Dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, àwọn dúkìá wọn àti àwọn ọmọ wọn kò níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ kiní kan lọ́dọ̀ Allāhu. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni n̄ǹkan ìkoná.
Ibẹ̀yẹn ni Zakariyyā ti pe Olúwa rẹ̀. Ó sọ pé: “Olúwa mi, ta mí ní ọrẹ àrọ́mọdọ́mọ dáadáa láti ọ̀dọ̀ Rẹ. Dájúdájú Ìwọ ni Olùgbọ́-àdúà.”
- Ibẹ̀yẹn ni Zakariyyā ti pe Olúwa rẹ̀. Ó sọ pé: "Olúwa mi, ta mí ní ọrẹ àrọ́mọdọ́mọ dáadáa láti ọ̀dọ̀ Rẹ. Dájúdájú Ìwọ ni Olùgbọ́ àdúà." -
(Zakariyyā) sọ pé: “Olúwa mi, báwo ni èmi yóò ṣe ní ọmọkùnrin; mo mà ti dàgbàlágbà, àgàn sì ni obìnrin mi?” Ó sọ pé: “Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣe ohun tí Ó bá fẹ́.”
Ìyẹn wà nínú ìró ìkọ̀kọ̀ tí À ń fi ìmísí rẹ̀ ránṣẹ́ sí ọ. Ìwọ kò kúkú sí lọ́dọ̀ wọn nígbà tí wọ́n ń ju gègé wọn (sínú odò láti mọ) ta ni nínú wọn ni ó máa gba Mọryam wò.[1] Ìwọ kò sì sí lọ́dọ̀ wọn nígbà tí wọ́n ń ṣe ìfàn̄fà (lórí rẹ̀).
1. Olúkùlùkù wọn kọ orúkọ rẹ̀ sára gègé rẹ̀. Wọ́n dá gègé wọn jọ, wọ́n dà wọ́n sínú odò. Odò gbé gbogbo gègé wọn lọ àfi gègé ti Zakariyā’ - kí ọlà Allāhu máa bá a -. Wọ́n sì gbé Mọryam fún Ànábì Zakariyā’ - kí ọlà Allāhu máa bá a - gẹ́gẹ́ bí alágbàwò rẹ̀.
(Mọryam) sọ pé: “Olúwa mi báwo ni èmi yó ṣe ní ọmọkùnrin, (nígbà tí) abara kan kò fọwọ́ kàn mí.” Ó sọ pé: Báyẹn ni Allāhu ṣe ń dá ohun tí Ó bá fẹ́. Nígbà tí Ó bá (gbèrò) láti dá ẹ̀dá kan ohun tí Ó máa sọ fún un ni pé: “Jẹ́ bẹ́ẹ̀.” Ó sì máa jẹ́ bẹ́ẹ̀.
Mo sì ń fi ohun tó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí tó ṣíwájú mi nínú at-Taorāh nítorí kí èmi lè ṣe apá kan èyí tí wọ́n ṣe ní èèwọ̀ fún yín ní ẹ̀tọ́ fún yín. Mo ti mú àmì kan wá fún yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.
Nígbà tí (Ànábì) ‘Īsā fura sí àìgbàgbọ́ lọ́dọ̀ wọn (pé wọ́n fẹ́ pa òun), ó sọ pé: “Ta ni olùrànlọ́wọ́ mi sí ọ̀dọ̀ Allāhu?” Àwọn ọmọlẹ́yìn (rẹ̀) sọ pé: “Àwa ni olùrànlọ́wọ́ fún (ẹ̀sìn) Allāhu. A gba Allāhu gbọ́. Kí o sì jẹ́rìí pé dájúdájú mùsùlùmí ni wá.
Ó ń bẹ nínú àwọn onítírà, ẹni tí ó jẹ́ pé tí o bá fi ọkàn tán an pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ owó, ó máa dá a padà fún ọ. Ó sì ń bẹ nínú wọn, ẹni tí ó jẹ́ pé tí o bá fi ọkàn tán an pẹ̀lú owó dinar kan (owó kékeré), kò níí dá a padà fún ọ àyàfi tí o bá dógò tì í lọ́rùn. Ìyẹn nítorí pé wọ́n wí pé: “Wọn kò lè fí ọ̀nà kan kan bá wa wí nítorí àwọn aláìmọ̀ọ́nkọmọ̀ọ́nkà.” Ńṣe ni wọ́n ń pa irọ́ mọ́ Allāhu, wọ́n sì mọ̀.
Ṣé ẹ̀sìn mìíràn yàtọ̀ sí ẹ̀sìn Allāhu ni wọ́n ń wá ni? Nígbà tí ó jẹ́ pé tiRẹ̀ ni gbogbo ẹni tí ń bẹ nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀ fún, wọ́n fẹ́ wọ́n kọ̀. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni Wọ́n máa dá wọn padà sí.
Sọ pé: “A gbàgbọ́ nínú Allāhu àti ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún wa àti ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, ’Ismọ̄‘īl, ’Ishāƙ, Ya‘ƙūb, àti àwọn àrọ́mọdọ́mọ (rẹ̀. A gbàgbọ́ nínú) ohun tí wọ́n fún (Ànábì) Mūsā àti ‘Īsā àti àwọn Ànábì láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn; A kò ya ẹnì kan kan sọ́tọ̀ nínú wọn. Àwa sì ni mùsùlùmí (olùjuwọ́-jusẹ̀-sílẹ̀) fún Un.”
Olùṣegbére ni wọ́n nínú ègún. Nítorí náà, A ò níí ṣe ìyà náà ní fífúyẹ́ fún wọn, A ò sì níí lọ́ wọn lára (láti jẹ̀yà nínú Iná).
Dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n sì kú nígbà tí wọ́n jẹ́ aláìgbàgbọ́, A ò níí gba ẹ̀kún ilẹ̀ wúrà lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni nínú wọn, ìbáà fi ṣèràpadà (fún ẹ̀mí ara rẹ̀ níbi Iná). Àwọn wọ̀nyẹn ni ìyà ẹlẹ́ta-eléro ń bẹ fún. Kò sì níí sí àwọn olùrànlọ́wọ́ fún wọn.
Báwo ni ẹ̀yin ṣe lè ṣàì gbàgbọ́, ẹ̀yin mà ni wọ́n ń ké àwọn āyah Allāhu fún, Òjíṣẹ́ Rẹ̀ sì wà láààrin yín! Ẹnikẹ́ni tí ó bá dúró ṣinṣin ti Allāhu, A ti tọ́ ọ sí ọ̀nà tààrà.[1]
1. “Òjíṣẹ́ Rẹ̀ sì wà láààrin yín!” Ìyẹn nígbà tí ó wà láyé láààrin àwọn Sọhābah rẹ̀ - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -.
Kí ó máa bẹ nínú yín, ìjọ kan tí yóò máa pèpè síbi ohun tó lóore, wọn yóò máa pàṣẹ ohun rere, wọn yó sì máa kọ ohun burúkú. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn sì ni olùjèrè.
Wọn kò níí kó ìnira ba yín àyàfi ìpalára díẹ̀. Tí wọ́n bá sì ba yín jà, wọ́n á sá fún yín. Lẹ́yìn náà, A ò níí ràn wọ́n lọ́wọ́.
Dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, àwọn dúkìá wọn àti àwọn ọmọ wọn kò níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ kiní kan (níbi ìyà) lọ́dọ̀ Allāhu. Àwọn wọ̀nyẹn sì ni èrò inú Iná. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀.
Àpèjúwe ohun tí wọ́n ń ná nínú ìṣẹ̀mí ayé yìí dà bí àpèjúwe afẹ́fẹ́ tí atẹ́gùn òtútù líle wà nínú rẹ̀. Ó fẹ́ lu oko àwọn ènìyàn tó ṣe àbòsí s’órí ara wọn. Ó sì pa á run. Allāhu kò sì ṣe àbòsí sí wọn, ṣùgbọ́n ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n ń ṣàbòsí sí.
Tí dáadáa kan bá kàn yín, ó máa kó ìbànújẹ́ bà wọn. Tí aburú kan bá sì ṣẹlẹ̀ sí yín, wọ́n máa dunnú sí i. Tí ẹ̀yin bá ṣe sùúrù, tí ẹ sì bẹ̀rù (Allāhu), ète wọn kò níí kó ìnira kan kan bá yín. Dájúdájú Allāhu ni Alámọ̀tán nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.́
Kò sí ohun tó kàn ọ́ nínú ọ̀rọ̀ náà. Yálà (Allāhu) máa gba ìronúpìwàdà wọn tàbí Ó máa jẹ wọ́n níyà; dájúdájú alábòsí ni wọ́n.[1]
1. Ẹ̀kọ́ tí āyah yìí fẹ́ kọ́ wa ni pé, mùsùlùmí kan kò gbọdọ̀ ro kèfèrí kan pin pé kó níí gba ’Islām títí ọjọ́ ikú rẹ̀. Ó ṣeé ṣe kí kèfèrí náà parí ìrìn-àjò ìṣẹ̀mí ayé rẹ̀ sínú ’Islām, tí Allāhu bá fẹ́ foríjìn ín. Ó sì ṣeé ṣe kí ó bá àìgbàgbọ́ rẹ̀ kú, tí Allāhu bá fẹ́ jẹ ẹ́ níyà.
Àwọn tí (ó jẹ́ pé) nígbà tí wọ́n bá ṣe ìbàjẹ́ kan tàbí tí wọ́n bá ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara wọn, wọ́n á rántí Allāhu, wọ́n á sì tọrọ àforíjìn fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn, - Ta sì ni Ó ń forí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ jin (ẹ̀dá) bí kò ṣe Allāhu. Wọn kò sì takú sórí ohun tí wọ́n ṣe nígbà tí wọ́n mọ̀ (pé ẹ̀ṣẹ̀ ni). -
Tí ìpalára kan bá kàn yín, irú ìpalára bẹ́ẹ̀ kúkú ti kan ìjọ (kèfèrí) náà. Àwọn ọjọ́ wọ̀nyí, À ń yí i po láààrin àwọn ènìyàn ni. Àti pé nítorí kí Allāhu lè ṣe àfihàn àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo àti (nítorí) kí Ó lè sọ àwọn kan nínú yín di òkú ojú-ogun (ní ojú-ọ̀nà Rẹ̀)[1]. Allāhu kò sì nífẹ̀ẹ́ àwọn alábòsí.
1. Àádọ́rin àwọn Sọhābah - kí Allāhu yọ́nú sí wọn - ló bá ogun yìí lọ. Mẹ́rin nínú wọn jẹ́ muhājirūn. Hamzah ọmọ ‘Abdul-Muttọlib wà nínú wọn. Àwọn yòókù jẹ́ ansọ̄r - kí Allāhu yọ́nú sí gbogbo wọn -.
Kò sì sí ohun kan tí wọ́n sọ tayọ pé wọ́n sọ pé: “Olúwa wa forí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa àti àṣejù wa nínú ọ̀rọ̀ (àwọn àṣìṣe) wa jìn wá, mú ẹsẹ̀ wa dúró ṣinṣin, kí O sì ṣe àrànṣe fún wa lórí ìjọ aláìgbàgbọ́.”
Pẹ̀lú ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu l’ó kúkú fi rọ̀ fún wọn; tí ó bá jẹ́ pé o jẹ́ ẹni burúkú, ọlọ́kàn líle, wọn ìbá ti túká kúrò lọ́dọ̀ rẹ. Ṣàmójú kúrò fún wọn, bá wọn tọrọ àforíjìn, kí o sì bá wọn jíròrò lórí ọ̀rọ̀. Tí o bá sì pinnu (ọ̀rọ̀ kan), kí o gbáralé Allāhu. Dájúdájú Allāhu nífẹ̀ẹ́ àwọn olùgbáralé E.
Kò lẹ́tọ̀ọ́ fún Ànábì kan láti jí mú nínú ọrọ̀ ogun ṣíwájú kí wọ́n tó pín in. Ẹnikẹ́ní tí ó bá mú nínú ọrọ̀ ogun lọ́nà ìjàǹbá ṣíwájú kí wọ́n tó pín in, ó máa dá ohun tí ó jí mú nínú ọrọ̀ ogun náà padà ní Ọjọ́ Àjíǹde. Lẹ́yìn náà, A óò san ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀san ohun tí ó ṣe níṣẹ́ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. A ò sì níí ṣe àbòsí sí wọn.
Ṣé gbogbo ìgbà tí àdánwò kan bá kàn yín, tí ẹ sì ti fi méjì irú rẹ̀ (kan àwọn kèfèrí), ni ẹ̀yin yóò máa sọ pé: “Ọ̀nà wo ni èyí gbà ṣẹlẹ̀ sí wa?” Sọ pé: “Ó wá láti ọ̀dọ̀ ara yín.” Dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
Ẹ má ṣe lérò pé òkú (ìyà) ni àwọn tí wọ́n pa sí ojú-ọ̀nà Allāhu, bí kò ṣe pé alààyè (ẹni ìkẹ́) ni wọ́n. Wọ́n sì ń pèsè ìjẹ-ìmu fún wọn lọ́dọ̀ Olúwa wọn.[1]
Kí àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ má ṣe lérò pé bí A ṣe ń lọ́ra fún wọn jẹ́ oore fún wọn. A kàn ń lọ́ra fún wọn nítorí kí wọ́n lè lékún nínú ẹ̀ṣẹ̀ ni. Ìyà tí í yẹpẹrẹ ẹ̀dá sì wà fún wọn.
Kí àwọn tó ń ṣahun pẹ̀lú ohun tí Allāhu fún wọn nínú oore-àjùlọ Rẹ̀ má ṣe lérò pé oore ni fún wọn, bí kò ṣe pé aburú ni fún wọn. A ó fí ohun tí wọ́n fi ṣahun kọ́ wọn lọ́rùn ní Ọjọ́ Àjíǹde. Ti Allāhu sì ni ogún àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Allāhu sì ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Allāhu kúkú ti gbọ́ ọ̀rọ̀ àwọn tó wí pé: “Dájúdájú aláìní ni Allāhu, àwa sì ni ọlọ́rọ̀.” A máa ṣàkọsílẹ̀ ohun tí wọ́n wí àti pípa tí wọ́n pa àwọn Ànábì láì lẹ́tọ̀ọ́. A sì máa sọ pé: “Ẹ tọ́ ìyà Iná jónijóni wò.”
Àwọn tó wí pé: “Dájúdájú Allāhu ṣàdéhùn fún wa pé a ò gbọdọ̀ gba Òjíṣẹ́ kan gbọ́ títí ó máa fí mú ẹran sàráà kan wá fún wa tí iná (àtọ̀runwá) yóò fi lánu.” Sọ pé: “Dájúdájú àwọn Òjíṣẹ́ kan ti wá ba yín ṣíwájú mi pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí to yanjú àti èyí tí ẹ wí (yìí), nítorí kí ni ẹ fi pa wọ́n tí ẹ bá jẹ́ olódodo?”
Olúwa wa, dájúdájú àwa gbọ́ olùpèpè kan tó ń pe (ìpè) sí ibi ìgbàgbọ́ pé: “Ẹ gba Olúwa yín gbọ́.” A sì gbàgbọ́ ní òdodo. Olúwa wa, nítorí náà, forí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jìn wá, kí O sì pa àwọn àṣìṣe wa rẹ́, kí O sì pa wá pẹ̀lú àwọn ẹni rere.
Contents of the translations can be downloaded and re-published, with the following terms and conditions:
1. No modification, addition, or deletion of the content.
2. Clearly referring to the publisher and the source (QuranEnc.com).
3. Mentioning the version number when re-publishing the translation.
4. Keeping the transcript information inside the document.
5. Notifying the source (QuranEnc.com) of any note on the translation.
6. Updating the translation according to the latest version issued from the source (QuranEnc.com).
7. Inappropriate advertisements must not be included when displaying translations of the meanings of the Noble Quran.
نتایج جستجو:
API specs
Endpoints:
Sura translation
GET / https://quranenc.com/api/v1/translation/sura/{translation_key}/{sura_number} description: get the specified translation (by its translation_key) for the speicified sura (by its number)
Parameters: translation_key: (the key of the currently selected translation) sura_number: [1-114] (Sura number in the mosshaf which should be between 1 and 114)
Returns:
json object containing array of objects, each object contains the "sura", "aya", "translation" and "footnotes".
GET / https://quranenc.com/api/v1/translation/aya/{translation_key}/{sura_number}/{aya_number} description: get the specified translation (by its translation_key) for the speicified aya (by its number sura_number and aya_number)
Parameters: translation_key: (the key of the currently selected translation) sura_number: [1-114] (Sura number in the mosshaf which should be between 1 and 114) aya_number: [1-...] (Aya number in the sura)
Returns:
json object containing the "sura", "aya", "translation" and "footnotes".