Traduction des sens du Noble Coran - Traduction en yorouba * - Lexique des traductions

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Traduction des sens Verset: (108) Sourate: HOUD
۞ وَأَمَّا ٱلَّذِينَ سُعِدُواْ فَفِي ٱلۡجَنَّةِ خَٰلِدِينَ فِيهَا مَا دَامَتِ ٱلسَّمَٰوَٰتُ وَٱلۡأَرۡضُ إِلَّا مَا شَآءَ رَبُّكَۖ عَطَآءً غَيۡرَ مَجۡذُوذٖ
Ní ti àwọn tí A bá ṣe ní olórí-ire, wọ́n máa wà nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ ní òdíwọ̀n ìgbà tí àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ fi ń bẹ¹, àfi ohun tí Olúwa rẹ bá fẹ́.² (Ọgbà Ìdẹ̀ra jẹ́) ọrẹ àìlópin.
1. Bíbẹ nínú Iná àti bíbẹ nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra ní òdiwọ̀n ìgbà tí àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ fi ń bẹ kò túmọ̀ sí pé òpin yóò dé bá Iná àti Ọgbà Ìdẹ̀ra gẹ́gẹ́ bí òpin yóò ṣe dé bá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ṣùgbọ́n ọ̀nà ìbátan níbi àfiwé tí ń bẹ láààrin àwọn méjéèjì ni pé, ó jẹ́ ara ẹwà èdè láti ṣe àfihàn ìgbà pípẹ́ fún n̄ǹkan. Lára irúfẹ èyí náà ni, bí àpẹ̀ẹrẹ, kí ọkùnrin kan sọ pé, “Èmi yóò máa jẹ́ ọkúnrin ní òdiwọ̀n ìgbà tí ilẹ̀ bá ń ṣú, tí ilẹ̀ bá ń mọ́.”
Ṣíwájú sí i, ìgbàgbọ́ àwa mùsùlùmí ahlu-sunnah wal-janmọ̄n‘ah ni pé, kò sí òpin ìgbà fún Iná àti Ọgbà Ìdẹ̀ra ní ọ̀run. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, àwọn kan lè kọ́kọ́ wọ inú Iná ṣíwájú kí Allāhu - tó ga jùlọ - tó padà mú wọn jáde kúrò nínú rẹ̀ pẹ̀lú àánú Rẹ̀ tàbí pẹ̀lú ìṣìpẹ̀ Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -. Lẹ́yìn náà, ó máa ṣẹ́ ku kìkìdá àwọn ọmọ Iná Gbére, wọn yó sì ṣe gbére nínú Iná.
Ní ìdà kejì ẹ̀wẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ó bá wọ Ọgbà Ìdẹ̀ra, ó máa ṣe gbére nínú rẹ̀ ni. Kò sì níí sí ẹnì kan tí ó máa ti inú Ọgbà Ìdẹ̀ra bọ́ sínú Iná Gbére.
Ẹ̀rí nínú sunnah Ànábì wa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -, tí á tún lè fi ní àgbọ́yé àwọn āyah wọ̀nyí dáradára ni hadīth Abu-Sa‘īd al-Kudri - kí Allāhu yọ́nú sí i -. Ó sọ pé, Òjíṣẹ́ Allāhu - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - sọ pé: “Ní Ọjọ́ Àjíǹde, wọn yóò mú Ikú wá ní ìrísí àgbò funfun, tí ó ní dúdú lára. Olùpèpè kan yó sì pèpè báyìí pé, “Ẹ̀yin ará Ọgbà Ìdẹ̀ra”. Àwọn ará Ọgbà Ìdẹ̀ra yó sì narùn jáde síta, wọn yóò wo (ìta). Olùpèpè yó sì sọ pé: “Ǹjẹ́ ẹ̀yin mọ èyí?” Wọn yóò sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, èyí ni Ikú.” Ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn sì máa rí i. Lẹ́yìn náà, olùpèpè máa pèpè báyìí pé, “Ẹ̀yin ará Iná”. Àwọn ará Iná yó sì narùn jáde síta, wọn yóò wo (ìta). Olùpèpè yó sì sọ pé: “Ǹjẹ́ ẹ̀yin mọ èyí?” Wọn yóò wí pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, èyí ni Ikú.” Ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn sì máa rí i. Nígbà náà, A óò pa Ikú. Lẹ́yìn náà, olùpèpè kan yóò sọ pé: “Ẹ̀yin ará Ọgbà Ìdẹ̀ra, gbére (ni tiyín báyìí nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra), kò sì sí Ikú mọ́. Olùpèpè yóò tún sọ pé: “Ẹ̀yin ará Iná, gbére (ni tiyín báyìí nínú Iná), kò sì sí Ikú mọ́.” Al-Bukāriy; Kitāb at-Tafsīr.
2. Awẹ́ gbólóhùn yìí “àfi ohun tí Olúwa rẹ bá fẹ́”, àgbọ́yé rẹ̀ ni pípẹ́ tí àwọn kan yóò pẹ́ kí wọ́n tó wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Ó kúkú ti hàn kedere pé àwọn kan yóò ṣíwájú àwọn mìíràn wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra látára bí ìrìn-àjò ẹ̀dá bá ṣe rí lórí afárá Iná.
Bákàn náà, àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kan yóò kọ́kọ́ wọ inú Iná ṣíwájú kí wọ́n tó wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Àti pé àwọn kan wulẹ̀ ti wà nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra ṣíwájú Ọjọ́ Àjíǹde ẹ̀dá. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí wọ́n kú sí ipò ṣẹhīd, gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe mú hadīth wá lórí èyí nínú ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Baƙọrah; 2:154.
Nítorí náà, nípa ti èrò Ọgbà Ìdẹ̀ra, “àfi ohun tí Olúwa rẹ bá fẹ́” túmọ̀ sí “àfi pípẹ́ tí Olúwa rẹ bá fẹ́ fún àwọn kan láti pẹ́ wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra.” Nígbà tí gbogbo wọn bá sì péjú pésẹ̀ tán sínú rẹ̀, wọn yó sì máa wà nínú rẹ̀ títí láéláé. Èyí yóò rí bẹ́ẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n bá pa Ikú. Kí Allāhu jẹ́ kí á tètè wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra.
Ní ìsọníṣókí, ìyàtọ̀ wà nínú àgbọ́yé “àfi ohun tí Olúwa rẹ bá fẹ́” nípa ti èrò Iná àti “àfi ohun tí Olúwa rẹ bá fẹ́” nípa ti èrò Ọgbà Ìdẹ̀ra. Àmọ́ àgbọ́yé àwọn méjèèjì kò jẹmọ́ pé òpin máa dé bá Iná àti Ọgbà Ìdẹ̀ra. Ọgbà gbére ni méjèèjì. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah as-Sajdah; 32:20.
Les exégèses en arabe:
 
Traduction des sens Verset: (108) Sourate: HOUD
Lexique des sourates Numéro de la page
 
Traduction des sens du Noble Coran - Traduction en yorouba - Lexique des traductions

Traduction des sens du Noble Coran en langue yorouba par Cheikh Abû Rahimah Mikhaïl Aikweiny et publiée en l'an 1432 de l'Hégire.

Fermeture