Traduction des sens du Noble Coran - Traduction en yorouba * - Lexique des traductions

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Traduction des sens Verset: (61) Sourate: AL ‘IMRÂN
فَمَنۡ حَآجَّكَ فِيهِ مِنۢ بَعۡدِ مَا جَآءَكَ مِنَ ٱلۡعِلۡمِ فَقُلۡ تَعَالَوۡاْ نَدۡعُ أَبۡنَآءَنَا وَأَبۡنَآءَكُمۡ وَنِسَآءَنَا وَنِسَآءَكُمۡ وَأَنفُسَنَا وَأَنفُسَكُمۡ ثُمَّ نَبۡتَهِلۡ فَنَجۡعَل لَّعۡنَتَ ٱللَّهِ عَلَى ٱلۡكَٰذِبِينَ
Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá jà ọ́ níyàn nípa rẹ̀ lẹ́yìn ohun tí ó dé bá ọ nínú ìmọ̀, kí o sọ pé: “Ẹ wá! Kí á pe àwọn ọmọkùnrin wa àti àwọn ọmọkùnrin yín àti àwọn obìnrin wa àti àwọn obìnrin yín àti àwa àti ẹ̀yin náà. Lẹ́yìn náà, kí á ṣàdúà ìparun (lórí òpùrọ́ nínú wa). Nítorí náà, a óò sọ pé, “ibi dandan (ìgbéjìnnà sí ìkẹ́) Allāhu kí ó máa jẹ́ ti àwọn òpùrọ́.”¹
1. Kíyè sí i! Āyah ìṣẹ́bilé yìí sọ̀kalẹ̀ nítorí irọ́ àwọn onítírà, bẹ́ẹ̀ náà ni a óò máa lo āyah yìí láti fi yanjú àwọn ọ̀ràn pàtàkì pàtàkì bí ọ̀ràn àdìsọ́kàn láààrin igun méjì nínú àwọn mùsùlùmí nígbàkígbà tí igun kan bá takú sórí irọ́ àti ìṣìnà lẹ́yìn ìfọ̀rọ̀wérọ̀. Irú ìṣẹ́bilé yìí ni olùdásílẹ̀ ìjọ Ahmadiyyah ṣe tí ó yíwọ́ fún un. Ikú kọ́lẹ́rà tí ó fi ṣẹ́bilé ara rẹ̀ náà ló pa á sínú ilé ìgbọ̀nsẹ̀!
Les exégèses en arabe:
 
Traduction des sens Verset: (61) Sourate: AL ‘IMRÂN
Lexique des sourates Numéro de la page
 
Traduction des sens du Noble Coran - Traduction en yorouba - Lexique des traductions

Traduction des sens du Noble Coran en langue yorouba par Cheikh Abû Rahimah Mikhaïl Aikweiny et publiée en l'an 1432 de l'Hégire.

Fermeture