Check out the new design

Translation of the Meanings of the Noble Qur'an - Yoruba translation - Abu Rahima Mikael * - Translations’ Index

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Translation of the meanings Surah: Al-Mā’idah   Ayah:
لُعِنَ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ مِنۢ بَنِيٓ إِسۡرَٰٓءِيلَ عَلَىٰ لِسَانِ دَاوُۥدَ وَعِيسَى ٱبۡنِ مَرۡيَمَۚ ذَٰلِكَ بِمَا عَصَواْ وَّكَانُواْ يَعۡتَدُونَ
Wọ́n ṣẹ́bi lé àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl lórí ahọ́n (Ànábì) Dāwūd àti ‘Īsā ọmọ Mọryam. Ìyẹn nítorí pé, wọ́n yapa (àṣẹ Allāhu), wọ́n sì ń tayọ ẹnu-ààlà.
Arabic explanations of the Qur’an:
كَانُواْ لَا يَتَنَاهَوۡنَ عَن مُّنكَرٖ فَعَلُوهُۚ لَبِئۡسَ مَا كَانُواْ يَفۡعَلُونَ
Wọn kì í kọ ìwà ìbàjẹ́ tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ láààrin ara wọn. Ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ sì burú.
Arabic explanations of the Qur’an:
تَرَىٰ كَثِيرٗا مِّنۡهُمۡ يَتَوَلَّوۡنَ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْۚ لَبِئۡسَ مَا قَدَّمَتۡ لَهُمۡ أَنفُسُهُمۡ أَن سَخِطَ ٱللَّهُ عَلَيۡهِمۡ وَفِي ٱلۡعَذَابِ هُمۡ خَٰلِدُونَ
O máa rí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú wọn tó ń bá àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ ṣọ̀rẹ́. Ohun tí ẹ̀mí wọn tì síwájú fún wọn sì burú tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí Allāhu fi bínú sí wọn. Olùṣegbére sì ni wọ́n nínú Ìyà.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَلَوۡ كَانُواْ يُؤۡمِنُونَ بِٱللَّهِ وَٱلنَّبِيِّ وَمَآ أُنزِلَ إِلَيۡهِ مَا ٱتَّخَذُوهُمۡ أَوۡلِيَآءَ وَلَٰكِنَّ كَثِيرٗا مِّنۡهُمۡ فَٰسِقُونَ
Tí ó bá jẹ́ pé wọ́n gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -, àti ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fún un, wọn kò níí mú wọn ní ọ̀rẹ́ àyò, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú wọn ni òbìlẹ̀jẹ́.
Arabic explanations of the Qur’an:
۞ لَتَجِدَنَّ أَشَدَّ ٱلنَّاسِ عَدَٰوَةٗ لِّلَّذِينَ ءَامَنُواْ ٱلۡيَهُودَ وَٱلَّذِينَ أَشۡرَكُواْۖ وَلَتَجِدَنَّ أَقۡرَبَهُم مَّوَدَّةٗ لِّلَّذِينَ ءَامَنُواْ ٱلَّذِينَ قَالُوٓاْ إِنَّا نَصَٰرَىٰۚ ذَٰلِكَ بِأَنَّ مِنۡهُمۡ قِسِّيسِينَ وَرُهۡبَانٗا وَأَنَّهُمۡ لَا يَسۡتَكۡبِرُونَ
Dájúdájú o máa rí i pé àwọn ènìyàn tí ọ̀tá wọn le jùlọ sí àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo ni àwọn yẹhudi àti àwọn ọ̀ṣẹbọ. Dájúdájú o sì máa rí i pé àwọn ènìyàn tó súnmọ́ àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo jùlọ ní ìfẹ́ ni àwọn tó wí pé: “Dájúdájú nasọ̄rọ̄ ni àwa.” Ìyẹn nítorí pé àwọn àlùfáà àti olùfọkànsìn ń bẹ láààrin wọn. Àti pé dájúdáju wọn kò níí ṣègbéraga (sí òdodo).
Arabic explanations of the Qur’an:
وَإِذَا سَمِعُواْ مَآ أُنزِلَ إِلَى ٱلرَّسُولِ تَرَىٰٓ أَعۡيُنَهُمۡ تَفِيضُ مِنَ ٱلدَّمۡعِ مِمَّا عَرَفُواْ مِنَ ٱلۡحَقِّۖ يَقُولُونَ رَبَّنَآ ءَامَنَّا فَٱكۡتُبۡنَا مَعَ ٱلشَّٰهِدِينَ
Nígbà tí wọ́n bá gbọ́ ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fún Òjíṣẹ́ náà, o máa rí ẹyinjú wọn tí ó máa damije nítorí ohun tí wọ́n ti mọ̀ nínú òdodo. Wọ́n á sì sọ pé: “Olúwa wa, a gbàgbọ́ ní òdodo, kọ wá mọ́ ara àwọn olùjẹ́rìí (òdodo).
Arabic explanations of the Qur’an:
 
Translation of the meanings Surah: Al-Mā’idah
Surahs’ Index Page Number
 
Translation of the Meanings of the Noble Qur'an - Yoruba translation - Abu Rahima Mikael - Translations’ Index

Translated by Sh. Abu Rahima Mikael Ekoyini

close