Traduction des sens du Noble Coran - Traduction en yorouba * - Lexique des traductions

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Traduction des sens Verset: (42) Sourate: FOUSSILAT
لَّا يَأۡتِيهِ ٱلۡبَٰطِلُ مِنۢ بَيۡنِ يَدَيۡهِ وَلَا مِنۡ خَلۡفِهِۦۖ تَنزِيلٞ مِّنۡ حَكِيمٍ حَمِيدٖ
Ìbàjẹ́ kò níí kàn án láti iwájú rẹ̀ àti láti ẹ̀yìn rẹ̀.¹ Ìmísí tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ ni láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́gbọ́n, Ẹlẹ́yìn.
1. Ìyẹn ni pé, kò sí tírà sánmọ̀ kan tí ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé irọ́ wà nínú al-Ƙur’ān ṣíwájú ìsọ̀kalẹ̀ rẹ̀. Kò sì wulẹ̀ níí sí tírà kan kan mọ́ lẹ́yìn rẹ̀ láti sánmọ̀, áḿbọ̀sìbọ́sí pé ó máa pe al-Ƙur’ān ní irọ́. Ní ṣókí, kò sí ẹni tí ó lè rí āyah kan pè ní irọ́ nínú al-Ƙur’ān. Èyí jẹ́ ààbò mímọ́ tí Allāhu - Ọba Aláààbò - fi bo al-Ƙur’ān yàtọ̀ sí àwọn tírà yòókù tó ṣíwájú rẹ̀ nítorí pé, ọwọ́kọ́wọ́ ti wọ inú wọn ní ìbámú sí sūrah al-Baƙọrah; 2:75 àti 79 àti sūrah al-Mọ̄’idah; 5:13.
Kódà ìwé kan tí àwọn nasọ̄rọ̄ ń pè ní “Bíbélì”, ohun tí àwọn òǹtẹ̀wé rẹ̀ “The Bible Societies” sọ nípa rẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ ìṣáájú tí wọ́n kọ sínú “Revised Standard Version” ni pé: “Àwọn ìwé bíbélì tí wọ́n kọ́kọ́ túmọ̀ sí èdè Gẹ̀ẹ́sì wáyé láti inú ojúlówó èdè Hébérù àti èdè Greek tààrà. Títúmọ̀ ìwé bíbélì tó sì jẹ́ àtẹ̀jáde àkọ́kọ́ ni iṣẹ́ ọwọ́ William Tyndale. Ó fojú winá àtakò tó lágbára. Wọ́n fi ẹ̀sùn kàn án pé, ó fínnú-fíndọ̀ dojú ìtúmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ inú bíbélì rú, wọ́n sì pa á láṣẹ pé kí wọ́n dáná sun àwọn májẹ̀mu titun rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe jẹ́ “àwọn ìtúmọ̀ tí kì í ṣe òdodo”. Arákùnrin náà padà bọ́ sọ́wọ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀, wọ́n pa á níta gban̄gba, wọ́n kangi ikú fún un, wọ́n sì dáná sun ún lórí rẹ̀ ní October 1536. Síbẹ̀síbẹ̀ ńkọ́, iṣẹ́ ìtúmọ̀ tí Tyndale ṣe ló padà di ìpìlẹ̀ ìtọ́kasí fún àwọn bíbélì tí wọ́n ń padà túmọ̀ sí èdè Gẹ̀ẹ́sì… Àwọn tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ìtúmọ̀ bíbélì ti King James Version ṣe àkíyèsí sí àwọn èyí tí wọ́n ti ṣe ṣíwájú; … Síbẹ̀síbẹ̀ ńkọ́, iṣẹ́ ìtúmọ̀ tí King James Version ṣe tún ní àléébù tó burú gan-an nínú. Láààrin 19 sẹ́ńtúrì, ìdàgbàsókè ẹ̀kọ́ bíbélì àti ṣíṣe àwárí àwọn àkọsílẹ̀ ìpìlẹ̀ bíbélì tí ó lọ́jọ́ lórí ju èyí tí king James Version gbé iṣẹ́ ìtúmọ̀ bíbélì tirẹ̀ lé lórí, ó fi hàn kedere pé àwọn àlèébù = wọ̀nyí pọ̀ púpọ̀ gan-an, wọ́n sì lágbára gan-an dé ibi pé ó bèèrè fún àtúnṣe àwọn ìtúmọ̀ tí wọ́n túmọ̀ bíbélì sí…”
Les exégèses en arabe:
 
Traduction des sens Verset: (42) Sourate: FOUSSILAT
Lexique des sourates Numéro de la page
 
Traduction des sens du Noble Coran - Traduction en yorouba - Lexique des traductions

Traduction des sens du Noble Coran en langue yorouba par Cheikh Abû Rahimah Mikhaïl Aikweiny et publiée en l'an 1432 de l'Hégire.

Fermeture