Traduction des sens du Noble Coran - Traduction en yorouba * - Lexique des traductions

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Traduction des sens Verset: (72) Sourate: MARIAM
ثُمَّ نُنَجِّي ٱلَّذِينَ ٱتَّقَواْ وَّنَذَرُ ٱلظَّٰلِمِينَ فِيهَا جِثِيّٗا
Lẹ́yìn náà, A máa gba àwọn tó bẹ̀rù (Allāhu) là. A sì máa fi àwọn alábósì sílẹ̀ sínú Iná lórí ìkúnlẹ̀.¹
1. Ìgbàkígbà tí Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - bá lo ọ̀rọ̀ arọ́pò-orúkọ “ọ̀pọ̀” bíi “A” tàbí ọ̀rọ̀ arọ́pò afarajorúkọ bíi “Àwa” fún Ara Rẹ̀, yàtọ̀ sí pé ó jẹ́ àpọ́nlé fún Un, kì í ṣe pé Ẹni tó ń jẹ́ “Allāhu” pé méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ọ̀rọ̀ arọ́pò-orúkọ tàbí ọ̀rọ̀ arọ́pò afarajorúkọ “ọ̀pọ̀” náà ń dúró fún iṣẹ́ kan nínú àwọn iṣẹ́ tí Allāhu máa ń dá ṣe pẹ̀lú gbólóhùn “Jẹ́ bẹ́ẹ̀, kí ó sì jẹ́ bẹ́ẹ̀” tàbí iṣẹ́ kan nínú àwọn iṣẹ́ tí Allāhu máa yan àwọn mọlāika Rẹ̀ láti ṣe. Ní ti āyah 68 àti 69, àwọn mọlāika ni Allāhu máa pàṣẹ iṣẹ́ wọ̀nyẹn fún lọ́jọ́ Àjíǹde. Àwọn mọlāika náà sì ni ẹ̀ṣọ́ Iná. Èyí wà ní ìbámu sí sūrah at-Tahrim; 66:6 àti sūrah al-Mudaththir; 74:30-31.
Bákan náà, kalmọh “wārid” tó jẹyọ nínú āyah 71 jẹ́ ọ̀rọ̀-orúkọ tí wọ́n ṣẹ̀dá láti ara ọ̀rọ̀-ìṣe “warada”. Nínú al-Ƙur’ān, a lè rí ìtúmọ̀ méjì tó súnmọ́ ara wọn, àmọ́ tó tún ń dúró fún ọ̀rọ̀ àti ìdàkejì rẹ̀ fún “warada”. “Warada” túmọ̀ sí “ó dé sí ibi tí kiní kan wà, ó sì wọ inú n̄ǹkan náà”, gẹ́gẹ́ bí ìtúmọ̀ yìí ṣe wà nínú sūrah Hūd; 11:98 àti sūrah al-’Anbiyā’; 21:98-100. “Warada” tún túmọ̀ sí “ó dé sí ibi tí kiní kan wà, àmọ́ kò wọ inú n̄ǹkan náà”, gẹ́gẹ́ bí ìtúmọ̀ yìí ṣe wà nínú sūrah al-Ƙọsọs; 28:23.
Ìtúmọ̀ méjèèjì wọ̀nyí ti fi hàn kedere pé kò sí ẹ̀dá tí kò níí dé ibi tí Iná wà lọ́jọ́ Àjíǹde. Àmọ́ àwọn kan máa “débẹ̀ wọbẹ̀”, àwọn kan sì máa “débẹ̀ láì wọbẹ̀”. Ìdí tí gbogbo ẹ̀dá máa fi dé ibi tí Iná wà ni pé, ojú ọ̀nà tí a máa tọ̀ dé ibi tí Ọgbà Ìdẹ̀ra wà ni Iná wà. Ìsàlẹ̀ lọ́wọ́ iwájú Ọgbà Ìdẹ̀ra ni Allāhu fi àyè Iná sí. Kódà, ọ̀nà tí a máa tọ̀ wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra sì jẹ́ afárá tín-ínrín yíyọ̀ lórí Iná. Igun mẹ́ta sì ni àwọn ènìyàn àti àlùjọ̀nnú máa pín sí lórí ìrìn wọn lórí afárá Iná.
Igun kìíní ni àwọn Ànábì, àwọn Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun - kí ìkẹ́ Allāhu máa bá wọn - àti àwọn kan nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo, tó máa rìn lórí afárá Iná láì níí jábọ́ sínú Iná títí wọ́n fi máa gúnlẹ̀ sínú ilé ìgbàlà wọn, Ọgbà Ìdẹ̀ra. - Kí Allāhu fi àánú Rẹ̀ ta wá lọ́rẹ àrìnyè náà. - Igun yìí ni Allāhu ti ṣe àforíjìn fún pátápátá lórí àṣìṣe wọn. Ṣebí kò sí bí a ó ṣe rìn tí orí wa kò níí mì lọ̀rọ̀ ẹ̀dá nílé ayé. Allāhu sì ni Aláforíjìn ẹ̀dá. Igun kìíní yìí ni Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - ń sọ nípa wọn nínú sūrah al-’Anbiyā’; 21:101-102 àti sūrah az-Zumọr; 39:61.
Igun kejì ni àwọn kan nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo, tó máa rìn lórí afárá Iná ní àrìnjábọ́ sínú Iná. Igun yìí ni wọ́n ní àwọn àṣìṣe kan lọ́rùn, àmọ́ tí Allāhu kò forí rẹ̀ jìn wọ́n. Sebí Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - kúkú ti sọ pé kí ẹni tí ó bá ń dá ẹ̀ṣẹ̀, tí kò tọrọ àforíjìn tàbí ronú pìwàdà lórí rẹ̀ títí ó fi kú má ṣe fọkàn balẹ̀ pé Òun kúkú máa forí rẹ̀ jìn ín. Tí Allāhu bá fẹ́, Ó máa forí rẹ̀ jìn ín. Tí Ó bá sì fẹ́, Ó máa fìyà ẹṣẹ̀ rẹ̀ jẹ ẹ́. Èyí wà ní ìbámu sí sūrah an-Nisā’; 4:116. Igun kejì yìí ló máa padà jáde kúrò nínú Iná lásìkò tí Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - bá fẹ́, yálà nípasẹ̀ ìṣìpẹ̀ Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - tàbí nípasẹ̀ àánú àti ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu - subhānahu wa ta’ālā -.
Igun kẹta ni igun gbogbo ẹni tí ó kú sórí àìgbàgbọ́ tàbí ìṣẹbọ tàbí ìṣojúméjì pẹ̀lú Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā -. Igun kẹta yìí náà máa rìn lórí afárá Iná ní àrìnjábọ́, àmọ́ wọn kò níí jáde kúrò nínú rẹ̀ títí láéláé nítorí pé, Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - kò níí ṣíjú àánú wò wọ́n rárá.
Nítorí náà, tí ẹnì kan bá sọ pé kò níí sí igun kan kan tí Iná kò níí jó nítorí gbólóhùn “wa ’in minkum ’illā wāriduhā”, ẹni náà ti sọ̀rọ̀ àìmọ̀kan tó gbópọn lẹnu nítorí pé, ó ti fi ìtúmọ̀ “warada” mọ sórí “ó débẹ̀ wọbẹ̀” nìkan, ó sì kọ̀yìn sí ìtúmọ̀ “warada” tó túmọ̀ sí “ó débẹ̀ kò wọbẹ̀”.
Bẹ́ẹ̀ náà ni ẹni tí ó bá sọ pé kò sí igun kan kan tí ó máa padà jáde kúrò nínú Iná. Kò sí ẹni tí ó máa sọ bẹ́ẹ̀ bí kò ṣe aláìgbàgbọ́ nínú ọ̀rọ̀ Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -. Bákan náà, tí ẹnì kan bá sọ pé kò níí sí igun kan kan tí ó máa wà nínú Iná gbére, irú ẹni náà ti sọ ọ̀rọ̀ tí ó lòdì sí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ āyah tó ń fi Iná gbere rinlẹ̀ fún àwọn aláìgbàgbọ́. Irú ẹni náà súnmọ́ kó jẹ́ ẹlẹ́sìn Ahmadiyyah.
Lẹ́yìn náà, yálà igun tí ó máa rin àrìnyè lórí afárá Iná tàbí igun tí ó máa rin àrìnjábọ́ sínú Inȧ, igun kìíní kejì máa wá lábẹ́ àkórìn àwọn mọlāika kan ni. Ìyẹn ni pé, àwọn mọlāika kan ló máa kó gbogbo ẹ̀dá lọ sórí afárá Iná nítorí pé, kò sí ẹ̀dá kan tó máa fẹ́ fínnú fíndọ̀ gba orí afárá Iná kọjá. Dándan sì ni fún gbogbo wọn láti gba orí rẹ̀ kọjá bọ́ sí àyè wọn. Àwọn mọlāika wọ̀nyẹn ni àwọn mọlāika agbèrò Ọgbà Ìdẹ̀ra àti àwọn mọlāika agbèrò Iná. Èyí ni Allāhu - subhānahu wa ta’ālā - tún fi rinlẹ̀ nínú sūrah az-Zumọr; 39:71-73.
Les exégèses en arabe:
 
Traduction des sens Verset: (72) Sourate: MARIAM
Lexique des sourates Numéro de la page
 
Traduction des sens du Noble Coran - Traduction en yorouba - Lexique des traductions

Traduction des sens du Noble Coran en langue yorouba par Cheikh Abû Rahimah Mikhaïl Aikweiny et publiée en l'an 1432 de l'Hégire.

Fermeture