Check out the new design

Translation of the Meanings of the Noble Qur'an - Yoruba translation - Abu Rahima Mikael * - Translations’ Index

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Translation of the meanings Surah: Saba’   Ayah:
أَفۡتَرَىٰ عَلَى ٱللَّهِ كَذِبًا أَم بِهِۦ جِنَّةُۢۗ بَلِ ٱلَّذِينَ لَا يُؤۡمِنُونَ بِٱلۡأٓخِرَةِ فِي ٱلۡعَذَابِ وَٱلضَّلَٰلِ ٱلۡبَعِيدِ
Ṣé ó dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu ni tàbí àlùjànnú ń bẹ lára rẹ̀ ni?” Rárá o! Àwọn tí kò gba Ọjọ́ Ìkẹ́yìn gbọ́ ti wà nínú ìyà àti ìṣìnà tó jìnnà.
Arabic explanations of the Qur’an:
أَفَلَمۡ يَرَوۡاْ إِلَىٰ مَا بَيۡنَ أَيۡدِيهِمۡ وَمَا خَلۡفَهُم مِّنَ ٱلسَّمَآءِ وَٱلۡأَرۡضِۚ إِن نَّشَأۡ نَخۡسِفۡ بِهِمُ ٱلۡأَرۡضَ أَوۡ نُسۡقِطۡ عَلَيۡهِمۡ كِسَفٗا مِّنَ ٱلسَّمَآءِۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَةٗ لِّكُلِّ عَبۡدٖ مُّنِيبٖ
Ṣé wọn kò rí ohun tó ń bẹ níwájú wọn àti ohun tó ń bẹ lẹ́yìn wọn ní sánmọ̀ àti ilẹ̀? Tí A bá fẹ́, Àwa ìbá jẹ́ kí ilẹ̀ ri mọ́ wọn lẹ́sẹ̀, tàbí kí Á já apá kan nínú sánmọ̀ lulẹ̀ lé wọn lórí mọ́lẹ̀. Dájúdájú àmì kan wà nínú ìyẹn fún gbogbo ẹrúsìn, olùronúpìwàdà.
Arabic explanations of the Qur’an:
۞ وَلَقَدۡ ءَاتَيۡنَا دَاوُۥدَ مِنَّا فَضۡلٗاۖ يَٰجِبَالُ أَوِّبِي مَعَهُۥ وَٱلطَّيۡرَۖ وَأَلَنَّا لَهُ ٱلۡحَدِيدَ
Dájúdájú A ti fún (Ànábì) Dāwūd ní oore àjùlọ láti ọ̀dọ̀ Wa; Ẹ̀yin àpáta, ẹ ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú rẹ̀. (A pe) àwọn ẹyẹ náà (pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀.) A sì rọ irin fún un.
Arabic explanations of the Qur’an:
أَنِ ٱعۡمَلۡ سَٰبِغَٰتٖ وَقَدِّرۡ فِي ٱلسَّرۡدِۖ وَٱعۡمَلُواْ صَٰلِحًاۖ إِنِّي بِمَا تَعۡمَلُونَ بَصِيرٞ
(A sọ fún un) pé, ṣe àwọn ẹ̀wù irin tó máa bo ara dáadáa, ṣe òrùka fún ẹ̀wù irin náà níwọ̀n-níwọ̀n. Kí ẹ sì ṣe rere. Dájúdájú Èmi ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَلِسُلَيۡمَٰنَ ٱلرِّيحَ غُدُوُّهَا شَهۡرٞ وَرَوَاحُهَا شَهۡرٞۖ وَأَسَلۡنَا لَهُۥ عَيۡنَ ٱلۡقِطۡرِۖ وَمِنَ ٱلۡجِنِّ مَن يَعۡمَلُ بَيۡنَ يَدَيۡهِ بِإِذۡنِ رَبِّهِۦۖ وَمَن يَزِغۡ مِنۡهُمۡ عَنۡ أَمۡرِنَا نُذِقۡهُ مِنۡ عَذَابِ ٱلسَّعِيرِ
Àti pé (A tẹ) atẹ́gùn lórí bá fún (Ànábì) Sulaemọ̄n, ìrìn oṣù kan ni ìrìn òwúrọ̀ rẹ̀, ìrìn oṣù kan sì ni ìrìn ìrọ̀lẹ́ rẹ̀[1]. A sì mú kí odò idẹ máa ṣàn nínú ilẹ̀ fún un. Ó sì wà nínú àwọn àlùjànnú, èyí tó ń ṣiṣẹ́ (fún un) níwájú rẹ̀ pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Olúwa rẹ̀. Àti pé ẹni tí ó bá yẹ̀ kúrò níbi àṣẹ Wa nínú wọn, A máa fún un ní ìyà iná tó ń jó tọ́ wò.
1. Èyí já sí pé Ànábì Sulaemọ̄n - kí ọlà Allāhu máa bá a - ń rin ìrìn oṣù méjì ní ojúmọ́ bí ó bá fẹ́ rìn jáde pẹ̀lú atẹ́gùn.
Arabic explanations of the Qur’an:
يَعۡمَلُونَ لَهُۥ مَا يَشَآءُ مِن مَّحَٰرِيبَ وَتَمَٰثِيلَ وَجِفَانٖ كَٱلۡجَوَابِ وَقُدُورٖ رَّاسِيَٰتٍۚ ٱعۡمَلُوٓاْ ءَالَ دَاوُۥدَ شُكۡرٗاۚ وَقَلِيلٞ مِّنۡ عِبَادِيَ ٱلشَّكُورُ
Wọ́n ń ṣe iṣẹ́ tí ó bá fẹ́ fún un nípa mímọ àwọn ilé (ilé ìjọ́sìn àti ilé ìgbé), àwọn ère,[1] àwọn àwo tó jìn kòtò tó fẹ̀ bí àbàtಠàti àwọn ìkòkò tó rídìí múlẹ̀.³ Ẹ̀yin ènìyàn (Ànábì) Dāwūd, ẹ ṣiṣẹ́ ìdúpẹ́ (fún Allāhu). Díẹ̀ nínú àwọn ẹrúsìn Mi sì ni olùdúpẹ́.
1. Ní àsìkò Ànábì Sulaemọ̄n - kí ọlà Allāhu máa bá a -, gbígbẹ́ ère fún fífi ṣe ọ̀ṣọ́ sínú ilé kì í ṣe èèwọ̀. Àmọ́ ní àsìkò Ànábì wa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -, ó ti di èèwọ̀, yálà ó jẹ́ ère tàbí àwòrán n̄ǹkan abẹ̀mí. 2. Àpẹ̀ẹrẹ ìyẹn ni àwọn àwo tí àwọn ènìyàn máa ń ṣe sínú ilé ìwẹ̀ tí ènìyàn máa ń wẹ̀ nínú rẹ̀ “bath tub”. 3. Àpẹ̀ẹrẹ ìyẹn ni àwọn apẹ irin ìdáná ńlá ńlá.
Arabic explanations of the Qur’an:
فَلَمَّا قَضَيۡنَا عَلَيۡهِ ٱلۡمَوۡتَ مَا دَلَّهُمۡ عَلَىٰ مَوۡتِهِۦٓ إِلَّا دَآبَّةُ ٱلۡأَرۡضِ تَأۡكُلُ مِنسَأَتَهُۥۖ فَلَمَّا خَرَّ تَبَيَّنَتِ ٱلۡجِنُّ أَن لَّوۡ كَانُواْ يَعۡلَمُونَ ٱلۡغَيۡبَ مَا لَبِثُواْ فِي ٱلۡعَذَابِ ٱلۡمُهِينِ
Nígbà tí A pàṣẹ pé kí ikú pa (Ànábì) Sulaemọ̄n, kò sí ohun tí ó mú àwọn àlùjànnú mọ̀ pé ó ti kú bí kò ṣe kòkòrò inú ilẹ̀ kan tí ó jẹ ọ̀pá rẹ̀. Nígbà tí ó wó lulẹ̀, ó hàn kedere sí àwọn àlùjànnú pé tí ó bá jẹ́ pé àwọn ní ìmọ̀ ìkọ̀kọ̀ ni, àwọn ìbá tí wà nínú (iṣẹ́) ìyà tó ń yẹpẹrẹ ẹ̀dá.
Arabic explanations of the Qur’an:
 
Translation of the meanings Surah: Saba’
Surahs’ Index Page Number
 
Translation of the Meanings of the Noble Qur'an - Yoruba translation - Abu Rahima Mikael - Translations’ Index

Translated by Sh. Abu Rahima Mikael Ekoyini

close