Traduction des sens du Noble Coran - Traduction en yorouba * - Lexique des traductions

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Traduction des sens Verset: (55) Sourate: AL ‘IMRÂN
إِذۡ قَالَ ٱللَّهُ يَٰعِيسَىٰٓ إِنِّي مُتَوَفِّيكَ وَرَافِعُكَ إِلَيَّ وَمُطَهِّرُكَ مِنَ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ وَجَاعِلُ ٱلَّذِينَ ٱتَّبَعُوكَ فَوۡقَ ٱلَّذِينَ كَفَرُوٓاْ إِلَىٰ يَوۡمِ ٱلۡقِيَٰمَةِۖ ثُمَّ إِلَيَّ مَرۡجِعُكُمۡ فَأَحۡكُمُ بَيۡنَكُمۡ فِيمَا كُنتُمۡ فِيهِ تَخۡتَلِفُونَ
(Ẹ rántí) nígbà tí Allāhu sọ pé: “‘Īsā, dájúdájú Mo máa gbà ọ́ kúrò lọ́wọ́ wọn pátápátá.¹ Mo máa gbé ọ wá sókè lọ́dọ̀ Mi. Mo sì máa fọ̀ ọ́ mọ́ lọ́dọ̀ àwọn tó ṣàì gbàgbọ́.² Mo sì máa fi àwọn tó tẹ̀lé ọ borí àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ títí di Ọjọ́ Àjíǹde. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Mi ni ibùpadàsí yín. Mo sì máa ṣe ìdájọ́ láààrin yín nípa ohun tí ẹ̀ ń yapa ẹnu sí.
1. Wọ́n ṣẹ̀dá “mutawaffi” láti ara “wafāt/wafāh.” Ìtúmọ̀ mẹ́ta ni wafāt/wafāh ní nínú al-Ƙur’ān, hadīth àti èdè Lárúbáwá. Àwọn ìtúmọ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà nìwọ̀nyí: “maot” ikú, “naom” oorun àti “ƙọbd” gbígba n̄ǹkan tàbí gbígba ẹnì kan kúrò lọ́wọ́ ẹnì kan pátápátá. Wafāt/wafāh túmọ̀ sí “maot” ikú nínú sūrah az-Zumọr; 39:42. Wafāt/wafāh túmọ̀ sí “naom” oorun nínú sūrah al-’Ani‘ām; 6:60. Wafāt/wafāh sì túmọ̀ sí “ƙọbd” gbígba ẹnì kan kúrò lọ́wọ́ ẹnì kan pátápátá nínú sūrah āli ‘Imrọ̄n; 3:55 ati sūrah al-Mọ̄’dah; 5:117. Ìdí tí wafāt/wafāh ti ‘Īsā fi túmọ̀ sí gbígba ẹnì kan kúrò lọ́wọ́ ẹnì kan pátápátá (ìyẹn, gbígbà pátápátá tí Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - gba Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - kúrò lọ́wọ́ àwọn yẹhudi tí wọ́n pète pèrò láti kàn án mọ́ orí igi àgbélébùú, òhun ni pé, Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - ti sọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà pé, àwọn yẹhudi kò rí ‘Īsā ọmọ Mọryam pa, wọn kò sì rí i kàn mọ́ igi àgbélébùú, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú sūrah an-Nisā’; 4:157-159.
Bákan náà, ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ hadīth Òjíṣẹ́ - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - tó ní àlàáfíà l’ó fi rinlẹ̀ pé ‘Īsā ọmọ Mọryam yóò padà sọ̀kalẹ̀ láti ojú sánmọ̀ ní òpin ayé láti wá ṣe àwọn iṣẹ́ ńlá ńlá kan. Kò sì níí sí rújúrújú kan kan nínú ìsọ̀kalẹ̀ ‘Īsā ọmọ Mọryam àti àwọn iṣẹ́ tí ó ń bọ̀ wá ṣe ní òpin ayé. Àmọ́ ìjọ Ahmadiyyah àti irú wọn mìíràn kò ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, wọ́n sì túmọ̀ wafāt/wafāh ti ‘Īsā ọmọ Mọryam sí ikú nítorí pé, olùdásílẹ̀ ìjọ Ahmadiyyah ti sọra rẹ̀ di ‘Īsā ọmọ Mọryam. Àwọn ìjọ Ahmadiyyah sì ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ digbí. Èyí sì tún jẹ́ ọ̀kan nínú ìdí pàtàkì tí ìjọ Ahmadiyyah fi yapa ’Islām. Wọ́n sì di kèfèrí. Ẹ kà á síwájú sí i nínú ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah an-Nisā’; 4:158.
2. Lára àṣìṣe àwọn nasọ̄rọ̄ ni bí wọ́n ṣe lérò pé àwọn gan-an ni al-Ƙur’ān ń tọ́ka sí pẹ̀lú gbólóhùn “àwọn tó tẹ̀lé ọ”, ìyẹn àwọn tó tẹ̀lé ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a -. Ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Ní àkọ́kọ́ náà, ẹlẹ́sìn ’Islām ni àwọn tó tẹ̀lé ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a -. Àti ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - àti ọ̀wọ́ àwọn tó tẹ̀lé e lójú ayé rẹ̀, mùsùlùmí ni wọ́n gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe pera wọn bẹ́ẹ̀ nínú sūrah yìí, āyah 52. Ó tún wà bẹ́ẹ̀ nínú sūrah al-Mọ̄’dah; 5:111. Àmọ́ nípa àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ lórí ọ̀rọ̀ ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a -, ìsọ̀rí mẹ́ta ni wọ́n. Ìsọ̀rí kìíní ni ìjọ yẹhudi. Àwọn di kèfèrí nípasẹ̀ bí wọn kò ṣe gba ‘Īsā gbọ́ ní Òjíṣẹ́ àti bí wọ́n ṣe pète pèrò láti kàn án mọ́ igi àgbélébùú àti láti pa á, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - kó o yọ nínú ète wọn. Ìsọ̀rí yìí gan-an ló sì jẹyọ nínú sūrah yìí láààrin āyah 52 sí 56.
Síwájú sí i, àwọn tó tẹ̀lé ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a -, tí wọ́n pera wọn ní mùsùlùmí àti àwọn yẹhudi tó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n sì fẹ́ kan ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - mọ́gi àgbélébùú; àwọn igun méjèèjì náà l’ó tún jẹyọ nínú sūrah as-Sọff; 61:14.
Lórí àwọn ìjọ mẹ́ta tó di aláìgbàgbọ́ lórí ọ̀rọ̀ ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a -, nasara ni ìjọ kejì. Wọ́n di kèfèrí nípasẹ̀ bí wọ́n ṣe sọ ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - di olúwa àti olùgbàlà lẹ́yìn Allāhu, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ‘Īsā ọmọ Mọryam kì í ṣe olúwa àti olùgbàlà fún ẹnì kan kan, kò sì pera rẹ̀ bẹ́ẹ̀ rí. Àwọn nasara wọ̀nyí ni Allāhu sọ nípa wọn nínú sūrah al-Mọ̄’idah; 5:17, 72 àti 73. Ìjọ kẹta ni ìjọ Ahmadiyyah. Wọ́n di kèfèrí nípasẹ̀ bí wọ́n ṣe gbàgbọ́ pé àwọn yẹhudi rí ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - kàn mọ́gi àgbélébùú, àmọ́ kò kú sórí rẹ̀. Ìgbàgbọ́ Ahmadiyyah yìí sì tako sūrah an-Nisā’; 4:157-159.
Les exégèses en arabe:
 
Traduction des sens Verset: (55) Sourate: AL ‘IMRÂN
Lexique des sourates Numéro de la page
 
Traduction des sens du Noble Coran - Traduction en yorouba - Lexique des traductions

Traduction des sens du Noble Coran en langue yorouba par Cheikh Abû Rahimah Mikhaïl Aikweiny et publiée en l'an 1432 de l'Hégire.

Fermeture