Check out the new design

Translation of the Meanings of the Noble Qur'an - Yoruba translation - Abu Rahima Mikael * - Translations’ Index

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Translation of the meanings Surah: Saba’   Ayah:
وَلَا تَنفَعُ ٱلشَّفَٰعَةُ عِندَهُۥٓ إِلَّا لِمَنۡ أَذِنَ لَهُۥۚ حَتَّىٰٓ إِذَا فُزِّعَ عَن قُلُوبِهِمۡ قَالُواْ مَاذَا قَالَ رَبُّكُمۡۖ قَالُواْ ٱلۡحَقَّۖ وَهُوَ ٱلۡعَلِيُّ ٱلۡكَبِيرُ
Ìṣìpẹ̀ kò sì níí ṣàǹfààní lọ́dọ̀ Allāhu àfi fún ẹni tí Ó bá yọ̀ǹda fún. (Inúfu-àyàfu ní àwọn olùṣìpẹ̀ àti àwọn olùṣìpẹ̀-fún máa wà) títí A óò fi yọ ìjáyà kúrò nínú ọkàn wọn. Wọ́n sì máa sọ (fún àwọn mọlāika) pé: “Kí ni Olúwa yín sọ (ní èsì ìṣìpẹ̀)?” Wọ́n máa sọ pé: “Òdodo l’Ó sọ (ìṣìpẹ̀ yin ti wọlé. Allāhu) Òun l’Ó ga, Ó tóbi.[1]
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Baƙọrah; 2:48.
Arabic explanations of the Qur’an:
۞ قُلۡ مَن يَرۡزُقُكُم مِّنَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۖ قُلِ ٱللَّهُۖ وَإِنَّآ أَوۡ إِيَّاكُمۡ لَعَلَىٰ هُدًى أَوۡ فِي ضَلَٰلٖ مُّبِينٖ
Sọ pé: “Ta ni Ó ń pèsè fún yín láti inú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀?” Sọ pé: “Allāhu ni.” Dájúdájú àwa tàbí ẹ̀yin wà nínú ìmọ̀nà tàbí nínú ìṣìnà pọ́nńbélé.[1]
1. Àwọn nasọ̄rọ̄ lérò pé Ànábì wa Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ń ṣeyèméjì nípa ẹ̀sìn rẹ̀ ni gbólóhùn yẹn fi parí āyah yẹn. Ọ̀rọ̀ kò sì rí bẹ́ẹ̀. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Baƙọrah; 2:74.
Arabic explanations of the Qur’an:
قُل لَّا تُسۡـَٔلُونَ عَمَّآ أَجۡرَمۡنَا وَلَا نُسۡـَٔلُ عَمَّا تَعۡمَلُونَ
Sọ pé: “Wọn kò níí bi yín léèrè nípa ẹ̀ṣẹ̀ tí a dá; wọn kò sì níí bi àwa náà nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.”
Arabic explanations of the Qur’an:
قُلۡ يَجۡمَعُ بَيۡنَنَا رَبُّنَا ثُمَّ يَفۡتَحُ بَيۡنَنَا بِٱلۡحَقِّ وَهُوَ ٱلۡفَتَّاحُ ٱلۡعَلِيمُ
Sọ pé: “Olúwa wa yóò kó wa jọ papọ̀. Lẹ́yìn náà, Ó máa fi òdodo ṣèdájọ́ láààrin wa. Òun sì ni Onídàájọ́, Onímọ̀.”
Arabic explanations of the Qur’an:
قُلۡ أَرُونِيَ ٱلَّذِينَ أَلۡحَقۡتُم بِهِۦ شُرَكَآءَۖ كَلَّاۚ بَلۡ هُوَ ٱللَّهُ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡحَكِيمُ
Sọ pé: “Ẹ fi hàn mí ná àwọn òrìṣà tí ẹ dàpọ̀ mọ́ Allāhu.” Rárá (kò ní akẹgbẹ́). Rárá sẹ́, Òun ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَمَآ أَرۡسَلۡنَٰكَ إِلَّا كَآفَّةٗ لِّلنَّاسِ بَشِيرٗا وَنَذِيرٗا وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَ ٱلنَّاسِ لَا يَعۡلَمُونَ
A kò rán ọ níṣẹ́ àfi sí gbogbo ènìyàn pátápátá; (o jẹ́) oníròó-ìdùnnú àti olùkìlọ̀ ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn kò mọ̀.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَيَقُولُونَ مَتَىٰ هَٰذَا ٱلۡوَعۡدُ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ
Wọ́n ń wí pé: “Ìgbà wo ni àdéhùn yìí yóò ṣẹ tí ẹ bá jẹ́ olódodo?”
Arabic explanations of the Qur’an:
قُل لَّكُم مِّيعَادُ يَوۡمٖ لَّا تَسۡتَـٔۡخِرُونَ عَنۡهُ سَاعَةٗ وَلَا تَسۡتَقۡدِمُونَ
Sọ pé: “Àdéhùn ọjọ́ kan ń bẹ fún yín, tí ẹ kò níí lè sún un ṣíwájú di àkókò kan, ẹ kò sì níí lè fà á sẹ́yìn.”[1]
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah Al-’a‘rọ̄f; 7:34.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَقَالَ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ لَن نُّؤۡمِنَ بِهَٰذَا ٱلۡقُرۡءَانِ وَلَا بِٱلَّذِي بَيۡنَ يَدَيۡهِۗ وَلَوۡ تَرَىٰٓ إِذِ ٱلظَّٰلِمُونَ مَوۡقُوفُونَ عِندَ رَبِّهِمۡ يَرۡجِعُ بَعۡضُهُمۡ إِلَىٰ بَعۡضٍ ٱلۡقَوۡلَ يَقُولُ ٱلَّذِينَ ٱسۡتُضۡعِفُواْ لِلَّذِينَ ٱسۡتَكۡبَرُواْ لَوۡلَآ أَنتُمۡ لَكُنَّا مُؤۡمِنِينَ
Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ wí pé: “A kò níí ní ìgbàgbọ́ nínú al-Ƙur’ān yìí àti èyí tó wá ṣíwájú rẹ̀.” Tí ó bá jẹ́ pé o bá rí wọn ni nígbà tí wọ́n bá dá àwọn alábòsí dúró níwájú Olúwa wọn, (o máa rí wọn tí) apá kan wọn yóò dá ọ̀rọ̀ náà padà sí apá kan; àwọn tí wọ́n sọ di ọ̀lẹ (nínú wọn) yóò wí fún àwọn tó ṣègbéraga (nínú wọn) pé: “Tí kì í bá ṣe ẹ̀yin ni, àwa ìbá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.”
Arabic explanations of the Qur’an:
 
Translation of the meanings Surah: Saba’
Surahs’ Index Page Number
 
Translation of the Meanings of the Noble Qur'an - Yoruba translation - Abu Rahima Mikael - Translations’ Index

Translated by Sh. Abu Rahima Mikael Ekoyini

close