Traduction des sens du Noble Coran - Traduction en yorouba * - Lexique des traductions

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Traduction des sens Verset: (4) Sourate: AL ‘IMRÂN
مِن قَبۡلُ هُدٗى لِّلنَّاسِ وَأَنزَلَ ٱلۡفُرۡقَانَۗ إِنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ بِـَٔايَٰتِ ٱللَّهِ لَهُمۡ عَذَابٞ شَدِيدٞۗ وَٱللَّهُ عَزِيزٞ ذُو ٱنتِقَامٍ
Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ́n jẹ́ ìmọ̀nà fún àwọn ènìyàn.¹ Ó tún sọ ọ̀rọ̀-ìpínyà (ọ̀rọ̀ tó ń ṣèpínyà láààrin òdodo àti irọ́) kalẹ̀.² Dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu, ìyà tó le ń bẹ fún wọn. Allāhu sì ni Alágbára, Olùgbẹ̀san.
1. Gbólóhùn yìí níí ṣepọ̀ pẹ̀lú ìjọ àti àsìkò. Ìyẹn ni pé, ìjọ ’Isrọ’īl nìkan ni tírà Taorāh àti ’Injīl jẹ́ ìmọ̀nà fún tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀. Ìjọ Ànábì Mūsā - kí ọlà Allāhu máa bá a - l’ó ni Taorāh. Ìjọ Ànábì ‘Īsā - kí ọlà Allāhu máa bá a - l’ó sì ni ’Injīl. Àmọ́ lẹ́yìn tí Allāhu - subhānahu wa ta‘āla - sọ tírà ìmọ̀nà mìíràn (al-Ƙur’ān / al-furƙọ̄n) kalẹ̀ fún Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -, ẹni tí Allāhu ṣe gbogbo ayé ní ìjọ rẹ̀, tí ó sì jẹ́ Ànábì ìkẹ́yìn, kò lẹ́tọ̀ọ́ fún ẹnikẹ́ni mọ́ láti tẹ̀lé Taorāh àti ’Injīl kan kan mọ́ àyàfi al-Ƙur’ān, gẹ́gẹ́ bí kò ṣe lẹ́tọ̀ọ́ láti tẹ̀lé Ànábì Mūsā àti Ànábì ‘Īsā lásìkò yìí àfi Ànábì ìgbà yìí, Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -. Kò wulẹ̀ sí ojúlówọ́ Taorāh àti ’Injīl ní àsìkò yìí mọ́ ní ìbámu sí sūrah al-Baƙọrah; 2:75, 79 àti sūrah al-Mọ̄’idah; 5:13 .
Nínú Sọhīh Muslim, láti ọ̀dọ̀ ’Abū Huraerah, láti ọ̀dọ̀ Òjíṣẹ́ Allāhu - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -, dájúdájú ó sọ pé: “Èmí fi Ẹni tí ẹ̀mí mi wà ní ọwọ́ Rẹ̀ búra; ẹnì kan nínú ìjọ yìí, yẹ̀húdí àti nasọ̄rọ̄, kò níí gbọ́ nípa mi, lẹ́yìn náà kí ó kú láì gba ohun tí wọ́n fi rán mi níṣẹ́ gbọ́, àfi kí ó wà nínú èrò Iná.”
Bákàn náà, nínú tírà musnad ’Ahmọd àti musọnnaf ‘Abdur-Razāƙ, láti ọ̀dọ̀ ‘Abdullāh bun Thābit - kí Allāhu yọ́nú sí i -, Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé Ànábì Mūsā - kí ọlà Allāhu máa bá a - di ẹni tí ó máa wà láààrin yín, lẹ́yìn náà tí ẹ bá tẹ̀lé e, tí ẹ sì pa mí tì, ẹ̀yin ìbá ṣìnà.”
2. Fún àlàyé lórí al-Furƙọ̄n, ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Baƙọrah; 2:53.
Les exégèses en arabe:
 
Traduction des sens Verset: (4) Sourate: AL ‘IMRÂN
Lexique des sourates Numéro de la page
 
Traduction des sens du Noble Coran - Traduction en yorouba - Lexique des traductions

Traduction des sens du Noble Coran en langue yorouba par Cheikh Abû Rahimah Mikhaïl Aikweiny et publiée en l'an 1432 de l'Hégire.

Fermeture