Traduction des sens du Noble Coran - Traduction en yorouba * - Lexique des traductions

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Traduction des sens Verset: (76) Sourate: AN-NAHL
وَضَرَبَ ٱللَّهُ مَثَلٗا رَّجُلَيۡنِ أَحَدُهُمَآ أَبۡكَمُ لَا يَقۡدِرُ عَلَىٰ شَيۡءٖ وَهُوَ كَلٌّ عَلَىٰ مَوۡلَىٰهُ أَيۡنَمَا يُوَجِّههُّ لَا يَأۡتِ بِخَيۡرٍ هَلۡ يَسۡتَوِي هُوَ وَمَن يَأۡمُرُ بِٱلۡعَدۡلِ وَهُوَ عَلَىٰ صِرَٰطٖ مُّسۡتَقِيمٖ
Allāhu tún fi àkàwé kan lélẹ̀ (nípa) ọkùnrin méjì kan, tí ọ̀kan nínú wọn jẹ́ odi, tí kò lè dá n̄ǹkan kan ṣe, tí ó tún jẹ́ wàhálà fún ọ̀gá rẹ̀ (nítorí pé) ibikíbi tí ó bá rán an lọ, kò níí mú oore kan bọ̀ (fún un láti ibẹ̀). Ṣé ó dọ́gba pẹ̀lú ẹni tí Ó ń pàṣẹ ṣíṣe ẹ̀tọ́, tí ó sì wà lójú ọ̀nà tààrà?¹
1. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èèwọ̀ ẹ̀sìn ni fún ẹ̀dá láti fi àkàwé àti àfijọ lélẹ̀ fún Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú āyah 74, Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - lè fi àkàwé ara Rẹ̀ lélẹ̀ fún ẹ̀dá nítorí kí ẹ̀dá lè mọ̀ pé Allāhu tóbi jùlọ. Nítorí náà, kíkó ara ẹni sínú wàhálà tí kò lẹ́tọ̀ọ́ ni sísọ ẹ̀dá kan di akẹgbẹ́ fún Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - nítorí pé, kò sí nínú wọn tí ó lè gbọ́ ìpè, áḿbọ̀sìbọ́sí pé wọn yóò jẹ́ ìpè. Báwo ni oore kan ṣe fẹ́ ti ọ̀dọ̀ wọn wá? Àwọn tó ń pè wọ́n kò sì yé wàhálà ẹ̀mí ara wọn lórí ìpè asán? Àmọ́, Allāhu, Ẹni tí Ó ń gbọ́ ìpè ẹ̀dá, Ẹni tí Ó ń jẹ́ ìpè ẹ̀dá, Òun ni a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo. Ó sì ti pa wá ní àṣẹ láti jọ́sìn fún Un. Àṣẹ náà ni àṣẹ òdodo.
Les exégèses en arabe:
 
Traduction des sens Verset: (76) Sourate: AN-NAHL
Lexique des sourates Numéro de la page
 
Traduction des sens du Noble Coran - Traduction en yorouba - Lexique des traductions

Traduction des sens du Noble Coran en langue yorouba par Cheikh Abû Rahimah Mikhaïl Aikweiny et publiée en l'an 1432 de l'Hégire.

Fermeture