Traduction des sens du Noble Coran - Traduction en yorouba * - Lexique des traductions

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Traduction des sens Verset: (8) Sourate: AL-ANBIYÂ’
وَمَا جَعَلۡنَٰهُمۡ جَسَدٗا لَّا يَأۡكُلُونَ ٱلطَّعَامَ وَمَا كَانُواْ خَٰلِدِينَ
A kò sì ṣe wọ́n ní abara tí kì í jẹun. Wọn kò sì jẹ́ olùṣegbére (nílé ayé).¹
1. Àwọn tó gbàgbọ́ pé Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - ti kú sọ pé, “Āyah yìí àti āyah 34 níwájú tako àì tí ì kú Ànábì ‘Īsā títí di àkókò yìí àti títí di àkókò òpin ayé. Nítorí náà, Ànábì ‘Īsā - kí ọlà Allāhu máa bá a - ti kú”.
Èsì: Kíyè sí i! Gbígbé tí Allāhu gbé Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - lọ sínú sánmọ̀ kò túmọ̀ sí pé Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - kò níí kú. Rárá o, ó máa kú lẹ́yìn ìgbà tí Allāhu - tó ga jùlọ - bá sọ̀ ọ́ kalẹ̀ láti ojú sánmọ̀ nítorí pé, abara ni, kì í ṣe ọlọ́hun. Allāhu, Ọlọ́hun nìkan ni kò níí kú láéláé. Yàtọ̀ sí āyah “ƙọbla maotih” nínú sūrah an-Nisā’; 4:159, àwọn hadīth Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ti fi rinlẹ̀ pé, ikú Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - di ẹ̀yìn ìgbà tí ó bá tó sọ̀kalẹ̀ láti ojú sánmọ̀, ìyẹn ní òpin ayé. Ohun tí ó kàn jẹ́ ìṣòro fún àwọn tí wọ́n gbàgbọ́ pé Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - ti kú ṣíwájú àsìkò yìí ni pé, bí wọ́n bá sọ pé kò sí āyah tààrà kan lórí àìtíìkú rẹ̀ àti ìsọ̀kalẹ̀ rẹ̀ láti ojú sánmọ̀ lópin ayé, kò sí ìmọ̀ tó yè kooro fún wọn lórí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa àwọn hadīth Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -. Nítorí pé, tí ó bá jẹ́ pé wọ́n ní ẹ̀kọ́ tó yè kooro lórí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa àwọn hadīth Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -, wọn ìbá mọ̀ pé dájúdájú hadīth Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ní òmìnira láti sọ ọ̀rọ̀ tí kò sí nínú al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé. Ní òdíwọ̀n ìgbà tí hadīth bẹ́ẹ̀ bá sì ti fẹsẹ̀ rinlẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa hadīth, ẹnu aláìmọ̀kan tàbí aláààbọ̀ ẹ̀kọ́ kan kan kò gbà á láti tako irúfẹ́ àwọn hadīth náà. Bí ó bá dán an wò pẹ̀rẹ̀, ìgbàgbọ́ rẹ̀ nínú al-Ƙur’ān àti ìgbàgbọ́ rẹ̀ nínú Ànábì wa Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ti bàjẹ́ mọ́ ọn lọ́wọ́. Èyí wà ní ìbámu sí sūrah an-Nisā’; 4: 115.
Bí àpẹ̀ẹrẹ, al-Ƙur’ān fi rinlẹ̀ pé, àwọn òkú kò lè gbọ́ ọ̀rọ̀ kan kan mọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn alààyè ní ìbámu sí sūrah an-Naml; 27:80, sūrah ar-Rūm; 30:52 àti sūrah Fātir; 35:22. Ànábì wa Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - sì padà di òkú tí wọ́n bò mọ́ inú sàréè nínú ìlú Mọdīnah Onímọ̀ọ́lẹ̀ ní ìbámu sí sūrah az-Zumọr; 39:30. Kò sì sí āyah tààrà kan nínú al-Ƙur’ān tí ó yọ Ànábì wa Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - sílẹ̀ nínú àwọn òkú tí kò lè gbọ́ ọ̀rọ̀ kan kan mọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn alààyè. Àmọ́ hadīth tó fẹsẹ̀ rinlẹ̀ wà tí ó ń fi rinlẹ̀ pé, Ànábì wa Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - máa ń dá sálámọ̀ padà fún ẹnikẹ́ni tí ó bá sálámọ̀ sí i nídìí sàréè rẹ̀. Kódà hadīth tó fẹsẹ̀ rinlẹ̀ tún wà tí ó ń fi rinlẹ̀ pé, ní gbogbo ọjọ́ Jímọ̀, àwọn mọlāika ń gbé ìtọrọ-ìkẹ́ àti ìtọrọ-ìbùkún fún Ànábì wa Muhammad sí etí ìgbọ́ rẹ̀ nínú sàréè rẹ̀ láti ibikíbi nílé ayé tí wọ́n bá ti ń tọrọ rẹ̀ fún un - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -.
Hadīth kìíní: Láti ọ̀dọ̀ Abū Huraerah - kí Allāhu yọ́nú sí i -, dájúdájú Òjíṣẹ́ Allāhu - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - sọ pé, “Kò sí ẹnì kan tí ó máa sálámọ̀ sí mi àfi kí Allāhu dá ẹ̀mí mi padà sí mi lára títí mo máa fi dá sálámọ̀ náà padà fún un.” Abū Dāūd ló gbà á wá lábẹ́ àkọlé: bāb ziyāratul-ƙubūr. Ṣeek al-Bāniy sọ pé, “hadīth náà dára”. Hadīth yìí tún wà nínú musnad ’Ahmad àti sunan Baehaƙiy.
Hadīth kejì: Láti ọ̀dọ̀ ’Aos ọmọ ’Aos - kí Allāhu yọ́nú sí i -, ó sọ pé, Òjíṣẹ́ Allāhu - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - sọ pé, “Dájúdájú ọjọ́ Jum‘ah wà nínú àwọn ọjọ́ yín tó lóore jùlọ; Wọ́n ṣẹ̀dá Ànábì Ādam - kí ọlà Allāhu máa bá a - nínú rẹ̀, Wọ́n gba ẹ̀mí rẹ̀ nínú rẹ̀, ìfọn àkọ́kọ́ sínú ìwo máa ṣẹlẹ̀ nínú rẹ̀. Ikú gbogbo ẹ̀dá sì máa ṣẹlẹ̀ nínú rẹ̀. Nítorí náà, ẹ ṣe ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ asọlātu fún mi nínú rẹ̀ nítorí pé, wọ́n máa ṣẹ́rí àwọn asọlātu yín sí ọ̀dọ̀ mi.” ’Aos sọ pé, àwọn Sọhābah wí pé, “Òjíṣẹ́ Allāhu, báwo ni wọ́n ṣe máa kó àwọn asọlātu wa wá bá ọ, ó ó má ti di erùpẹ̀!?” Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - sì sọ pé: “Dájúdájú Allāhu - tó ga jùlọ - ṣe ẹran ara àwọn Ànábì ní èèwọ̀ fún ilẹ̀.” Abū Dāūd ló gbà á wá lábẹ́ àkọlé: bāb fọdli yaomil-Jum‘ah walaelatil-Jum‘ah. Ṣeek al-Bāniy sọ pé, “hadīth náà ní àlàáfíà”. Hadīth yìí tún wà nínú musnad ’Ahmad àti sunan Baehaƙiy.
Àpẹ̀ẹrẹ mìíràn ni àwọn hadīth tààrà tó fẹsẹ̀ rinlẹ̀ lórí ènìyàn hóró kan ṣoṣo tí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - pè ní “Mọsīhu-ddajjāl”. Ẹni yìí má yọjú sáyé lópin ayé. Ó sì máa fòòró ayé ní ìfòòró kan tí kò tí ì ṣẹlẹ̀ rí. Àmọ́ tòhun ti bí “Mọsīhu-ddajjāl” ṣe jẹ́ ẹyọ kan nínú àwọn àmì ńlá fún òpin ayé, kò sí āyah kan tààrà lórí rẹ̀ nínú al-Ƙur’ān. Ànábì wa Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - nìkan ló jẹ́ kí á mọ̀ pé ènìyàn kan ń bọ̀ lópin ayé tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mọsīhu-ddajjāl.
Èyí sì ni ìgbàgbọ́ àti àdìsọ́kàn àwa mùsùlùmí, tòhun ti bí kò ṣe sí āyah tó gbè é lẹ́sẹ̀ tààrà nínú al-Ƙur’ān. Nígbà tí gbogbo àwa mùsùlùmí ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn irúfẹ́ àwọn hadīth òkè wọ̀nyẹn, ní ìṣẹ̀lẹ̀ tó tayọ òye wa, àmọ́ tí ó tẹnu Ànábì wa Muhammad olódodo - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - jáde, nígbà náà ta ni ẹni tí ó máa lórí láyà tako àwọn hadīth Bukọ̄riy àti hadith Muslim tó wá lórí àì tí ì kú Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - títí di àkókò yìí àti títí di àkókò òpin ayé? Ẹnikẹ́ni tí ó bá takò ó ti tako Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -. Ọ̀kan nìyí nínú àwọn hadīth náà.
Láti ọ̀dọ̀ Abū Huraerah - kí Allāhu yọ́nú sí i -, dájúdájú Òjíṣẹ́ Allāhu - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - sọ pé: “Báwo ni ẹ̀yin máa wà nígbà tí Ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - bá sọ̀kalẹ̀ sáààrin yín, tí ó sì darí yín pẹ̀lú ohun tí ń bẹ lọ́dọ̀ yín.” Ẹnì kan nínú àwọn tó gba hadīth yìí wá sọ pé, “Kí ni ìtúmọ̀ “tí ó sì darí yín pẹ̀lú ohun tí ń bẹ lọ́dọ̀ yín”? Tàbí kí ni ìtúmọ̀ “tí ohun tí ó máa fi darí yín sì máa wá láti ọ̀dọ̀ yín?” Ibnu Abī Thi’b sì fèsì pé, “Ó máa fi tírà Olúwa yín àti sunnah Ànábì yín - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - darí yín.” ni ìtúmọ̀ rẹ̀. Ìyẹn ni pé, al-Ƙur’ān àti sunnah Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ni “imām” dúró fún nínú hadīth yìí, gẹ́gẹ́ bí “imām” ṣé dúró fún “tírà” nínú sūrah Hūd; 11:17, sūrah al-’Ahƙọ̄f; 46:12 àti sūrah Yāsīn, 36:12. Bí a bá sì túmọ̀ imām sí aṣíwájú lórí ìrun àti aláṣẹ, òhun náà wọlé nítorí pé, hadīth mìíràn gbà á wá pẹ̀lú ìtúmọ̀ yẹn. Ìtúmọ̀ kìíní kejì ló ń já sí pé, ìjọ yìí kò ní Ànábì méjì, kò sì ní tírà méjì. Nítorí náà, ipò ọmọ-ẹ̀yìn ni ipò Ànábì ‘Isā - kí ọlà Allāhu máa bá a - nínú ìjọ yìí ní òpin ayé.
Les exégèses en arabe:
 
Traduction des sens Verset: (8) Sourate: AL-ANBIYÂ’
Lexique des sourates Numéro de la page
 
Traduction des sens du Noble Coran - Traduction en yorouba - Lexique des traductions

Traduction des sens du Noble Coran en langue yorouba par Cheikh Abû Rahimah Mikhaïl Aikweiny et publiée en l'an 1432 de l'Hégire.

Fermeture