Check out the new design

Traduction des sens du Noble Coran - La traduction en yorouba - Aboû Raḥîmah Mickaël * - Lexique des traductions

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Traduction des sens Sourate: Az Zumar   Verset:
قُلۡ إِنِّيٓ أُمِرۡتُ أَنۡ أَعۡبُدَ ٱللَّهَ مُخۡلِصٗا لَّهُ ٱلدِّينَ
Sọ pé: “Dájúdájú Wọ́n pa mí ní àṣẹ pé kí n̄g jọ́sìn fún Allāhu lẹ́ni tí yóò máa fi àfọ̀mọ́-ọkàn (àníyàn mímọ́) ṣe ẹ̀sìn fún Un.[1]
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ āyah 2.
Les exégèses en arabe:
وَأُمِرۡتُ لِأَنۡ أَكُونَ أَوَّلَ ٱلۡمُسۡلِمِينَ
Wọ́n tún pa mí ní àṣẹ pé kí èmi jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ (nínú) àwọn mùsùlùmí (ní àsìkò tèmi).”[1]
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-’Ani‘ām; 6:14.
Les exégèses en arabe:
قُلۡ إِنِّيٓ أَخَافُ إِنۡ عَصَيۡتُ رَبِّي عَذَابَ يَوۡمٍ عَظِيمٖ
Sọ pé: “Dájúdájú èmi ń páyà ìyà ọjọ́ ńlá, tí mo bá fi lè yapa àṣẹ Olúwa mi.”
Les exégèses en arabe:
قُلِ ٱللَّهَ أَعۡبُدُ مُخۡلِصٗا لَّهُۥ دِينِي
Sọ pé: “Allāhu ni èmi yóò máa jọ́sìn fún lẹ́ni tí èmi yóò máa fi àfọ̀mọ́-ọkàn (àníyàn mímọ́) ṣe ẹ̀sìn mi fún Un
Les exégèses en arabe:
فَٱعۡبُدُواْ مَا شِئۡتُم مِّن دُونِهِۦۗ قُلۡ إِنَّ ٱلۡخَٰسِرِينَ ٱلَّذِينَ خَسِرُوٓاْ أَنفُسَهُمۡ وَأَهۡلِيهِمۡ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِۗ أَلَا ذَٰلِكَ هُوَ ٱلۡخُسۡرَانُ ٱلۡمُبِينُ
Ẹ̀yin ẹ jọ́sìn fún ohun tí ẹ bá fẹ́ lẹ́yìn Rẹ̀.”[1] Sọ pé: “Dájúdájú àwọn ẹni òfò ni àwọn tó ṣe ẹ̀mí ara wọn àti ará ilé wọn ní òfò ní Ọjọ́ Àjíǹde. Gbọ́! Ìyẹn, òhun ni òfò pọ́nńbélé.”
1. Ìyẹn ni pé, ẹ̀yin ẹ ṣe ohun tí ó bá wù yín. Kò kúkú sí ohun tí kò ní ẹ̀san.
Les exégèses en arabe:
لَهُم مِّن فَوۡقِهِمۡ ظُلَلٞ مِّنَ ٱلنَّارِ وَمِن تَحۡتِهِمۡ ظُلَلٞۚ ذَٰلِكَ يُخَوِّفُ ٱللَّهُ بِهِۦ عِبَادَهُۥۚ يَٰعِبَادِ فَٱتَّقُونِ
Àwọn àjà Iná máa wà ní òkè wọn. Àwọn àjà yó sì wà ní ìsàlẹ̀ wọn. Ìyẹn ni Allāhu fi ń dẹ́rù ba àwọn ẹrúsìn Rẹ̀ (báyìí pé:) “Ẹ̀yin ẹrúsìn Mi, ẹ bẹ̀rù Mi.”
Les exégèses en arabe:
وَٱلَّذِينَ ٱجۡتَنَبُواْ ٱلطَّٰغُوتَ أَن يَعۡبُدُوهَا وَأَنَابُوٓاْ إِلَى ٱللَّهِ لَهُمُ ٱلۡبُشۡرَىٰۚ فَبَشِّرۡ عِبَادِ
Àwọn tí wọ́n takété sí àwọn òrìṣà tí wọn kò jọ́sìn fún un,[1] wọ́n sì ṣẹ́rí padà sí (jíjọ́sìn fún) Allāhu, ìró ìdùnnú ń bẹ fún wọn. Nítorí náà, fún àwọn ẹrúsìn Mi ní ìró ìdùnnú.
1. A tún lè túmọ̀ rẹ̀ báyìí pé, “Àwọn tí wọ́n takété sí jíjọ́sìn fún àwọn òrìṣà”. Ìyẹn ni pé, àwọn tí kò bọ òrìṣà, àwọn tí kì í ṣe ẹlẹbọ́.
Les exégèses en arabe:
ٱلَّذِينَ يَسۡتَمِعُونَ ٱلۡقَوۡلَ فَيَتَّبِعُونَ أَحۡسَنَهُۥٓۚ أُوْلَٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ هَدَىٰهُمُ ٱللَّهُۖ وَأُوْلَٰٓئِكَ هُمۡ أُوْلُواْ ٱلۡأَلۡبَٰبِ
Àwọn tó ń tẹ́tí gbọ́ ọ̀rọ̀, tí wọ́n sì ń tẹ̀lé èyí tó dára jùlọ nínú rẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí Allāhu fi mọ̀nà. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni onílàákàyè.
Les exégèses en arabe:
أَفَمَنۡ حَقَّ عَلَيۡهِ كَلِمَةُ ٱلۡعَذَابِ أَفَأَنتَ تُنقِذُ مَن فِي ٱلنَّارِ
Ṣé ẹni tí ọ̀rọ̀ ìyà Iná ti kòlé lórí (nípa àìgbàgbọ́ rẹ̀, ṣé kò níí wọná ni?) Ṣé ìwọ l’ó máa la ẹni tó wà nínú Iná (nípasẹ̀ àìgbàgbọ́ rẹ̀) ni?
Les exégèses en arabe:
لَٰكِنِ ٱلَّذِينَ ٱتَّقَوۡاْ رَبَّهُمۡ لَهُمۡ غُرَفٞ مِّن فَوۡقِهَا غُرَفٞ مَّبۡنِيَّةٞ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُۖ وَعۡدَ ٱللَّهِ لَا يُخۡلِفُ ٱللَّهُ ٱلۡمِيعَادَ
Ṣùgbọ́n àwọn tó bẹ̀rù Olúwa wọn, tiwọn ni àwọn ilé gíga, tí àwọn ilé gíga tún wà lókè rẹ̀, àwọn odò yó sì máa ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Àdéhùn Allāhu ni (èyí). Allāhu kò sì níí yẹ àdéhùn náà.
Les exégèses en arabe:
أَلَمۡ تَرَ أَنَّ ٱللَّهَ أَنزَلَ مِنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءٗ فَسَلَكَهُۥ يَنَٰبِيعَ فِي ٱلۡأَرۡضِ ثُمَّ يُخۡرِجُ بِهِۦ زَرۡعٗا مُّخۡتَلِفًا أَلۡوَٰنُهُۥ ثُمَّ يَهِيجُ فَتَرَىٰهُ مُصۡفَرّٗا ثُمَّ يَجۡعَلُهُۥ حُطَٰمًاۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَذِكۡرَىٰ لِأُوْلِي ٱلۡأَلۡبَٰبِ
Ṣé o kò wòye pé dájúdájú Allāhu l’Ó sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀, Ó sì mú omi náà wọnú àwọn omi ìṣẹ́lẹ̀rú nínú ilẹ̀, lẹ́yìn náà, Ó ń fi mú irúgbìn tí àwọ̀ wọn yàtọ̀ síra wọn jáde, lẹ́yìn náà, (irúgbìn náà) yóò gbẹ, o sì máa rí i ní pípọ́n, lẹ́yìn náà, Ó máa sọ ọ́ di rírún? Dájúdájú ìrántí wà nínú ìyẹn fún àwọn onílàákàyè.
Les exégèses en arabe:
 
Traduction des sens Sourate: Az Zumar
Lexique des sourates Numéro de la page
 
Traduction des sens du Noble Coran - La traduction en yorouba - Aboû Raḥîmah Mickaël - Lexique des traductions

Traduit par Cheikh Aboû Raḥîmah Mickaël Aykwînî.

Fermeture