَ فِيهَا مِنۡ أَسَاوِرَ مِن ذَهَبٖ وَلُؤۡلُؤٗاۖ وَلِبَاسُهُمۡ فِيهَا حَرِيرٞ
Dájúdájú Allāhu yóò fi àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra, tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. A óò ṣe wọ́n ní ọ̀ṣọ́ nínú rẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀gbà wúrà àti àlúùlúù. Aṣọ àlàárì sì ni aṣọ wọn nínú rẹ̀.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَهُدُوٓاْ إِلَى ٱلطَّيِّبِ مِنَ ٱلۡقَوۡلِ وَهُدُوٓاْ إِلَىٰ صِرَٰطِ ٱلۡحَمِيدِ
A fún wọn ní ìmọ̀nà síbi ohun tó dára nínú ọ̀rọ̀.¹ A sì tọ́ wọn sí ọ̀nà Ẹlẹ́yìn.
1. “Ohun tó dára nínú ọ̀rọ̀” dúró fún kalmọtuṣ-ṣahādah àti al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé. “Ojú ọ̀nà Ẹlẹ́yìn” dúró fún ẹ̀sìn ’Islām àti Ọgbà Ìdẹ̀ra èyí tí Allāhu Ọba Ẹlẹ́yìn gbékalẹ̀.
Arabic explanations of the Qur’an:
إِنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ وَيَصُدُّونَ عَن سَبِيلِ ٱللَّهِ وَٱلۡمَسۡجِدِ ٱلۡحَرَامِ ٱلَّذِي جَعَلۡنَٰهُ لِلنَّاسِ سَوَآءً ٱلۡعَٰكِفُ فِيهِ وَٱلۡبَادِۚ وَمَن يُرِدۡ فِيهِ بِإِلۡحَادِۭ بِظُلۡمٖ نُّذِقۡهُ مِنۡ عَذَابٍ أَلِيمٖ
Dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n ń ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu àti Mọ́sálásí Haram, èyí tí A ṣe ní dọ́gbadọ́gba fún àwọn ènìyàn, olùgbé-inú rẹ̀ àti àlejò (fún ìjọ́sìn ṣíṣe), ẹnikẹ́ni tí ó bá ní èrò láti ṣe ìyípadà kan níbẹ̀ pẹ̀lú àbòsí, A máa mú un tọ́ ìyà ẹlẹ́ta-eléro wò.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَإِذۡ بَوَّأۡنَا لِإِبۡرَٰهِيمَ مَكَانَ ٱلۡبَيۡتِ أَن لَّا تُشۡرِكۡ بِي شَيۡـٔٗا وَطَهِّرۡ بَيۡتِيَ لِلطَّآئِفِينَ وَٱلۡقَآئِمِينَ وَٱلرُّكَّعِ ٱلسُّجُودِ
(Ẹ rántí) nígbà tí A ṣàfi hàn àyè ilé náà fún (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm (A sì pa á láṣẹ) pé o ò gbọdọ̀ sọ kiní kan di akẹgbẹ́ fún Mi. Àti pé kí o ṣe ilé Mi ní mímọ́ fún àwọn olùyípo rẹ̀, olùkírun, olùdáwọ́tẹ-orúnkún àti olùforíkanlẹ̀.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَأَذِّن فِي ٱلنَّاسِ بِٱلۡحَجِّ يَأۡتُوكَ رِجَالٗا وَعَلَىٰ كُلِّ ضَامِرٖ يَأۡتِينَ مِن كُلِّ فَجٍّ عَمِيقٖ
Kí o sì pe ìpè fún àwọn ènìyàn fún iṣẹ́ Hajj. Wọn yóò wá bá ọ pẹ̀lú ìrìn ẹsẹ̀ àti lórí gbogbo n̄ǹkan ìgùn, wọn yóò máa wá láti àwọn ọ̀nà jíjìn
Arabic explanations of the Qur’an:
لِّيَشۡهَدُواْ مَنَٰفِعَ لَهُمۡ وَيَذۡكُرُواْ ٱسۡمَ ٱللَّهِ فِيٓ أَيَّامٖ مَّعۡلُومَٰتٍ عَلَىٰ مَا رَزَقَهُم مِّنۢ بَهِيمَةِ ٱلۡأَنۡعَٰمِۖ فَكُلُواْ مِنۡهَا وَأَطۡعِمُواْ ٱلۡبَآئِسَ ٱلۡفَقِيرَ
nítorí kí wọ́n lè rí àwọn àǹfààní tó ń bẹ fún wọn àti nítorí kí wọ́n lè ṣèrántí orúkọ Allāhu fún àwọn ọjọ́ tí wọ́n ti mọ̀¹ lórí n̄ǹkan tí Allāhu pa lésè fún wọn nínú àwọn ẹran-ọ̀sìn. Nítorí náà, ẹ jẹ nínú rẹ̀, kí ẹ sì fi bọ́ aláìlera, tálíkà.
1. Ìyẹn àwọn ọjọ́ mẹ́wàá àkọ́kọ́ nínú oṣù Thul-hijjah.
Arabic explanations of the Qur’an:
ثُمَّ لۡيَقۡضُواْ تَفَثَهُمۡ وَلۡيُوفُواْ نُذُورَهُمۡ وَلۡيَطَّوَّفُواْ بِٱلۡبَيۡتِ ٱلۡعَتِيقِ
Lẹ́yìn náà, kí wọ́n yanjú ìdọ̀tí ara wọn fún ìparí iṣẹ́ Hajj wọn, kí wọ́n mú àwọn ẹ̀jẹ́ wọn ṣẹ, kí wọ́n sì yípo Ilé Láéláé náà.
Arabic explanations of the Qur’an:
ذَٰلِكَۖ وَمَن يُعَظِّمۡ حُرُمَٰتِ ٱللَّهِ فَهُوَ خَيۡرٞ لَّهُۥ عِندَ رَبِّهِۦۗ وَأُحِلَّتۡ لَكُمُ ٱلۡأَنۡعَٰمُ إِلَّا مَا يُتۡلَىٰ عَلَيۡكُمۡۖ فَٱجۡتَنِبُواْ ٱلرِّجۡسَ مِنَ ٱلۡأَوۡثَٰنِ وَٱجۡتَنِبُواْ قَوۡلَ ٱلزُّورِ
Ìyẹn (nìyẹn). Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì pàtàkì àwọn n̄ǹkan tí Allāhu bu ọ̀wọ̀ fún, òhun ló lóore jùlọ fún un lọ́dọ̀ Olúwa rẹ̀. Wọ́n sì ṣe àwọn ẹran-ọ̀sìn ní ẹ̀tọ́ fún yín àyàfi àwọn tí wọ́n ń kà (ní èèwọ̀) fún yín. Nítorí náà, ẹ jìnnà sí ẹ̀gbin òrìṣà. Kí ẹ sì jìnnà sí ọ̀rọ̀ irọ́.
Arabic explanations of the Qur’an:
حُنَفَآءَ لِلَّهِ غَيۡرَ مُشۡرِكِينَ بِهِۦۚ وَمَن يُشۡرِكۡ بِٱللَّهِ فَكَأَنَّمَا خَرَّ مِنَ ٱلسَّمَآءِ فَتَخۡطَفُهُ ٱلطَّيۡرُ أَوۡ تَهۡوِي بِهِ ٱلرِّيحُ فِي مَكَانٖ سَحِيقٖ
(Ẹ jẹ́) olùdúró-déédé-nínú-ẹ̀sìn fún Allāhu, ẹ má ṣe jẹ́ ẹni tí yóò máa ṣẹbọ sí I. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣẹbọ sí Allāhu, ó dà bí ẹni tó jábọ́ láti ojú sánmọ̀, tí ẹyẹ sì gbé e lọ tàbí (tí) atẹ́gùn jù ú sínú àyè tó jìnnà.¹
1. Ìyẹn ni pé, rádaràda réderède ni ìkángun ẹni tó bá ṣẹbọ kú.
Arabic explanations of the Qur’an:
ذَٰلِكَۖ وَمَن يُعَظِّمۡ شَعَٰٓئِرَ ٱللَّهِ فَإِنَّهَا مِن تَقۡوَى ٱلۡقُلُوبِ
Ìyẹn (nìyẹn). Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì pàtàkì àwọn n̄ǹkan tí Allāhu fi ṣe àríṣàmì fún ẹ̀sìn ’Islām, dájúdájú ó wà lára níní ìbẹ̀rù Allāhu nínú ọkàn.
Arabic explanations of the Qur’an:
لَكُمۡ فِيهَا مَنَٰفِعُ إِلَىٰٓ أَجَلٖ مُّسَمّٗى ثُمَّ مَحِلُّهَآ إِلَى ٱلۡبَيۡتِ ٱلۡعَتِيقِ
Àwọn àǹfààní wà fún yín lára àwọn ẹran-ọ̀sìn títí di gbèdéke àkókò kan. Lẹ́yìn náà, Ilé Láéláé náà ni ibùpa àwọn ẹran náà.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَلِكُلِّ أُمَّةٖ جَعَلۡنَا مَنسَكٗا لِّيَذۡكُرُواْ ٱسۡمَ ٱللَّهِ عَلَىٰ مَا رَزَقَهُم مِّنۢ بَهِيمَةِ ٱلۡأَنۡعَٰمِۗ فَإِلَٰهُكُمۡ إِلَٰهٞ وَٰحِدٞ فَلَهُۥٓ أَسۡلِمُواْۗ وَبَشِّرِ ٱلۡمُخۡبِتِينَ
Ìkọ̀ọ̀kan ìjọ (mùsùlùmí tó ṣíwájú) ni A yan ẹran pípa fún nítorí kí wọ́n lè dárúkọ Allāhu lórí ohun tí Ó pèsè fún wọn nínú àwọn ẹran-ọ̀sìn. Nítorí náà, Ọlọ́hun yín tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo, Ọlọ́hun Ọ̀kan ṣoṣo ni. Òun ni kí ẹ jẹ́ mùsùlùmí fún. Kí o sì fún àwọn ọlọ́kàn ìrẹ̀lẹ̀, àwọn olùfọkànbalẹ̀ sọ́dọ̀ Allāhu ní ìró ìdùnnú.
Arabic explanations of the Qur’an:
ٱلَّذِينَ إِذَا ذُكِرَ ٱللَّهُ وَجِلَتۡ قُلُوبُهُمۡ وَٱلصَّٰبِرِينَ عَلَىٰ مَآ أَصَابَهُمۡ وَٱلۡمُقِيمِي ٱلصَّلَوٰةِ وَمِمَّا رَزَقۡنَٰهُمۡ يُنفِقُونَ
(Àwọn ni) àwọn tí ó jẹ́ pé tí A bá dárúkọ Allāhu (fún wọn), ọkàn wọn máa gbọ̀n rìrì. (Wọ́n jẹ́) onísùúrù lórí ohun tí ó bá ṣẹlẹ̀ sí wọn. (Wọ́n jẹ́) olùkírun. Wọ́n sì ń ná nínú ohun tí A pa lésè fùn wọn.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَٱلۡبُدۡنَ جَعَلۡنَٰهَا لَكُم مِّن شَعَٰٓئِرِ ٱللَّهِ لَكُمۡ فِيهَا خَيۡرٞۖ فَٱذۡكُرُواْ ٱسۡمَ ٱللَّهِ عَلَيۡهَا صَوَآفَّۖ فَإِذَا وَجَبَتۡ جُنُوبُهَا فَكُلُواْ مِنۡهَا وَأَطۡعِمُواْ ٱلۡقَانِعَ وَٱلۡمُعۡتَرَّۚ كَذَٰلِكَ سَخَّرۡنَٰهَا لَكُمۡ لَعَلَّكُمۡ تَشۡكُرُونَ
Àwọn ràkúnmí, A ṣe wọ́n nínú àwọn n̄ǹkan àríṣàmì fún ẹ̀sìn Allāhu fún yín. Oore wà lára wọn fún yín. Nítorí náà, ẹ dárúkọ Allāhu lé wọn lórí (kí ẹ sì gún wọn) ní ìdúró. Nígbà tí wọ́n bá fi ẹ̀gbẹ́ lélẹ̀, ẹ jẹ nínú rẹ̀. Ẹ fi bọ́ ẹni tó ní ìtẹ́lọ́rùn àti atọrọjẹ. Báyẹn ni A ṣe rọ̀ wọ́n fún yín nítorí kí ẹ lè dúpẹ́ (fún Un).
Arabic explanations of the Qur’an:
لَن يَنَالَ ٱللَّهَ لُحُومُهَا وَلَا دِمَآؤُهَا وَلَٰكِن يَنَالُهُ ٱلتَّقۡوَىٰ مِنكُمۡۚ كَذَٰلِكَ سَخَّرَهَا لَكُمۡ لِتُكَبِّرُواْ ٱللَّهَ عَلَىٰ مَا هَدَىٰكُمۡۗ وَبَشِّرِ ٱلۡمُحۡسِنِينَ
Ẹran (tí ẹ pa) àti ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ kò níí dé ọ̀dọ̀ Allāhu. Ṣùgbọ́n ìbẹ̀rù Allāhu láti ọ̀dọ̀ yín ló máa dé ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Báyẹn ni (Allāhu) ṣe rọ̀ wọ́n fún yín nítorí kí ẹ lè ṣe ìgbétóbi fún Allāhu nípa bí Ó ṣe fi ọ̀nà mọ̀ yín. Kí o sì fún àwọn olùṣe-rere ní ìró ìdùnnú.
Arabic explanations of the Qur’an:
۞ إِنَّ ٱللَّهَ يُدَٰفِعُ عَنِ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْۗ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يُحِبُّ كُلَّ خَوَّانٖ كَفُورٍ
Dájúdájú Allāhu ń ti aburú kúrò fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo. Dájúdájú Allāhu kò nífẹ̀ẹ́ gbogbo àwọn oníjàǹbá, aláìgbàgbọ́.
Arabic explanations of the Qur’an:
أُذِنَ لِلَّذِينَ يُقَٰتَلُونَ بِأَنَّهُمۡ ظُلِمُواْۚ وَإِنَّ ٱللَّهَ عَلَىٰ نَصۡرِهِمۡ لَقَدِيرٌ
A yọ̀ǹda (ogun ẹ̀sìn jíjà) fún àwọn (mùsùlùmí) tí (àwọn kèfèrí) ń gbógun tì nítorí pé (àwọn kèfèrí) ti ṣe àbòsí sí wọn. Dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí àrànṣe wọn.
Arabic explanations of the Qur’an:
ٱلَّذِينَ أُخۡرِجُواْ مِن دِيَٰرِهِم بِغَيۡرِ حَقٍّ إِلَّآ أَن يَقُولُواْ رَبُّنَا ٱللَّهُۗ وَلَوۡلَا دَفۡعُ ٱللَّهِ ٱلنَّاسَ بَعۡضَهُم بِبَعۡضٖ لَّهُدِّمَتۡ صَوَٰمِعُ وَبِيَعٞ وَصَلَوَٰتٞ وَمَسَٰجِدُ يُذۡكَرُ فِيهَا ٱسۡمُ ٱللَّهِ كَثِيرٗاۗ وَلَيَنصُرَنَّ ٱللَّهُ مَن يَنصُرُهُۥٓۚ إِنَّ ٱللَّهَ لَقَوِيٌّ عَزِيزٌ
(Àwọn ni) àwọn tí wọ́n lé jáde kúrò nínú ìlú wọn ní ọ̀nà àìtọ́ àfi (nítorí pé) wọ́n ń sọ pé: “Allāhu ni Olúwa wa.” Tí kò bá jẹ́ pé Allāhu ń dènà (aburú) fún àwọn ènìyàn ni, tí Ó ń fi apá kan wọn dènà (aburú) fún apá kan, wọn ìbá ti wó ilé ìsìn àwọn fadá, ṣọ́ọ̀ṣì, sínágọ́gù àti àwọn mọ́sálásí tí wọ́n ti ń dárúkọ Allāhu ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀.¹ Dájúdájú Allāhu yóò ṣe àrànṣe fún ẹnikẹ́ni tó ń ran (ẹ̀sìn ’Islām) Rẹ̀ lọ́wọ́. Dájúdájú Allāhu mà ni Alágbára, Olùborí.²
1. Ó ti rinlẹ̀ nínú sunnah Ànábì wa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - pé àwa mùsùlùmí kò gbọdọ̀ da ilé ìsìn àwọn yẹhudi àti nasọ̄rọ̄ wó lulẹ̀ ní àsìkò ogun ẹ̀sìn nítorí pé, àwọn ilé ìsìn náà rọrùn láti sọ di mọ́sálásí, ní pàtàkì jùlọ nígbà tí ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - bá padà sọ̀kalẹ̀ láti ojú sánmọ̀ ní òpin ayé.
2. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah at-Taobah; 9:13.
Arabic explanations of the Qur’an:
ٱلَّذِينَ إِن مَّكَّنَّٰهُمۡ فِي ٱلۡأَرۡضِ أَقَامُواْ ٱلصَّلَوٰةَ وَءَاتَوُاْ ٱلزَّكَوٰةَ وَأَمَرُواْ بِٱلۡمَعۡرُوفِ وَنَهَوۡاْ عَنِ ٱلۡمُنكَرِۗ وَلِلَّهِ عَٰقِبَةُ ٱلۡأُمُورِ
(Àwọn náà ni) àwọn tí ó jẹ́ pé tí A bá fún wọn ní ipò lórí ilẹ̀, wọn yóò kírun, wọn yóò yọ Zakāh, wọn yóò pàṣẹ ohun rere, wọn yó sì kọ ohun burúkú. Ti Allāhu sì ni ìkángun àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀dá.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَإِن يُكَذِّبُوكَ فَقَدۡ كَذَّبَتۡ قَبۡلَهُمۡ قَوۡمُ نُوحٖ وَعَادٞ وَثَمُودُ
Tí wọ́n bá pè ọ́ ní òpùrọ́, àwọn ìjọ Nūh, ìjọ ‘Ād àti ìjọ Thamūd kúkú ti pe àwọn Òjíṣẹ́ wọn ní òpùrọ́ ṣíwájú wọn.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَقَوۡمُ إِبۡرَٰهِيمَ وَقَوۡمُ لُوطٖ
Àti pé ìjọ ’Ibrọhīm àti ìjọ (Ànábì) Lūt,
Arabic explanations of the Qur’an:
وَأَصۡحَٰبُ مَدۡيَنَۖ وَكُذِّبَ مُوسَىٰۖ فَأَمۡلَيۡتُ لِلۡكَٰفِرِينَ ثُمَّ أَخَذۡتُهُمۡۖ فَكَيۡفَ كَانَ نَكِيرِ
àti àwọn ará ìlú Mọdyan (àwọn náà ṣe bẹ́ẹ̀). Wọ́n tún pe (Ànábì) Mūsā ní òpùrọ́. Mo sì lọ́ àwọn aláìgbàgbọ́ lára. Lẹ́yìn náà, Mo gbá wọn mú. Báwo sì ni bí Mo ṣe (fi ìyà) kọ (aburú fún wọn) ti rí!
Arabic explanations of the Qur’an:
فَكَأَيِّن مِّن قَرۡيَةٍ أَهۡلَكۡنَٰهَا وَهِيَ ظَالِمَةٞ فَهِيَ خَاوِيَةٌ عَلَىٰ عُرُوشِهَا وَبِئۡرٖ مُّعَطَّلَةٖ وَقَصۡرٖ مَّشِيدٍ
Nítorí náà, mélòó mélòó nínú ìlú tí A ti parẹ́ nígbà tí wọ́n jẹ́ alábòsí; àwọn ilé wọn dàwó lulẹ̀ pẹ̀lú òrùlé rẹ̀. (Mélòó mélòó nínú) kànǹga tí wọ́n ti patì (nípasẹ̀ ìparun) àti ilé pẹ̀tẹ́ẹ̀sì oníbíríkì (tó ti dahoro)!
Arabic explanations of the Qur’an:
أَفَلَمۡ يَسِيرُواْ فِي ٱلۡأَرۡضِ فَتَكُونَ لَهُمۡ قُلُوبٞ يَعۡقِلُونَ بِهَآ أَوۡ ءَاذَانٞ يَسۡمَعُونَ بِهَاۖ فَإِنَّهَا لَا تَعۡمَى ٱلۡأَبۡصَٰرُ وَلَٰكِن تَعۡمَى ٱلۡقُلُوبُ ٱلَّتِي فِي ٱلصُّدُورِ
Ṣé wọn kò rìn kiri lórí ilẹ̀ kí wọ́n sì ní àwọn ọkàn tí wọ́n máa fi ṣe làákàyè tàbí àwọn etí tí wọn máa fi gbọ́rọ̀? Dájúdájú àwọn ojú kò fọ́, ṣùgbọ́n àwọn ọkàn tó wà nínú igbá-àyà ló ń fọ́.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَيَسۡتَعۡجِلُونَكَ بِٱلۡعَذَابِ وَلَن يُخۡلِفَ ٱللَّهُ وَعۡدَهُۥۚ وَإِنَّ يَوۡمًا عِندَ رَبِّكَ كَأَلۡفِ سَنَةٖ مِّمَّا تَعُدُّونَ
Wọ́n sì ń kán ọ lójú fún ìyà náà. Allāhu kò sì níí yapa àdéhùn Rẹ̀. Dájúdájú ọjọ́ kan lọ́dọ̀ Olúwa rẹ dà bí ẹgbẹ̀rún ọdún nínú ohun tí ẹ̀ ń kà (ní òǹkà).¹
1. Nínú āyah yìí, sūrah al-Hajj; 22:47 àti sūrah as-Sajdah; 32:5, ọjọ́ ẹyọ kan lọ́dọ̀ Allāhu - Ọba tó ga jùlọ - ni ẹgbẹ̀rún ọdún tiwa, àmọ́ nínú sūrah al-Mọ‘ārij; 70:4, ọjọ́ ẹyọ kan lọ́dọ̀ Allāhu ni ọ̀kẹ́ méjì ààbọ̀ (ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta) tiwa (50,000).
Àwọn āyah mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyẹn fẹ́ takora wọn lójú aláìnímọ̀ nípa ìṣe Allāhu - Ọba tó ga jùlọ -, àmọ́ kò sí ìtakora láààrin wọn ní ọ̀dọ̀ àwọn onímọ̀-ẹ̀sìn ’Islām. Ní ti āyah 47 nínú sūrah al-Hajj, Allāhu - Ọba tó ga jùlọ - ń sọ̀rọ̀ nípa ìdí tí ìyà kò fi tètè sọ̀kalẹ̀ lé àwọn aláìgbàgbọ́ lórí pé, tí Òun bá sọ fún wọn pé àárọ̀ ọ̀la ni ọjọ́ ìyà wọn (bí àpẹ̀ẹrẹ), ìyẹn dúró fún ẹgbẹ̀rún ọdún kan. Ní ti āyah 5 nínú sūrah as-Sajdah, Allāhu - Ọba tó ga jùlọ - ń sọ̀rọ̀ nípa ìsọ̀kalẹ̀ àti ìgùnkè àwọn mọlāika láààrin òkè sánmọ̀ keje àti ilẹ̀ keje ní ojoojúmọ pé, òǹkà ọdún tí ẹ̀dá mìíràn máa lò fún rírin ìrìn-àjò náà ní àlọbọ̀ máa jẹ́ ẹgbẹ̀rún ọdún tiwa (1,000).
Àmọ́ ní ti āyah 4 nínú sūrah al-Mọ‘ārij, Allāhu fún ìrìn-àjò yìí kan náà ní òdíwọ̀n ọ̀kẹ́ méjì ààbọ̀ ọdún, dípò ẹgbẹ̀rún ọdún. Kíyè sí i, nínú āyah ọlọ́jọ́ kan tó dọ́gba sí ẹgbẹ̀rún ọdún, Allāhu fi gbólóhùn yìí parí rẹ̀ “nínú ohun tí ẹ̀ ń kà ní òǹkà” ìyẹn nílé ayé. Àmọ́ Allāhu kò fi gbólóhùn yẹn parí rẹ̀ nínú āyah ọlọ́jọ́ kan tó dọ́gba sí ọ̀kẹ́ méjì ààbọ̀ ọdún. Ìtúmọ̀ èyí ni pé, ọjọ́ ọlọ́kẹ̀ẹ́ méjì-ààbọ̀ ọdún yẹn = = máa dúró fún ọjọ́ kan lọ́jọ́ Àjíǹde lára àwọn aláìgbàgbọ́ nítorí kí wọ́n lè kan ìnira tí ẹ̀mí wọn kò níí gbé.
Àwọn onímímọ̀ wulẹ̀ tún sọ pé, yálà ọjọ́ kan ẹlẹ́gbẹ̀rún ọdún tàbí ọjọ́ ọlọ́kẹ̀ẹ́ méjì ààbọ̀ ọdún, ìkíní kejì ló máa ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ Àjíǹde. Wọ́n ní, wàhálà ọjọ́ kan lọ́jọ́ Àjíǹde máa dọ́gba sí ẹgbẹ̀rún ọdún lára onígbàgbọ́ òdodo nítorí kí ìnira ọjọ́ náà máa baà pọ̀ jù lára wọn, nígbà tí wàhálà ọjọ́ kan lọ́jọ́ Àjíǹde máa dọ́gba sí ọ̀kẹ́ méjì-ààbọ̀ ọdún lára àwọn aláìgbàgbọ́ nítorí kí ìnira ọjọ́ náà lè tán wọn ní sùúrù. Èyí sì wà ní ìbámu sí sūrah al-Mudaththir; 74: 8-10.
Síwájú sí i, bí ọjọ́ kan ní ọ̀dọ̀ Allāhu ṣe lè jẹ́ ẹgbẹ̀rún ọdún kan, ó tún lè jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ààbọ̀ ọdún, yálà nílé yìí tàbí lọ́jọ́ Àjíǹde, tí Allāhu bá fẹ́ bẹ́ẹ̀.
Ní àkọ́kọ́ ná, “Allāhu l’Ó ń díwọ̀n òru àti ọ̀sán” (sūrah al-Muzammil; 73:20). Bákan náà, nínú ẹ̀gbàwá Nawwās bun Sam‘ān - kí Allāhu yọ́nú sí i - lórí ọ̀rọ̀ òǹkà ọjọ́ tí Mọsīh Dajjāl máa lò nílé ayé láti fi da ilé ayé rú pátápátá ṣíwájú kí Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam, ẹni-àńretí - kí ọlà Allāhu máa bá a - tó wá fi idà pa á. Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - sọ pé. “Ó máa lo ogójì ọjọ́. Ọjọ́ kìíní bí ọdún kan. Ọjọ́ kejì bí oṣù kan. Ọjọ́ kẹta bí ọ̀ṣẹ̀ kan. Ọjọ́ yòókù bí ọjọ́ yín.” (Muslim) Nítorí náà, ọjọ́ kàn lè dọ́gba sí ẹgbẹ̀rún ọdún tiwa (1000), tí Allāhu bá fẹ́. Ọjọ́ kan sì lè dọ́gba sí ọ̀kẹ́ méjì ààbọ̀ ọdún tiwa (50,000), tí Allāhu bá fẹ́. Aṣèyí-ówùú ni Allāhu.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَكَأَيِّن مِّن قَرۡيَةٍ أَمۡلَيۡتُ لَهَا وَهِيَ ظَالِمَةٞ ثُمَّ أَخَذۡتُهَا وَإِلَيَّ ٱلۡمَصِيرُ
Mélòó mélòó nínú ìlú tí Mo lọ́ lára, tí wọ́n jẹ́ alábòsí. Lẹ́yìn náà, Mo gbá wọn mú. Ọ̀dọ̀ Mi sì ni àbọ̀ ẹ̀dá.
Arabic explanations of the Qur’an:
قُلۡ يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ إِنَّمَآ أَنَا۠ لَكُمۡ نَذِيرٞ مُّبِينٞ
Sọ pé: “Ẹ̀yin ènìyàn, èmi mà ni olùkìlọ̀ pọ́nńbélé fún yín.”
Arabic explanations of the Qur’an:
فَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ لَهُم مَّغۡفِرَةٞ وَرِزۡقٞ كَرِيمٞ
Nítorí náà, àwọn tó bá gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere, àforíjìn àti arísìkí alápọ̀n-ọ́nlé ń bẹ fún wọn.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَٱلَّذِينَ سَعَوۡاْ فِيٓ ءَايَٰتِنَا مُعَٰجِزِينَ أُوْلَٰٓئِكَ أَصۡحَٰبُ ٱلۡجَحِيمِ
Àwọn tó ṣe iṣẹ́ (burúkú) nípa àwọn āyah Wa, tí wọ́n ń dá àwọn ènìyàn ní agara (láti tẹ̀lé àwọn āyah Wa, tí wọ́n sì lérò pé àwọn máa mórí bọ́ lọ́dọ̀ Allāhu); àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú iná Jẹhīm.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَمَآ أَرۡسَلۡنَا مِن قَبۡلِكَ مِن رَّسُولٖ وَلَا نَبِيٍّ إِلَّآ إِذَا تَمَنَّىٰٓ أَلۡقَى ٱلشَّيۡطَٰنُ فِيٓ أُمۡنِيَّتِهِۦ فَيَنسَخُ ٱللَّهُ مَا يُلۡقِي ٱلشَّيۡطَٰنُ ثُمَّ يُحۡكِمُ ٱللَّهُ ءَايَٰتِهِۦۗ وَٱللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٞ
A kò rán Òjíṣẹ́ kan tàbí Ànábì kan níṣẹ́ ṣíwájú rẹ àfi kí ó jẹ́ pé nígbà tí ó bá sọ̀rọ̀, Èṣù máa ju (n̄ǹkan) sínú ọ̀rọ̀ rẹ̀. Nítorí náà, Allāhu yóò pa ohun tí Èṣù ń jù sínú rẹ̀ rẹ́. Lẹ́yìn náà, Ó máa fi òdodo àwọn āyah Rẹ̀ rinlẹ̀. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n. ¹
1. Āyah 52 yìí jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn āyah pàtàkì tí àwọn nasọ̄rọ̄ máa ń tọ́ka sí láti fi tako al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé àti Ànábì wa Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -. Àwọn nasọ̄rọ̄ máa ń sọ pé, “Kókó tó wà nínú āyah náà ni pé, Èṣù máa ń gbé ọ̀rọ̀ sẹ́nu Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - lásìkò tí ó bá fẹ́ ka al-Ƙur’ān fún àwọn ènìyàn láti fi jíṣẹ́ fún wọn. Wọ́n fi kún un pé Èṣù ló máa ń gba ẹnu Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - sọ̀rọ̀ nígbàkígbà tí ó bá ń jíṣẹ́ Ọlọ́hun.”
Nítorí kí ọ̀rọ̀ ẹnu àwọn nasọ̄rọ̄ wọ̀nyí lè dùn létí àwọn ènìyàn, wọ́n túlé kan ẹ̀gbàwá ọ̀rọ̀ kan tí wọ́n ṣe àfitì rẹ̀ sọ́dọ̀ ọmọ ‘Abbās - kí Allāhu yọ́nú sí i - pé, “Ní ọjọ́ kan Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ń ké sūrah an-Najm, ìyẹn sūrah 53, fún àwọn ará ìlú Mọkkah. Nígbà tí ó ké sūrah náà dé orí āyah 19 sí āyah 20, ní àyè tí Allāhu - tó ga jùlọ - ti sọ pé “Ẹ sọ fún mi nípa òrìṣà Lāt àti òrìṣà ‘Uzzā, àti òmíràn, Mọnāh, òrìṣà kẹta”, ó sọ pé “Ìwọ̀nyẹn ni àwọn ẹyẹ àgbà. Àti pé ìrètí wà nínú ìṣìpẹ̀ tí wọ́n máa ṣe.” Nígbà tí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - sọ bẹ́ẹ̀ tán, gbogbo àwọn mùsùlùmí àti àwọn ọ̀ṣẹbọ sì dìjọ forí kanlẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀…”
Àwọn nasọ̄rọ̄ wá sọ pé, “àwọn òrìṣà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyẹn tí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - pè ní ẹyẹ àgbà ni ọ̀rọ̀ náà tí Èṣù jù sí ẹnu Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - lásìkò tó ń ké al-Ƙur’ān náà. Ìtàn náà sì wà nínú àkọsílẹ̀ àwọn tírà tafsīr àwọn mùsùlùmí.” Ọ̀rọ̀ wọn nìwọ̀nyẹn lórí ìtúmọ̀ tí wọ́n fún āyah 52 àti ẹ̀rí wọn lórí rẹ̀ parí.
Èsì ọ̀rọ̀: Ọ̀rọ̀ ńlá ni àwọn nasọ̄rọ̄ sọ yìí. Ọ̀rọ̀ náà kì í ṣe òdodo rárá. Àfiwé ìtúkútùú àwọn nasọ̄rọ̄ wọ̀nyí dà bí ọ̀rọ̀ arákùnrin wọn kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ “Lákin”. Lákin yìí ló sọ pé òun náà nímọ̀ ìtúmọ̀ al-Ƙur’ān ju àwa mùsùlùmí lọ. Ó sì sọ pé kódà Allāhu dárúkọ òun náà nínú al-Ƙur’ān. A sì bi í léèrè pé ibo ni orúkọ rẹ̀ wà nínú al-Ƙur’ān. Ó sì fèsì pé orúkọ òun ni gbogbo ibi tí al-Ƙur’ān bá ti sọ pé “لَكِنْ” (lākin)!?
Ẹ̀yin onímọ̀ èdè, ṣé ìtúmọ̀ “لَكِنْ” (lākin) nínú èdè Lárúbáwá sì ni ìtúmọ̀ “Lákin” nínú èdè Yorùbá? “Ṣùgbọ́n / àmọ́” ni ìtúmọ̀ “لَكِنْ” (lākin) nínú èdè Lárúbáwá. “Ẹni tí ó ní akin-ọkàn” sì ni ìtúmọ̀ “Lákin” nínú èdè Yorùbá. Ṣé ẹ rí i báyìí pé “ṣùgbọ́n” ti wọnú ọ̀rọ̀ àwọn nasọ̄rọ̄. Ìyẹn ni pé, wọn kò ní ìmọ̀ olóóókan nípa al-Ƙur’ān àti hadīth, ṣùgbọ́n wọ́n mọ irọ́ funfun báláú pa mọ́ ẹ̀sìn ’Islām. Ìṣe wọn yìí sì ṣe wẹ́kú ọ̀rọ̀ tí Allāhu - tó ga jùlọ - sọ nípa wọn nínú sūrah al-Baƙọrah; 2: 78.
Wàyí tí a ti mọ irú ènìyàn tí àwọn nasọ̄rọ̄ í ṣe, ẹ jẹ́ kí á ṣàlàyé āyah tí wọ́n ń túmọ̀ sódì náà.
Ní àkọ́kọ́ ná, ẹni tí Èṣù bá ń gbẹnu rẹ̀ sọ̀rọ̀, bí kò jẹ́ wèrè, ó máa jẹ́ eléṣù tí ó bá Èṣù dòwò pọ̀. Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - kì í ṣe wèrè. Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - kò sì lọ́dẹ orí. Bẹ́ẹ̀ sì ni pé kò bọ̀rìṣà rí áḿbọ̀sìbọ́sí pé Èṣù yóò máa gùn ún. Allāhu - tó ga jùlọ - sì ti fi rinlẹ̀ nínú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ āyah al-Ƙur’ān pé Èṣù àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kò lágbára lórí àwọn onígbàgbọ́ òdodo. Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - sì ni ọ̀gá àwọn onígbàgbọ́ òdodo. Díẹ̀ nínú àwọn àyè tí Allāhu - tó ga jùlọ - ti sọ èyí ni sūrah al-Hijr; 15:42 àti sūrah an-Nahl; 16:99 -100. Bákan náà, Allāhu - tó ga jùlọ - tún fi rinlẹ̀ pé ààbò mímọ́ wà fún ìsọ̀kalẹ̀ al-Ƙur’ān, kíké rẹ̀ àti ṣíṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ láti ojú ayé Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - títí di òpin ayé, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú sūrah al-Hijr; 15:9 àti sūrah Fussilat; 41:41 - 42. Nítorí náà, Èsù kan kan kò lè rọ́nà ti ọ̀rọ̀ tirẹ̀ bọ inú al-Ƙur’ān.
Bákan náà, ọ̀rọ̀kọ́rọ̀ tàbí ọ̀rọ̀ eléṣù kò tẹnu Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - jáde rí nínú ìgbésí ayé rẹ̀ ní ìbámu sí sūrah an-Najm; 53: 3 - 4.
Síwájú sí i, Èṣù kan kan kò lè rí àwòrán tàbí ohùn Ànábì wa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - yá lò yálà lójú oorun tàbí lójú ayé nítorí hadīth Sọhīh, ní ibi tí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ti sọ pé “Èṣù kò lè gbé àwòrán mi wọ̀.”
Kódà “ƙọrīn” èṣù àlùjọ̀nnú alábàárìn tí Allāhu fi sára ènìyàn kọ̀ọ̀kan, láì yọ Ànábì tàbí Òjíṣẹ́ kan sílẹ̀, tí ó máa ń pa ènìyàn láṣẹ aburú nínú ẹ̀mí, òun gan-an kò lè pa Ànábì wa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - láṣẹ aburú nítorí pé Allāhu ṣe àrànṣe fún Ànábì wa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - lórí rẹ̀. Àlùjọ̀nnú náà sì gba ’Islām, kò sì pa Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - láṣẹ aburú.
Nítorí náà, “ma‘sūm” ẹni tí ààbò mímọ́ wà fún ni Ànábì wa Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -. Pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí tààrà wọ̀nyẹn, mùsùlùmí onígbàgbọ́ òdodo kò níí pẹ̀lú ọ̀bọ jẹko láti sọ pé èṣù kan gba ẹnu Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - sọ̀rọ̀ láti sọ pé “Ìwọ̀nyẹn ni àwọn ẹyẹ àgbà. Àti pé ìrètí wà nínú ìṣìpẹ̀ tí wọ́n máa ṣe.”
Ní ti àwọn hadīth tí wọ́n fi gbe ọ̀rọ̀ burúkú náà lẹ́sẹ̀, gbogbo àwọn hadīth náà ló lẹ, tí kò ṣe é fi ṣe ẹ̀rí àfi hadīth ẹyọ kan péré. Ìyẹn ni pé, gbogbo hadīth tó ń sọ nípa pé Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - sọ pé “Ìwọ̀nyẹn ni àwọn ẹyẹ àgbà. Àti pé ìrètí wà nínú ìṣìpẹ̀ tí wọ́n máa ṣe.” jẹ́ hadīth tó lẹ pátápátá. Àmọ́ èyí tí ó fẹsẹ̀ rinlẹ̀ nínú wọn kò tayọ èyí tí ó wà nínú sọhīhu-l-Bukọ̄riy, lábẹ́ àkọlé ìforíkanlẹ̀ àwọn mùsùlùmí pẹ̀lú àwọn ọ̀ṣẹbọ. Láti ọ̀dọ̀ Ọmọ ‘Abbās - kí Allāhu yọ́nú sí àwọn méjèèjì -, ó sọ pé: “Dájúdájú Ànábì forí kanlẹ̀ níbi āyah ìforíkanlẹ̀ nínú sūrah an-Najm. Àwọn mùsùlùmí, àwọn ọ̀ṣẹbọ, àlùjọ̀nnú àti ènìyàn sì forí kanlẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀.” Hadīth nìyí tó fẹsẹ̀ rinlẹ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Kò sì sí ọ̀rọ̀ “àwọn ẹyẹ àgbà” kan kan nínú rẹ̀.
Ohun tí ènìyàn yó kàn fẹ́ mọ̀ nípa rẹ̀ ni pé, kí ló mú àwọn ọ̀ṣẹbọ forí kanlẹ̀ láì tí ì gba ’Islām. Ìdí tí àwọn ọ̀ṣẹbọ wọ̀nyẹn fi forí kanlẹ̀ ni pé, wọ́n gbọ́ orúkọ òrìṣà wọn mẹ́ta kan nínú āyah al-Ƙur’ān, ìyẹn nínú sūrah an-Najm; 53:19-20, wọ́n bá lérò pé Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - náà ń pàtàkì àwọn òrìṣà náà. Inú wọn sì dùn. Wọ́n bá forí kanlẹ̀. Ìforíkanlẹ̀ wọn kò sì wulẹ̀ wúlò fún n̄ǹkan kan. Àmọ́ níkété tí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ké sūrah náà síwájú wọ āyah 26. Ara wọn balẹ̀. Wọ́n sì rí i dájú pé, ọ̀tọ̀ ni ohun tí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - sọ. Ọ̀tọ̀ ni ohun tí àwọn èṣù inú ẹ̀mí wọn gbé jù sínú ọkàn wọn. Àwọn fúnra wọn ni wọ́n sọ ohun tí àwọn èṣù inú ẹ̀mí wọn gbé jù sínú ẹ̀mí wọn.
Àmọ́ nítorí kí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - máa baà banújẹ́ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni Allāhu - tó ga jùlọ - fi sọ ọ́ di ohun mímọ̀ fún un nínú āyah 52 (ìyẹn, nínú sūrah al-Hajj) pé, kò sí Ànábì tàbí Òjíṣẹ́ ti irú rẹ̀ kò sẹlẹ̀ sí rí ní ọ̀nà kan tàbí òmíràn. Nítorí náà, Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - fẹ́ pe làákàyè wọn wálé pé, Allāhu kò lọ́wọ́ nínú àwọn orúkọ òrìṣà náà. Àti pé, kò sí ìkápá ìpẹ̀ ṣíṣe fún wọn lọ́dọ̀ Allāhu - tó ga jùlọ -. Āyah 23 sí 26 nínú sūrah an-Najm sì ń jẹ́rìí sí èyí.
Síwájú sí i, mímú tí àwọn tírà tafsīr mú ìṣẹ̀lẹ̀ náà wà láì sọ àwílé jẹ́ àsọọ̀yán àti àsọọ̀tó. Àmọ́ sá, ẹ̀gbàwá Bukọ̄riy ti yanjú ọ̀rọ̀ náà. Kò sì sí ọ̀rọ̀ “àwọn ẹyẹ àgbà mẹ́ta” kan kan nínú rẹ̀. Nítorí náà, hadīth kò báà lé ní igba lórí ọ̀rọ̀ kan náà, tí ó bá ti tako āyah kan nínú al-Ƙur’ān tàbí tí ó bá tako hadīth Bukọ̄riy tàbí hadīth Muslim, irú hadīth náà kò wúlò nínú ẹ̀sìn wa láti fi ṣe ẹ̀rí ọ̀rọ̀. -W-Allāhu ’a‘lam. -
Arabic explanations of the Qur’an:
لِّيَجۡعَلَ مَا يُلۡقِي ٱلشَّيۡطَٰنُ فِتۡنَةٗ لِّلَّذِينَ فِي قُلُوبِهِم مَّرَضٞ وَٱلۡقَاسِيَةِ قُلُوبُهُمۡۗ وَإِنَّ ٱلظَّٰلِمِينَ لَفِي شِقَاقِۭ بَعِيدٖ
(Èyí ń ṣẹlẹ̀) nítorí kí (Allāhu) lè fi ohun tí Èṣù ń jù (sínú rẹ̀) ṣe àdánwò fún àwọn tí àìsàn ń bẹ nínú ọkàn wọn àti àwọn tí ọkàn wọn le. Dájúdájú àwọn alábòsí sì wà nínú ìyapa tó jìnnà (sí òdodo).
Arabic explanations of the Qur’an:
وَلِيَعۡلَمَ ٱلَّذِينَ أُوتُواْ ٱلۡعِلۡمَ أَنَّهُ ٱلۡحَقُّ مِن رَّبِّكَ فَيُؤۡمِنُواْ بِهِۦ فَتُخۡبِتَ لَهُۥ قُلُوبُهُمۡۗ وَإِنَّ ٱللَّهَ لَهَادِ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ إِلَىٰ صِرَٰطٖ مُّسۡتَقِيمٖ
(Èyí ń ṣẹlẹ̀) nítorí kí àwọn tí A fún ní ìmọ̀ lè mọ̀ pé dájúdájú al-Ƙur’ān jẹ́ òdodo láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Nítorí náà, wọn yó sì gbàgbọ́ nínú rẹ̀, ọkàn wọn yó sì balẹ̀ sí i. Dájúdájú Allāhu l’Ó ń fi ẹsẹ̀ àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo rinlẹ̀ sójú ọ̀nà tààrà (’Islām).
Arabic explanations of the Qur’an:
وَلَا يَزَالُ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ فِي مِرۡيَةٖ مِّنۡهُ حَتَّىٰ تَأۡتِيَهُمُ ٱلسَّاعَةُ بَغۡتَةً أَوۡ يَأۡتِيَهُمۡ عَذَابُ يَوۡمٍ عَقِيمٍ
Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ kò sì níí yé wà nínú iyèméjì nípa rẹ̀ títí Àkókò náà yóò fi dé bá wọn ní òjijì tàbí (títí) ìyà ọjọ́ ìparun yóò fi dé bá wọn.
Arabic explanations of the Qur’an:
ٱلۡمُلۡكُ يَوۡمَئِذٖ لِّلَّهِ يَحۡكُمُ بَيۡنَهُمۡۚ فَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ فِي جَنَّٰتِ ٱلنَّعِيمِ
Gbogbo ìjọba ọjọ́ yẹn ń jẹ́ ti Allāhu tí Ó máa ṣèdájọ́ láààrin wọn. Nítorí náà, àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, (wọn yóò wà) nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَٱلَّذِينَ كَفَرُواْ وَكَذَّبُواْ بِـَٔايَٰتِنَا فَأُوْلَٰٓئِكَ لَهُمۡ عَذَابٞ مُّهِينٞ
Àwọn tó sì ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n tún pe àwọn āyah Wa ní irọ́; àwọn wọ̀nyẹn ni ìyà tí í yẹpẹrẹ ẹ̀dá sì wà fún.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَٱلَّذِينَ هَاجَرُواْ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ ثُمَّ قُتِلُوٓاْ أَوۡ مَاتُواْ لَيَرۡزُقَنَّهُمُ ٱللَّهُ رِزۡقًا حَسَنٗاۚ وَإِنَّ ٱللَّهَ لَهُوَ خَيۡرُ ٱلرَّٰزِقِينَ
Àwọn tí wọ́n gbé ìlú wọn jù sílẹ̀ nítorí ẹ̀sìn Allāhu, lẹ́yìn náà, tí wọ́n pa wọ́n tàbí tí wọ́n kú; dájúdájú Allāhu yóò pèsè fún wọn ní ìpèsè tó dára. Dájúdájú Allāhu, Ó mà l’óore jùlọ nínú àwọn olùpèsè.¹
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah as-Sọ̄ffāt; 37:125.
Arabic explanations of the Qur’an:
لَيُدۡخِلَنَّهُم مُّدۡخَلٗا يَرۡضَوۡنَهُۥۚ وَإِنَّ ٱللَّهَ لَعَلِيمٌ حَلِيمٞ
Dájúdájú (Allāhu) yóò fi wọ́n sínú àyè kan tí wọn yóò yọ́nú sí. Dájúdájú Allāhu mà ni Onímọ̀, Aláfaradà.
Arabic explanations of the Qur’an:
۞ ذَٰلِكَۖ وَمَنۡ عَاقَبَ بِمِثۡلِ مَا عُوقِبَ بِهِۦ ثُمَّ بُغِيَ عَلَيۡهِ لَيَنصُرَنَّهُ ٱللَّهُۚ إِنَّ ٱللَّهَ لَعَفُوٌّ غَفُورٞ
Ìyẹn (nìyẹn). Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbẹ̀san irú ìyà tí wọ́n fi jẹ ẹ́, lẹ́yìn náà tí wọ́n bá tún ṣàbòsí sí i, dájúdájú Allāhu yóò ṣàrànṣe fún un. Dájúdájú Allāhu mà ni Alámòjúúkúrò, Aláforíjìn.
Arabic explanations of the Qur’an:
ذَٰلِكَ بِأَنَّ ٱللَّهَ يُولِجُ ٱلَّيۡلَ فِي ٱلنَّهَارِ وَيُولِجُ ٱلنَّهَارَ فِي ٱلَّيۡلِ وَأَنَّ ٱللَّهَ سَمِيعُۢ بَصِيرٞ
Ìyẹn nítorí pé dájúdájú Allāhu ń fi òru bọ inú ọ̀sán, Ó sì ń fi ọ̀sán bọ inú òru. Allāhu sì ni Olùgbọ́, Olùríran.
Arabic explanations of the Qur’an:
ذَٰلِكَ بِأَنَّ ٱللَّهَ هُوَ ٱلۡحَقُّ وَأَنَّ مَا يَدۡعُونَ مِن دُونِهِۦ هُوَ ٱلۡبَٰطِلُ وَأَنَّ ٱللَّهَ هُوَ ٱلۡعَلِيُّ ٱلۡكَبِيرُ
Ìyẹn nítorí pé dájúdájú Allāhu, Òun ni Òdodo. Àti pé dájúdájú ohun tí wọ́n ń pè lẹ́yìn Rẹ̀ ni irọ́. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Ó ga, Ó tóbi.
Arabic explanations of the Qur’an:
أَلَمۡ تَرَ أَنَّ ٱللَّهَ أَنزَلَ مِنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءٗ فَتُصۡبِحُ ٱلۡأَرۡضُ مُخۡضَرَّةًۚ إِنَّ ٱللَّهَ لَطِيفٌ خَبِيرٞ
Ṣé o ò rí i pé dájúdájú Allāhu ń sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀, ilẹ̀ sì máa lọ́ràá wá? Dájúdájú Allāhu ni Aláàánú, Alámọ̀tán.
Arabic explanations of the Qur’an:
لَّهُۥ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِۚ وَإِنَّ ٱللَّهَ لَهُوَ ٱلۡغَنِيُّ ٱلۡحَمِيدُ
TiRẹ̀ ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀. Dájúdájú Allāhu, Òun mà ni Ọlọ́rọ̀, Ẹlẹ́yìn.
Arabic explanations of the Qur’an:
أَلَمۡ تَرَ أَنَّ ٱللَّهَ سَخَّرَ لَكُم مَّا فِي ٱلۡأَرۡضِ وَٱلۡفُلۡكَ تَجۡرِي فِي ٱلۡبَحۡرِ بِأَمۡرِهِۦ وَيُمۡسِكُ ٱلسَّمَآءَ أَن تَقَعَ عَلَى ٱلۡأَرۡضِ إِلَّا بِإِذۡنِهِۦٓۚ إِنَّ ٱللَّهَ بِٱلنَّاسِ لَرَءُوفٞ رَّحِيمٞ
Ṣé o ò rí i pé dájúdájú Allāhu rọ ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀ fún yín, àti ọkọ̀ ojú-omi tó ń rìn nínú agbami odò pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀, Ó ń mú sánmọ̀ dání tí kò fi jábọ́ àyàfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Rẹ̀? Dájúdájú Allāhu mà ni Aláàánú, Oníkẹ̀ẹ́ fún àwọn ènìyàn.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَهُوَ ٱلَّذِيٓ أَحۡيَاكُمۡ ثُمَّ يُمِيتُكُمۡ ثُمَّ يُحۡيِيكُمۡۗ إِنَّ ٱلۡإِنسَٰنَ لَكَفُورٞ
Òun sì ni Ẹni tó ṣe yín ni alààyè, lẹ́yìn náà Ó ń sọ yín di òkú, lẹ́yìn náà Ó máa sọ yín di alààyè. Dájúdájú ènìyàn mà ni aláìmoore.
Arabic explanations of the Qur’an:
لِّكُلِّ أُمَّةٖ جَعَلۡنَا مَنسَكًا هُمۡ نَاسِكُوهُۖ فَلَا يُنَٰزِعُنَّكَ فِي ٱلۡأَمۡرِۚ وَٱدۡعُ إِلَىٰ رَبِّكَۖ إِنَّكَ لَعَلَىٰ هُدٗى مُّسۡتَقِيمٖ
Ìjọ kọ̀ọ̀kan l’A fún ní ìlànà tí wọ́n máa lò. Nítorí náà, kí wọ́n má ṣe jà ọ́ níyàn nípa ọ̀rọ̀ náà. Kí o sì pèpè sọ́dọ̀ Olúwa rẹ. Dájúdájú o kúkú wà lójú ọ̀nà tààrà. ¹
1. Gbólóhùn yìí “Ìjọ kọ̀ọ̀kan l’A fún ní ìlànà tí wọ́n máa lò.” Ìyẹn nínú ’Islām tí Allāhu fi rán Òjíṣẹ́ wọn sí wọn nítorí pé, ’Islām ni ẹ̀sìn gbogbo àwọn Ànábì àti àwọn Òjísẹ́ Olọ́hun, àmọ́ ìlànà ìjọ́sìn kan láààrin ìjọ Òjíṣẹ́ kan sí òmíràn lè yàtọ̀. Bí àpẹ̀ẹrẹ, kò sí ìjọ Òjíṣẹ́ kan tí kò ní ìrun tirẹ̀, àmọ́ òǹkà rakaa àti àsìkò ìrun ń yàtọ̀ láààrin ìjọ Òjíṣẹ́ kan sí òmíràn.
Bákan náà ni ìyàtọ̀ tún lè wà nínú ìṣe àti àṣà láààrin ìjọ Òjíṣẹ́ kan sí òmíràn. Bí àpẹ̀ẹrẹ, àṣà ìkúnlẹ̀-kíni jẹ́ ìṣe tó ní ẹ̀tọ́ nínú ìjọ ìṣáájú, àmọ́ tí ó jẹ́ ìṣe tí ó di èèwọ̀ nínú ìjọ Ànábì wa Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - . Gbogbo ìjọ Òjíṣẹ́ ni wọ́n lè yàtọ̀ síra wọn ní ojú pọ̀n-nà wọ̀nyẹn, àmọ́ kò sí ìyàtọ̀ láààrin ìjọ Òjíṣẹ́ kan sí òmíràn lórí jíjẹ́ tí Allāhu ń jẹ́ Ọlọ́hun ọ̀kan ṣoṣo, Olúwa àti Olùgbàlà. Allāhu sì ṣe ẹbọ ṣíṣe ní èèwọ̀ fún gbogbo wọn pátápátá. Èyí gan-an ni ìpìlẹ̀ fún ìgbàgbọ́ òdodo tí gbogbo àwọn Ànábì àti Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun mú wá - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá wọn - .
Arabic explanations of the Qur’an:
وَإِن جَٰدَلُوكَ فَقُلِ ٱللَّهُ أَعۡلَمُ بِمَا تَعۡمَلُونَ
Tí wọ́n bá sì jà ọ́ níyàn, sọ nígbà náà pé: “Allāhu nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Arabic explanations of the Qur’an:
ٱللَّهُ يَحۡكُمُ بَيۡنَكُمۡ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ فِيمَا كُنتُمۡ فِيهِ تَخۡتَلِفُونَ
Allāhu máa ṣèdájọ́ láààrin yín ní Ọjọ́ Àjíǹde nípa ohun tí ẹ̀ ń yapa ẹnu sí.”
Arabic explanations of the Qur’an:
أَلَمۡ تَعۡلَمۡ أَنَّ ٱللَّهَ يَعۡلَمُ مَا فِي ٱلسَّمَآءِ وَٱلۡأَرۡضِۚ إِنَّ ذَٰلِكَ فِي كِتَٰبٍۚ إِنَّ ذَٰلِكَ عَلَى ٱللَّهِ يَسِيرٞ
Ṣé o ò mọ̀ pé dájúdájú Allāhu l’Ó mọ ohun tí ń bẹ nínú sánmọ̀ àti ilẹ̀? Dájúdájú (àkọsílẹ̀) ìyẹn wà nínú tírà kan. Dájúdájú ìyẹn rọrùn fún Allāhu.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَيَعۡبُدُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ مَا لَمۡ يُنَزِّلۡ بِهِۦ سُلۡطَٰنٗا وَمَا لَيۡسَ لَهُم بِهِۦ عِلۡمٞۗ وَمَا لِلظَّٰلِمِينَ مِن نَّصِيرٖ
Lẹ́yìn Allāhu, wọ́n sì ń jọ́sìn fún ohun tí (Allāhu) kò sọ ẹ̀rí kan kalẹ̀ fún àti ohun tí kò sí ìmọ̀ kan fún wọn lórí rẹ̀. Kò sì níí sí alárànṣe kan fún àwọn alábòsí.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَإِذَا تُتۡلَىٰ عَلَيۡهِمۡ ءَايَٰتُنَا بَيِّنَٰتٖ تَعۡرِفُ فِي وُجُوهِ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ ٱلۡمُنكَرَۖ يَكَادُونَ يَسۡطُونَ بِٱلَّذِينَ يَتۡلُونَ عَلَيۡهِمۡ ءَايَٰتِنَاۗ قُلۡ أَفَأُنَبِّئُكُم بِشَرّٖ مِّن ذَٰلِكُمُۚ ٱلنَّارُ وَعَدَهَا ٱللَّهُ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْۖ وَبِئۡسَ ٱلۡمَصِيرُ
Nígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Wa tó yanjú fún wọn, o máa rí ohun tí ẹ̀mí kọ̀ (ìkorò-ojú) nínú ojú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́; wọn sì fẹ́ẹ̀ fọwọ́ ìnira kan àwọn tí ń ké àwọn āyah Wa fún wọn. Sọ pé: “Ṣé kí n̄g fún yín ní ìró ohun tó burú ju ìyẹn? Iná tí Allāhu ṣèlérí rẹ̀ fún àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ ni. Ìkángun náà sì burú.”
Arabic explanations of the Qur’an:
يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ ضُرِبَ مَثَلٞ فَٱسۡتَمِعُواْ لَهُۥٓۚ إِنَّ ٱلَّذِينَ تَدۡعُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ لَن يَخۡلُقُواْ ذُبَابٗا وَلَوِ ٱجۡتَمَعُواْ لَهُۥۖ وَإِن يَسۡلُبۡهُمُ ٱلذُّبَابُ شَيۡـٔٗا لَّا يَسۡتَنقِذُوهُ مِنۡهُۚ ضَعُفَ ٱلطَّالِبُ وَٱلۡمَطۡلُوبُ
Ẹ̀yin ènìyàn, Wọ́n fi àkàwé kan lélẹ̀. Nítorí náà, ẹ tẹ́tí sí i. Dájúdájú àwọn tí ẹ̀ ń pè lẹ́yìn Allāhu, wọn kò lè dá eṣinṣin kan, wọn ìbàá para pọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Tí eṣinṣin náà bá sì gba kiní kan mọ́ wọn lọ́wọ́, wọn kò lè gbà á padà lọ́wọ́ rẹ̀. Ọ̀lẹ ni ẹni tí ń wá n̄ǹkan (lọ́dọ̀ òrìṣà) àti (òrìṣà) tí wọ́n ń wá n̄ǹkan lọ́dọ̀ rẹ̀.
Arabic explanations of the Qur’an:
مَا قَدَرُواْ ٱللَّهَ حَقَّ قَدۡرِهِۦٓۚ إِنَّ ٱللَّهَ لَقَوِيٌّ عَزِيزٌ
Wọn kò bu ọ̀wọ̀ fún Allāhu ní ọ̀wọ̀ tí ó tọ́ sí I. Dájúdájú Allāhu mà ni Alágbára, Olùborí.
Arabic explanations of the Qur’an:
ٱللَّهُ يَصۡطَفِي مِنَ ٱلۡمَلَٰٓئِكَةِ رُسُلٗا وَمِنَ ٱلنَّاسِۚ إِنَّ ٱللَّهَ سَمِيعُۢ بَصِيرٞ
Allāhu l’Ó ń ṣa àwọn kan lẹ́ṣà (láti jẹ́) Òjíṣẹ́ nínú àwọn mọlāika àti nínú àwọn ènìyàn. Dájúdájú Allāhu ni Olùgbọ́, Olùríran.¹
1. Kíyè sí i! Āyah yìí jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn āyah tí àwọn òpùrọ́ àsoòkùn sẹ́sìn máa ń lò láti fi sọ pé, Allāhu kò ì dáwọ́ fífi iṣẹ́ jíjẹ́ Rẹ̀ rán àwọn ènìyàn kan níṣẹ́ sáyé lẹ́yìn ikú Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - . Àwọn tí wọ́n pa irọ́ ńlá yìí mọ Allāhu kò gbàgbọ́ pé tírà ìkẹ́yìn tí wọ́n fi jíṣẹ́ Allāhu fún gbogbo ayé ni al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé. Àti pé, wọ́n kò gbàgbọ́ pé, Ànábì wa Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ni òpin gbogbo àwọn tí Allāhu fi iṣẹ́ jíjẹ́ Rẹ̀ rán nínú àwọn ènìyàn àti àlùjànnú.
Nípa àìgbàgbọ́ wọn yìí, wọ́n sọ àwọn ààfáà wọn di “wòlíì onímìísí”. Irú àwọn wọ̀nyí ni ìjọ Ahmadiyyah, ìjọ onísūfī Tijäniyyah àti Ƙọ̄diriyyah, àti àwọn ìjọ ẹlẹ́mìí gbígbé. Irú àwọn wọ̀nyí tí jáde kúrò nínú ìgbàgbọ́ òdodo tí ’Islām mú wá pátápátá. Wọ́n ti di aláìgbàgbọ́. Èèwọ̀ sì ni fún mùsùlùmí òdodo láti kí ìrun lẹ́yìn wọn. Bí irú àwọn aláìgbàgbọ́ wọ̀nyí bá wà ní orí ilẹ̀ tí wọ́n ti ń lo ìjọba ’Islām, ìdájọ́ ikú ni ọ̀ràn tí wọ́n dá, àfi tí wọ́n bá tètè ronú pìwàdà. Ẹ tún ka ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-’Ahzāb; 33:40.
Arabic explanations of the Qur’an:
يَعۡلَمُ مَا بَيۡنَ أَيۡدِيهِمۡ وَمَا خَلۡفَهُمۡۚ وَإِلَى ٱللَّهِ تُرۡجَعُ ٱلۡأُمُورُ
Ó mọ ohun tí ń bẹ níwájú wọn àti ní ẹ̀yìn wọn. Ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni wọ́n máa ṣẹ́rí àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀dá padà sí.
Arabic explanations of the Qur’an:
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ ٱرۡكَعُواْ وَٱسۡجُدُواْۤ وَٱعۡبُدُواْ رَبَّكُمۡ وَٱفۡعَلُواْ ٱلۡخَيۡرَ لَعَلَّكُمۡ تُفۡلِحُونَ۩
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ dáwọ́tẹ orúnkún (lórí ìrun), ẹ forí kanlẹ̀, ẹ jọ́sìn fún Olúwa yín, kí ẹ sì ṣe rere nítorí kí ẹ lè jèrè.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَجَٰهِدُواْ فِي ٱللَّهِ حَقَّ جِهَادِهِۦۚ هُوَ ٱجۡتَبَىٰكُمۡ وَمَا جَعَلَ عَلَيۡكُمۡ فِي ٱلدِّينِ مِنۡ حَرَجٖۚ مِّلَّةَ أَبِيكُمۡ إِبۡرَٰهِيمَۚ هُوَ سَمَّىٰكُمُ ٱلۡمُسۡلِمِينَ مِن قَبۡلُ وَفِي هَٰذَا لِيَكُونَ ٱلرَّسُولُ شَهِيدًا عَلَيۡكُمۡ وَتَكُونُواْ شُهَدَآءَ عَلَى ٱلنَّاسِۚ فَأَقِيمُواْ ٱلصَّلَوٰةَ وَءَاتُواْ ٱلزَّكَوٰةَ وَٱعۡتَصِمُواْ بِٱللَّهِ هُوَ مَوۡلَىٰكُمۡۖ فَنِعۡمَ ٱلۡمَوۡلَىٰ وَنِعۡمَ ٱلنَّصِيرُ
Ẹ jagun fún ẹ̀sìn Allāhu ní ọ̀nà ẹ̀tọ́ tí ẹ lè gbà jagun fún Un. Òun l’Ó ṣà yín lẹ́ṣà, kò sì kó ìdààmú kan kan ba yín nínú ẹ̀sìn. (Ẹ tẹ̀lé) ẹ̀sìn bàbá yín (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm. (Allāhu) l’Ó sọ yín ní mùsùlùmí ṣíwájú (àsìkò yìí) àti nínú (al-Ƙur’ān) yìí nítorí kí Òjíṣẹ́ lè jẹ́ ẹlẹ́rìí fún yín àti nítorí kí ẹ̀yin náà lè jẹ́ ẹlẹ́rìí fún àwọn ènìyàn.¹ Nítorí náà, ẹ kírun, ẹ yọ Zakāh, kí ẹ sì bá Allāhu dúró. Òun ni Aláàbò yín. Ó dára ni Aláàbò. Ó sì dára ní Alárànṣe.
1. Ọ̀kan pàtàkì nínú ẹ̀rí tó ń fi rinlẹ̀ pé, Allāhu kò fi ẹ̀sìn nasrọ̄niyyah tàbí ẹ̀sìn yahudiyyah rán Òjíṣẹ́ kan kan rí ni gbólóhùn “(Allāhu) l’Ó sọ yín ní mùsùlùmí ṣíwájú (àsìkò yìí) àti nínú (al-Ƙur’ān) yìí”. Gbólóhùn náà ti fi hàn kedere pé, Allāhu - tó ga jùlọ - t’Ó fi ẹ̀sìn kan ṣoṣo rán gbogbo àwọn Ànábì àti àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀ - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá wọn -, Òun l’Ó sọ ẹ̀sìn náà ni ’Islām. Ó sì sọ ẹlẹ́sìn náà ni “mùsùlùmí”. Tí ẹnì kan bá pe ara rẹ̀ ní nasọ̄rọ̄, ẹ bi í léèrè pé “ta ni ó sọ ẹ̀sìn kan ní nasrọniyyah? Ta sì ni ó sọ wọ́n ní nasọ̄rọ̄?” Ó dájú pé kì í ṣe Allāhu, Ọlọ́hun - tó ga jùlọ -. Ẹyìn àti ọpẹ́ ni fún Allāhu tí Ó tọ́ wa sọ́nà tààrà Rẹ̀, ’Islām.
Arabic explanations of the Qur’an:
 
Translation of the meanings Surah: Al-Hajj
Surahs’ Index Page Number
 
Translation of the Meanings of the Noble Qur'an - Yoruba translation - Translations’ Index

Translation of the Quran meanings into Yoruba by Abu Rahima Mikhail Aikweiny, printed in 1432 H.

close