Traduction des sens du Noble Coran - Traduction en yorouba * - Lexique des traductions

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Traduction des sens Verset: (46) Sourate: AL-‘ANKABOUT
۞ وَلَا تُجَٰدِلُوٓاْ أَهۡلَ ٱلۡكِتَٰبِ إِلَّا بِٱلَّتِي هِيَ أَحۡسَنُ إِلَّا ٱلَّذِينَ ظَلَمُواْ مِنۡهُمۡۖ وَقُولُوٓاْ ءَامَنَّا بِٱلَّذِيٓ أُنزِلَ إِلَيۡنَا وَأُنزِلَ إِلَيۡكُمۡ وَإِلَٰهُنَا وَإِلَٰهُكُمۡ وَٰحِدٞ وَنَحۡنُ لَهُۥ مُسۡلِمُونَ
Ẹ má ṣe bá àwọn onítírà ṣàríyàn jiyàn àfi ní ọ̀nà tó dára jùlọ (èyí ni lílo al-Ƙur’ān àti hadīth. Ẹ má sì ṣe jà wọ́n lógun) àfi àwọn tó bá ṣàbòsí nínú wọn.¹ Kí ẹ sì sọ pé: “A gbàgbọ́ nínú ohun tí Wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún àwa àti ohun tí Wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún ẹ̀yin. Ọlọ́hun wa àti Ọlọ́hun yín, (Allāhu) Ọ̀kan ṣoṣo ni. Àwa sì ni mùsùlùmí (olùjuwọ́-jusẹ̀-sílẹ̀) fún Un.”
1. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé alábòsí wulẹ̀ ni gbogbo àwọn onítírà, àbòsí mìíràn ni Allāhu ń tọ́ka sí lára wọn nínú āyah yìí. Òhun sì ni bí àwọn onítírà ṣe ń gbógun ti àwa mùsùlùmí àti bí wọ́n ṣe ń kọ̀ láti san ìsákọ́lẹ̀ fún ìjọba ’Islām lábẹ́ ìjọba ’Islām.
Les exégèses en arabe:
 
Traduction des sens Verset: (46) Sourate: AL-‘ANKABOUT
Lexique des sourates Numéro de la page
 
Traduction des sens du Noble Coran - Traduction en yorouba - Lexique des traductions

Traduction des sens du Noble Coran en langue yorouba par Cheikh Abû Rahimah Mikhaïl Aikweiny et publiée en l'an 1432 de l'Hégire.

Fermeture