Check out the new design

Translation of the Meanings of the Noble Qur'an - Yoruba translation - Abu Rahima Mikael * - Translations’ Index

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Translation of the meanings Surah: Al-Insān   Ayah:
عَيۡنٗا يَشۡرَبُ بِهَا عِبَادُ ٱللَّهِ يُفَجِّرُونَهَا تَفۡجِيرٗا
Omi ìṣẹ́lẹ̀rú kan ni, tí àwọn ẹrúsìn Allāhu yóò máa mu, tí wọn yó sì máa mú un ṣàn jáde dáadáa (ní ibi tí wọ́n bá ti fẹ́ ẹ).
Arabic explanations of the Qur’an:
يُوفُونَ بِٱلنَّذۡرِ وَيَخَافُونَ يَوۡمٗا كَانَ شَرُّهُۥ مُسۡتَطِيرٗا
Wọ́n ń mú ẹ̀jẹ́ wọn ṣẹ. Wọ́n sì ń páyà ọjọ́ kan, tí aburú rẹ̀ jẹ́ ohun tí ó máa fọ́nká gan-an.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَيُطۡعِمُونَ ٱلطَّعَامَ عَلَىٰ حُبِّهِۦ مِسۡكِينٗا وَيَتِيمٗا وَأَسِيرًا
Tòhun ti bí wọ́n ṣe ní ìfẹ́ sí (ọrọ̀ tó), wọ́n ń fún mẹ̀kúnnù, ọmọ òrukàn àti ẹrú ní oúnjẹ jẹ.
Arabic explanations of the Qur’an:
إِنَّمَا نُطۡعِمُكُمۡ لِوَجۡهِ ٱللَّهِ لَا نُرِيدُ مِنكُمۡ جَزَآءٗ وَلَا شُكُورًا
(Wọ́n sì ń sọ pé:) “Nítorí Ojú rere Allāhu (nìkan) l’a fi ń fun yín ní oúnjẹ jẹ; àwa kò sì gbèrò ẹ̀san tàbí ìdúpẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ yín.
Arabic explanations of the Qur’an:
إِنَّا نَخَافُ مِن رَّبِّنَا يَوۡمًا عَبُوسٗا قَمۡطَرِيرٗا
Dájúdájú àwa ń páyà ọjọ́ kan tí (ẹ̀dá yóò) fajú ro kókó ní ọ̀dọ̀ Olúwa wa.”
Arabic explanations of the Qur’an:
فَوَقَىٰهُمُ ٱللَّهُ شَرَّ ذَٰلِكَ ٱلۡيَوۡمِ وَلَقَّىٰهُمۡ نَضۡرَةٗ وَسُرُورٗا
Nítorí náà, Allāhu yóò ṣọ́ wọn níbi aburú ọjọ́ yẹn. Ó sì máa fún wọn ni ìtutù ojú àti ìdùnnú.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَجَزَىٰهُم بِمَا صَبَرُواْ جَنَّةٗ وَحَرِيرٗا
Ó sì máa san wọ́n ní ẹ̀san Ọgbà Ìdẹ̀ra àti aṣọ àlàárì nítorí pé wọ́n ṣe sùúrù.
Arabic explanations of the Qur’an:
مُّتَّكِـِٔينَ فِيهَا عَلَى ٱلۡأَرَآئِكِۖ لَا يَرَوۡنَ فِيهَا شَمۡسٗا وَلَا زَمۡهَرِيرٗا
Wọn yóò máa rọ̀gbọ̀kú sórí àwọn ibùsùn wọn. Wọn kò sì níí rí òòrùn tàbí òtútù.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَدَانِيَةً عَلَيۡهِمۡ ظِلَٰلُهَا وَذُلِّلَتۡ قُطُوفُهَا تَذۡلِيلٗا
Àwọn ibòji (inú Ọgbà Ìdẹ̀ra) yóò súnmọ́ wọn. A sì máa mú àwọn esò ibẹ̀ súnmọ́ àrọ́wọ́tó wọn ní ti sísúnmọ́.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَيُطَافُ عَلَيۡهِم بِـَٔانِيَةٖ مِّن فِضَّةٖ وَأَكۡوَابٖ كَانَتۡ قَوَارِيرَا۠
Àti pé wọn yóò máa gbé ife ìmumi ńlá tí wọ́n ṣe láti ara fàdákà àti àwọn ife ìmumi kékeré tí ó jẹ́ aláwo káà kiri ọ̀dọ̀ wọn.
Arabic explanations of the Qur’an:
قَوَارِيرَاْ مِن فِضَّةٖ قَدَّرُوهَا تَقۡدِيرٗا
Ife aláwo tí wọ́n ṣe láti ara fàdákà ni (wọ́n). A sì ṣe wọ́n níwọ̀n- níwọ̀n (tí ó ṣe wẹ́kú ohun tí wọ́n fẹ́ mu).
Arabic explanations of the Qur’an:
وَيُسۡقَوۡنَ فِيهَا كَأۡسٗا كَانَ مِزَاجُهَا زَنجَبِيلًا
Àti pé wọn yóò máa fún wọn ní ife ọtí kan mu nínú (Ọgbà Ìdẹ̀ra). Ohun tí A pòpọ̀ mọ́ (ọtí náà) ni atalẹ̀.
Arabic explanations of the Qur’an:
عَيۡنٗا فِيهَا تُسَمَّىٰ سَلۡسَبِيلٗا
Nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra (wọn yóò tún máa mu) omi ìṣẹ́lẹ̀rú kan, tí À ń pè ní omi salsabīl.
Arabic explanations of the Qur’an:
۞ وَيَطُوفُ عَلَيۡهِمۡ وِلۡدَٰنٞ مُّخَلَّدُونَ إِذَا رَأَيۡتَهُمۡ حَسِبۡتَهُمۡ لُؤۡلُؤٗا مَّنثُورٗا
Àwọn ọ̀dọ́kùnrin tí kò níí gbó yó sì máa lọ bọ̀ láààrin wọn. Nígbà tí ìwọ bá sì rí wọn, ìwọ yóò kà wọ́n kún òkúta olówó iyebíye tí wọ́n fọ́n kalẹ̀.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَإِذَا رَأَيۡتَ ثَمَّ رَأَيۡتَ نَعِيمٗا وَمُلۡكٗا كَبِيرًا
Nígbà tí ìwọ bá sì wo ibẹ̀ yẹn (nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra), ìwọ yóò rí ìdẹ̀ra àti ọlá tó tóbi.
Arabic explanations of the Qur’an:
عَٰلِيَهُمۡ ثِيَابُ سُندُسٍ خُضۡرٞ وَإِسۡتَبۡرَقٞۖ وَحُلُّوٓاْ أَسَاوِرَ مِن فِضَّةٖ وَسَقَىٰهُمۡ رَبُّهُمۡ شَرَابٗا طَهُورًا
Aṣọ àlàárì fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ aláwọ̀ ewéko àti aṣọ àlàárì tó nípọn máa wà lókè wọn (àti lára wọn). A sì máa fi ẹ̀gbà-ọwọ́ onífàdákà ṣe wọ́n ní ọ̀ṣọ́. Olúwa wọn yó sì fún wọn ní ohun mímu mímọ́ mu.
Arabic explanations of the Qur’an:
إِنَّ هَٰذَا كَانَ لَكُمۡ جَزَآءٗ وَكَانَ سَعۡيُكُم مَّشۡكُورًا
Dájúdájú èyí jẹ́ ẹ̀san fun yín. Wọ́n sì máa fi ẹ̀san rere àdìpèlé dúpẹ́ iṣẹ́ yín fun yín.
Arabic explanations of the Qur’an:
إِنَّا نَحۡنُ نَزَّلۡنَا عَلَيۡكَ ٱلۡقُرۡءَانَ تَنزِيلٗا
Dájúdájú Àwa l’A sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ fún ọ díẹ̀ díẹ̀.[1]
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-’Isrọ̄’; 17:106.
Arabic explanations of the Qur’an:
فَٱصۡبِرۡ لِحُكۡمِ رَبِّكَ وَلَا تُطِعۡ مِنۡهُمۡ ءَاثِمًا أَوۡ كَفُورٗا
Nítorí náà, ṣe sùúrù fún ìdájọ́ Olúwa rẹ. Má ṣe tẹ̀lé ẹlẹ́ṣẹ̀ tàbí aláìmoore kan nínú wọn.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَٱذۡكُرِ ٱسۡمَ رَبِّكَ بُكۡرَةٗ وَأَصِيلٗا
Rántí orúkọ Olúwa rẹ ní àárọ̀ àti ní ìrọ̀lẹ́.
Arabic explanations of the Qur’an:
 
Translation of the meanings Surah: Al-Insān
Surahs’ Index Page Number
 
Translation of the Meanings of the Noble Qur'an - Yoruba translation - Abu Rahima Mikael - Translations’ Index

Translated by Sh. Abu Rahima Mikael Ekoyini

close