Traduction des sens du Noble Coran - Traduction en yorouba * - Lexique des traductions

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Traduction des sens Verset: (52) Sourate: AL-AHZÂB
لَّا يَحِلُّ لَكَ ٱلنِّسَآءُ مِنۢ بَعۡدُ وَلَآ أَن تَبَدَّلَ بِهِنَّ مِنۡ أَزۡوَٰجٖ وَلَوۡ أَعۡجَبَكَ حُسۡنُهُنَّ إِلَّا مَا مَلَكَتۡ يَمِينُكَۗ وَكَانَ ٱللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ رَّقِيبٗا
Kò lẹ́tọ̀ọ́ fún ọ (láti fẹ́) àwọn obìnrin (mìíràn) lẹ́yìn (ìsọ̀rí àwọn obìnrin tí A ti sọ ṣíwájú¹, kò sì lẹ́tọ̀ọ́ fún ọ) láti fi àwọn obìnrin (mìíràn) pààrọ̀ wọn, kódà kí dáadáa wọn jọ ọ́ lójú, àfi àwọn ẹrú rẹ. Allāhu sì ń jẹ́ Olùṣọ́ lórí gbogbo n̄ǹkan.²
1. Ìyẹn nínú āyah 50.
2. Āyah yìí kò túmọ̀ sí pé kí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - má ṣe fẹ́ ìyàwó kún àwọn ìyàwó rẹ̀ ní àsìkò tí āyah yìí sọ̀kalẹ̀, àmọ́ kò gbọ́dọ̀ fẹ́ obìnrin kan àyàfi nínú àwọn ìsọ̀rí obìnrin tí Allāhu ti ṣe ní ẹ̀tọ́ fún un nínú āyah 50.
Lẹ́yìn náà, āyah yìí kọ̀ fún Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - láti yọ èyíkéyìí ìyàwó rẹ̀ kúrò ní ipò ìyá àwọn onígbàgbọ́ òdodo nípasẹ̀ ìkọ̀sílẹ̀ àfi ìyàwó tí ó bá jẹ́ ẹrú ogun ní ìpìlẹ̀. Ìyá wa ‘Ā’iṣah - kí Allāhu yọ́nú sí i - sọ pé: “Òjíṣẹ́ Allāhu kò tí ì kú títí Allāhu fi ṣe àwọn obìnrin ayé ní ẹ̀tọ́ fún un láti fẹ́.” Ìyẹn ni pé, Òjíṣẹ́ Allāhu - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - lẹ́tọ̀ọ́ láti máa fẹ́ ìyàwó lọ́ títí ọjọ́ ikú rẹ̀.
Kíyè sí i, Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - kọ ìyá wa Hafsọh ọmọ ‘Umar sílẹ̀, lẹ́yìn náà ó fẹ́ ẹ padà. Bákan náà, Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - gbèrò láti kọ ìyá wa Saodah sílẹ̀. Èyí sì ni ó ṣokùnfà tí Saodah - kí Allāhu yọ́nú sí i - fi yọ̀ǹda ọjọ́ tirẹ̀ fún ‘Ā’iṣah - kí Allāhu yọ́nú sí i -. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ méjèèjì yìí ti ṣẹlẹ̀ ṣíwájú ìsọ̀kalẹ̀ āyah yìí. (at-Tọbariy).
Nítorí náà, kí Ànábì fẹ́ ìyàwó kún àwọn ìyàwó rẹ̀ láì ní ẹnu ààlà, láì sì gbọdọ̀ tìtorí èyí kọ òmíràn sílẹ̀, àfi ẹrú ogun, èyí tún jẹ́ n̄ǹkan ẹ̀ṣà tí Allāhu fi ṣà á lẹ́ṣà. Ìdí ni pé, òǹkà ìyàwó mùsùlùmí kò gbọdọ̀ tayọ mẹ́rin ní abẹ́ àkóṣo rẹ̀. Tí òǹkà ìyàwó Mùsùlùmí bá sì pé mẹ́rin, mùsùlùmí lè kọ ọ̀kan sílẹ̀ láti lè fi òmíràn jìrọ̀ rẹ̀, ìyẹn nígbà tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ bá jẹmọ́ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ìbẹ̀rù Allāhu tàbí ẹnì kan kú nínú wọn. Ẹ wo sūrah an-Nisā’;4:3 àti 20 - 21.
Les exégèses en arabe:
 
Traduction des sens Verset: (52) Sourate: AL-AHZÂB
Lexique des sourates Numéro de la page
 
Traduction des sens du Noble Coran - Traduction en yorouba - Lexique des traductions

Traduction des sens du Noble Coran en langue yorouba par Cheikh Abû Rahimah Mikhaïl Aikweiny et publiée en l'an 1432 de l'Hégire.

Fermeture