Traduction des sens du Noble Coran - Traduction en yorouba * - Lexique des traductions

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Traduction des sens Verset: (37) Sourate: AL-AHZÂB
وَإِذۡ تَقُولُ لِلَّذِيٓ أَنۡعَمَ ٱللَّهُ عَلَيۡهِ وَأَنۡعَمۡتَ عَلَيۡهِ أَمۡسِكۡ عَلَيۡكَ زَوۡجَكَ وَٱتَّقِ ٱللَّهَ وَتُخۡفِي فِي نَفۡسِكَ مَا ٱللَّهُ مُبۡدِيهِ وَتَخۡشَى ٱلنَّاسَ وَٱللَّهُ أَحَقُّ أَن تَخۡشَىٰهُۖ فَلَمَّا قَضَىٰ زَيۡدٞ مِّنۡهَا وَطَرٗا زَوَّجۡنَٰكَهَا لِكَيۡ لَا يَكُونَ عَلَى ٱلۡمُؤۡمِنِينَ حَرَجٞ فِيٓ أَزۡوَٰجِ أَدۡعِيَآئِهِمۡ إِذَا قَضَوۡاْ مِنۡهُنَّ وَطَرٗاۚ وَكَانَ أَمۡرُ ٱللَّهِ مَفۡعُولٗا
(Rántí) nígbà tí ò ń sọ fún ẹni tí Allāhu ṣèdẹ̀ra fún, tí ìwọ náà ṣèdẹ̀ra fún¹ pé: “Mú ìyàwó rẹ dání, kí o sì bẹ̀rù Allāhu.” O sì ń fi pamọ́ sínú ẹ̀mí rẹ ohun tí Allāhu yó ṣàfi hàn rẹ̀. Àti pé ò ń páyà àwọn ènìyàn. Allāhu l’Ó sì lẹ́tọ̀ọ́ jùlọ pé kí o páyà Rẹ̀. Nígbà tí Zaed ti parí bùkátà rẹ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀ (tí ó sì ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀), A ti ṣe é ní ìyàwó fún ọ nítorí kí ó má baà jẹ́ láìfí fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo láti fẹ́ ìyàwó ọmọ-ọlọ́mọ tí wọ́n ń pè ní ọmọ wọn nígbà tí wọ́n bá ti parí bùkátà wọn lọ́dọ̀ wọn (tí wọ́n sì ti kọ̀ wọ́n sílẹ̀). Àṣẹ Allāhu sì gbọ́dọ̀ ṣẹ.²
1. Ẹni yìí ni Zaed ọmọ Hārithah - kí Allāhu yọ́nú sí i -. Ìdẹ̀ra Allāhu lórí rẹ̀ ni pé, Allāhu ṣe é ní mùsùlùmí. Ìdẹ̀ra Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - lórí rẹ̀ ni pé, Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - mú un kúrò lóko ẹrú. Ó sọ ọ́ di olómìnira.
2. Ohun tí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - fi pamọ́ sínú ẹ̀mí rẹ̀ ni gbólóhùn yìí: “Nígbà tí Zaed ti parí bùkátà rẹ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀ (tí ó sì ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀), A ti ṣe é ní ìyàwó fún ọ …”. Àmọ́ kàkà kí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - kéde gbólóhùn yìí fún àwọn mùsùlùmí, kí ó sì jíṣẹ́ fún Zaed, ńṣe ni Ànábì ń sọ fún un pé: “Mú ìyàwó rẹ dání...”
Ohun tí ó sì fa èyí fún Ànábì wa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ni pé, kí àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí àti àwọn aláìgbàgbọ́ má baà wí pé: “Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - l’ó fi Zaenab fún Zaed, ọmọ rẹ̀. Ó tún fi ìyàwó tí ọmọ rẹ̀ kọ̀ sílẹ̀ ṣaya…”. Zaed kì í sì ṣe ọmọ Ànábì wa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -. Hārithah ni bàbá tó bí Zaed lọ́mọ. Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ni ìdí tí àwọn aṣíwájú rere - kí Allāhu kẹ́ wọn - fi sọ pé, nínú gbogbo āyah al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé kò sí èyí tí ó lágbára lára Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - láti fi jíṣẹ́ fún àwọn ènìyàn bí kò ṣe āyah: “Nígbà tí Zaed ti parí bùkátà rẹ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀ (tí ó sì ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀), A ti ṣe é ní ìyàwó fún ọ …”. Nítorí náà, ẹ jìnnà sí àwọn ìtànkítàn tí àwọn nasọ̄rọ̄ bá ń sọ kiri nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà, kò sí èyí tí ó fẹsẹ̀ rinlẹ̀ nínú rẹ̀ àfi èyí tí A sọ sókè yìí.
Kíyè sí i, bóyá ni Ànábì tàbí Òjíṣẹ́ kan nínú àwọn Òjíṣẹ́ Allāhu - kí ọlà Allāhu máa bá wọn - wà tí àwọn ọ̀tá ẹ̀sìn ’Islām kì í sọ ìsọkúsọ nípa rẹ̀. Ìṣe àti àṣà wọn nìyẹn. Ẹni tí a sì lérò pé àwọn nasọ̄rọ̄ máa pọ́nlé, ohun tí wọ́n tún sọ nípa rẹ̀ ju fífi ẹ̀sùn ìyàwó púpọ̀ kan Ànábì wa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - àti fífẹ́ tí ó fẹ́ Zaenab tí Zaed kọ̀ sílẹ̀. Pípè tí àwọn nasọ̄rọ̄ ń pe Ànábì ‘Īsā ni ọmọ Allāhu, pípè tí wọ́n ń pè é ní ọlọ́hun ọmọ, pípè tí wọ́n ń pè é ní olúwa àti olùgbàlà, ó burú yéye ju fífi ẹ̀sùn ìyàwó púpọ̀ kan Ànábì wa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -, gẹ́gẹ́ bí Allāhu ti ṣe pe àkíyèsí wa sí aburú rẹ̀ nínú sūrah Mọryam; 19:88 - 95. Àmọ́ àwọn nasọ̄rọ̄ kò fura!
Les exégèses en arabe:
 
Traduction des sens Verset: (37) Sourate: AL-AHZÂB
Lexique des sourates Numéro de la page
 
Traduction des sens du Noble Coran - Traduction en yorouba - Lexique des traductions

Traduction des sens du Noble Coran en langue yorouba par Cheikh Abû Rahimah Mikhaïl Aikweiny et publiée en l'an 1432 de l'Hégire.

Fermeture