Traduction des sens du Noble Coran - Traduction en yorouba * - Lexique des traductions

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Traduction des sens Verset: (90) Sourate: YOUNOUS
۞ وَجَٰوَزۡنَا بِبَنِيٓ إِسۡرَٰٓءِيلَ ٱلۡبَحۡرَ فَأَتۡبَعَهُمۡ فِرۡعَوۡنُ وَجُنُودُهُۥ بَغۡيٗا وَعَدۡوًاۖ حَتَّىٰٓ إِذَآ أَدۡرَكَهُ ٱلۡغَرَقُ قَالَ ءَامَنتُ أَنَّهُۥ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا ٱلَّذِيٓ ءَامَنَتۡ بِهِۦ بَنُوٓاْ إِسۡرَٰٓءِيلَ وَأَنَا۠ مِنَ ٱلۡمُسۡلِمِينَ
A mú àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl la agbami òkun já. Fir‘aon àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì gbá tọ̀ wọ́n lẹ́yìn, ní ti ìlara àti ìtayọ ẹnu-ààlà, títí ìtẹ̀rì sínú agbami òkun fi bá a. Ó sì wí pé: “Mo gbàgbọ́ pé dájúdájú kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Ẹni tí àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl gbàgbọ́. Mo sì wà nínú àwọn mùsùlùmí.”¹
1. Àkíyèsí mẹ́ta ló wà nínú gbólóhùn tí Fir‘aon sọ yìí. Ìkíní: Fir‘aon sọ pé, “Mo gbàgbọ́ pé dájúdájú kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Ẹni tí àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl gbàgbọ́.”, dípò kí Fir‘aon sọ pé, “Mo gbàgbọ́ pé dájúdájú kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Allāhu.” Ìgbéraga rẹ̀ ló mú “àfi Allāhu.”wúwo lẹ́nu rẹ̀, tí ó fi wí pé “àfi Ẹni tí àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl gbàgbọ́.”
Ìkéjì: Nínú ẹ̀gbàwá Imām ’Ahmọd, nínú hadīth mọrfū‘ Sa‘īd bun Jubaer àti Ibn ‘Abbās - kí Allāhu yọ́nú sí wọn -, Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - sọ pé: “Dájúdájú Jibrīl - kí ọlà Allāhu máa bá a - ń rọ́ erùpẹ̀ sí ẹnu Fir‘aon ní ti ìpáyà pé kí ó má sọ pé, “kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Allāhu.”. Èyí fi hàn pé, Fir‘aon kò rí kalmọh wí bí ó ṣe yẹ kí ó wí i. Wọ́n ní kí ó sọ́ tó, ó ní òun kò lè sọ tótòtòó. Dípò kí ó sọ pé, “kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Allāhu.”, ó wí pé, “kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Ẹni tí àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl gbàgbọ́.” Ṣé Ọlọ́hun tí àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl gbàgbọ́ kò lórúkọ ni?
Ìkẹta: Ẹ̀sìn ’Islām ni ẹ̀sìn àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl lójú ayé Ànábì Mūsā - kí ọlà Allāhu máa bá a -. Mùsùlùmí sì ni wọ́n. Èyí ló hàn sí Fir‘aon l’òun náà fi sọ pé, “Mo sì wà nínú àwọn mùsùlùmí.” Àmọ́ lẹ́yìn ikú Ànábì Mūsā - kí ọlà Allāhu máa bá a -, àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl pa ẹ̀sìn ’Islām tì pátápátá, wọ́n sì gbé ẹ̀sìn mìíràn kalẹ̀ fúnra wọn. Orúkọ ẹ̀sìn àdádáálẹ̀ wọn sì ni Yẹhūdiyyah. Irú àdánwò yìí kan náà ló ṣẹlẹ̀ sí ìjọ Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - lẹ́yìn tí Allāhu gbé e gun sánmọ̀ lọ láàyè. Ìjọ tirẹ̀ náà pa ẹ̀sìn ’Islām tì pátápátá, wọ́n sì gbé ẹ̀sìn mìíràn kalẹ̀ fúnra wọn. Orúkọ ẹ̀sìn àdádáálẹ̀ wọn sì ni Nasrọ̄niyyah. Ẹ tún wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Baƙọrah; 2:62.
Les exégèses en arabe:
 
Traduction des sens Verset: (90) Sourate: YOUNOUS
Lexique des sourates Numéro de la page
 
Traduction des sens du Noble Coran - Traduction en yorouba - Lexique des traductions

Traduction des sens du Noble Coran en langue yorouba par Cheikh Abû Rahimah Mikhaïl Aikweiny et publiée en l'an 1432 de l'Hégire.

Fermeture