Firo maanaaji al-quraan tedduɗo oo - Firo yurbawiiwo * - Tippudi firooji ɗii

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Firo maanaaji Aaya: (29) Simoore: Simoo tuubabuya
قَٰتِلُواْ ٱلَّذِينَ لَا يُؤۡمِنُونَ بِٱللَّهِ وَلَا بِٱلۡيَوۡمِ ٱلۡأٓخِرِ وَلَا يُحَرِّمُونَ مَا حَرَّمَ ٱللَّهُ وَرَسُولُهُۥ وَلَا يَدِينُونَ دِينَ ٱلۡحَقِّ مِنَ ٱلَّذِينَ أُوتُواْ ٱلۡكِتَٰبَ حَتَّىٰ يُعۡطُواْ ٱلۡجِزۡيَةَ عَن يَدٖ وَهُمۡ صَٰغِرُونَ
Ẹ gbógun ti àwọn tí kò gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn àti àwọn tí kò ṣe ní èèwọ̀ ohun tí Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ṣe ní èèwọ̀¹ àti àwọn tí kò ṣe ẹ̀sìn òdodo nínú àwọn tí A fún ní tírà. (Ẹ gbógun tì wọ́n) títí wọ́n yóò fi máa fi ọwọ́ ará wọn san owó-orí ní ẹni yẹpẹrẹ.
1. Awẹ́ gbólóhùn yìí “ ohun tí Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ṣe ní èèwọ̀” ti fi hàn pé, al-Ƙur'ān àti hadīth Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -, ìkíní kejì ló lè ṣe n̄ǹkan kan ní èèwọ̀ fún mùsùlùmí. Nítorí náà, èèwọ̀ ni ohunkóhun tí hadīth Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - tó fẹsẹ̀ rinlẹ̀ bá ṣe ní èèwọ̀, ìbáà má sìí nínú al-Ƙur'ān alápọ̀n-ọ́nlé. Bí àpẹ̀erẹ, èèwọ̀ ni fún obìnrin láti fi irun kún irun, èèwọ̀ sì ni fún obìnrin láti ṣe irun tí ó máa yọké. Irun tó yọké ni irun tí ó yọ ìkúùkù lórí obìnrin. Nínú hadīth Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ni ìwọ̀nyẹn wà.
Faccirooji aarabeeji:
 
Firo maanaaji Aaya: (29) Simoore: Simoo tuubabuya
Tippudi cimooje Tonngoode hello ngoo
 
Firo maanaaji al-quraan tedduɗo oo - Firo yurbawiiwo - Tippudi firooji ɗii

Firo maanaaji al-quraan tedduɗo oo e ɗemngal yurba, firi ɗum ko mawɗo Abuu Rahiima Miikaa'iil aykuuniy. Muulngo hitaande 1432fergo

Uddude