Check out the new design

Translation of the Meanings of the Noble Qur'an - Yoruba translation - Abu Rahima Mikael * - Translations’ Index

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Translation of the meanings Surah: Al-Mā’idah   Ayah:
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ إِذَا قُمۡتُمۡ إِلَى ٱلصَّلَوٰةِ فَٱغۡسِلُواْ وُجُوهَكُمۡ وَأَيۡدِيَكُمۡ إِلَى ٱلۡمَرَافِقِ وَٱمۡسَحُواْ بِرُءُوسِكُمۡ وَأَرۡجُلَكُمۡ إِلَى ٱلۡكَعۡبَيۡنِۚ وَإِن كُنتُمۡ جُنُبٗا فَٱطَّهَّرُواْۚ وَإِن كُنتُم مَّرۡضَىٰٓ أَوۡ عَلَىٰ سَفَرٍ أَوۡ جَآءَ أَحَدٞ مِّنكُم مِّنَ ٱلۡغَآئِطِ أَوۡ لَٰمَسۡتُمُ ٱلنِّسَآءَ فَلَمۡ تَجِدُواْ مَآءٗ فَتَيَمَّمُواْ صَعِيدٗا طَيِّبٗا فَٱمۡسَحُواْ بِوُجُوهِكُمۡ وَأَيۡدِيكُم مِّنۡهُۚ مَا يُرِيدُ ٱللَّهُ لِيَجۡعَلَ عَلَيۡكُم مِّنۡ حَرَجٖ وَلَٰكِن يُرِيدُ لِيُطَهِّرَكُمۡ وَلِيُتِمَّ نِعۡمَتَهُۥ عَلَيۡكُمۡ لَعَلَّكُمۡ تَشۡكُرُونَ
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, nígbà tí ẹ bá fẹ́ kírun, ẹ wẹ ojú yín àti ọwọ́ yín títí dé ìgúnpá. Ẹ fi omi pá orí yín. Ẹ wẹ ẹsẹ̀ yín títí dé kókósẹ̀ méjèèjì. Tí ẹ bá ní jánnábà lára, ẹ wẹ ìwẹ̀ ìmọ́ra. Tí ẹ bá jẹ́ aláìsàn, tàbí ẹ wà lórí ìrìn-àjò tàbí ẹnì kan nínú yín dé láti ilé ìgbọ̀nsẹ̀, tàbí ẹ súnmọ́ obìnrin, tí ẹ ò bá rí omi, nígbà náà kí ẹ fi erùpẹ̀ mímọ́ ṣe tayamọmu. Ẹ fi pá ojú yín àti ọwọ́ yín lára rẹ̀. Allāhu kò fẹ́ láti kó wàhálà ba yín, ṣùgbọ́n Ó fẹ́ láti fọ̀ yín mọ́. Ó sì fẹ́ ṣe àṣepé ìdẹ̀ra Rẹ̀ fún yín nítorí kí ẹ lè dúpẹ́.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَٱذۡكُرُواْ نِعۡمَةَ ٱللَّهِ عَلَيۡكُمۡ وَمِيثَٰقَهُ ٱلَّذِي وَاثَقَكُم بِهِۦٓ إِذۡ قُلۡتُمۡ سَمِعۡنَا وَأَطَعۡنَاۖ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَۚ إِنَّ ٱللَّهَ عَلِيمُۢ بِذَاتِ ٱلصُّدُورِ
Ẹ rántí ìdẹ̀ra tí Allāhu ṣe fún yín àti àdéhùn Rẹ̀, èyí tí Ó ba yín ṣe, nígbà tí ẹ̀yin sọ pé: “A gbọ́, a sì tẹ̀lé e.” Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa ohun tí ń bẹ nínú igbá-àyà ẹ̀dá.
Arabic explanations of the Qur’an:
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ كُونُواْ قَوَّٰمِينَ لِلَّهِ شُهَدَآءَ بِٱلۡقِسۡطِۖ وَلَا يَجۡرِمَنَّكُمۡ شَنَـَٔانُ قَوۡمٍ عَلَىٰٓ أَلَّا تَعۡدِلُواْۚ ٱعۡدِلُواْ هُوَ أَقۡرَبُ لِلتَّقۡوَىٰۖ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَۚ إِنَّ ٱللَّهَ خَبِيرُۢ بِمَا تَعۡمَلُونَ
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ jẹ́ olùdúró ṣinṣin lórí déédé nítorí ti Allāhu nígbà tí ẹ bá ń jẹ́rìí. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ìkórira àwọn ènìyàn kan tì yín láti má ṣe déédé. Ẹ ṣe déédé, òhun l’ó súnmọ́ ìbẹ̀rù Allāhu jùlọ. Kí ẹ sì bẹ̀rù Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.[1]
1. Ẹ tún wo sūrah an-Nisā’; 4:135.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَعَدَ ٱللَّهُ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ لَهُم مَّغۡفِرَةٞ وَأَجۡرٌ عَظِيمٞ
Allāhu ṣe àdéhùn fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣiṣẹ́ rere (pé) àforíjìn àti ẹ̀san ńlá ń bẹ fún wọn.
Arabic explanations of the Qur’an:
 
Translation of the meanings Surah: Al-Mā’idah
Surahs’ Index Page Number
 
Translation of the Meanings of the Noble Qur'an - Yoruba translation - Abu Rahima Mikael - Translations’ Index

Translated by Sh. Abu Rahima Mikael Ekoyini

close