Traduction des sens du Noble Coran - Traduction en yorouba * - Lexique des traductions

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Traduction des sens Sourate: MOUHAMMAD   Verset:

Suuratu Muhammad

ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ وَصَدُّواْ عَن سَبِيلِ ٱللَّهِ أَضَلَّ أَعۡمَٰلَهُمۡ
Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n tún ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà Allāhu, (Allāhu) máa sọ iṣẹ́ wọn di òfò.
Les exégèses en arabe:
وَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ وَءَامَنُواْ بِمَا نُزِّلَ عَلَىٰ مُحَمَّدٖ وَهُوَ ٱلۡحَقُّ مِن رَّبِّهِمۡ كَفَّرَ عَنۡهُمۡ سَيِّـَٔاتِهِمۡ وَأَصۡلَحَ بَالَهُمۡ
Àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n ṣe àwọn iṣẹ́ rere, tí wọ́n tún gbàgbọ́ nínú ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún (Ànábì) Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -, òhun sì ni òdodo láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn, (Allāhu) máa pa àwọn (iṣẹ́) aburú wọn rẹ́, Ó sì máa ṣe àtúnṣe ọ̀rọ̀ wọn sí dáadáa.
Les exégèses en arabe:
ذَٰلِكَ بِأَنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ ٱتَّبَعُواْ ٱلۡبَٰطِلَ وَأَنَّ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ ٱتَّبَعُواْ ٱلۡحَقَّ مِن رَّبِّهِمۡۚ كَذَٰلِكَ يَضۡرِبُ ٱللَّهُ لِلنَّاسِ أَمۡثَٰلَهُمۡ
Ìyẹn (rí bẹ́ẹ̀) nítorí pé, dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ tẹ̀lé irọ́. Àti pé dájúdájú àwọn tó gbàgbọ́ tẹ̀lé òdodo láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Báyẹn ni Allāhu ṣe ń fi àpèjúwe wọn lélẹ̀ fún àwọn ènìyàn.
Les exégèses en arabe:
فَإِذَا لَقِيتُمُ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ فَضَرۡبَ ٱلرِّقَابِ حَتَّىٰٓ إِذَآ أَثۡخَنتُمُوهُمۡ فَشُدُّواْ ٱلۡوَثَاقَ فَإِمَّا مَنَّۢا بَعۡدُ وَإِمَّا فِدَآءً حَتَّىٰ تَضَعَ ٱلۡحَرۡبُ أَوۡزَارَهَاۚ ذَٰلِكَۖ وَلَوۡ يَشَآءُ ٱللَّهُ لَٱنتَصَرَ مِنۡهُمۡ وَلَٰكِن لِّيَبۡلُوَاْ بَعۡضَكُم بِبَعۡضٖۗ وَٱلَّذِينَ قُتِلُواْ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ فَلَن يُضِلَّ أَعۡمَٰلَهُمۡ
Nítorí náà, nígbà tí ẹ bá pàdé àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ (lójú ogun ẹ̀sìn), ẹ máa bẹ́ wọn lọ́rùn ǹsó títí di ìgbà tí ẹ máa fi rí wọn pa dáadáa. (Nígbà tí ọwọ́ yín bá ti bà wọ́n tán), ẹ dè wọ́n mọ́lẹ̀ sórí ìgbèkùn. Lẹ́yìn náà, ẹ lè tú wọn sílẹ̀ ní ọ̀fẹ́ tàbí kí ẹ tú wọn sílẹ̀ pẹ̀lú owó ìtúsílẹ̀ títí kò fi níí sí ogun ẹ̀sìn mọ́.1 Ìyẹn (wà bẹ́ẹ̀). Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́, ìbá gbẹ̀san fúnra Rẹ̀ (láì níí la ogun lọ), ṣùgbọ́n nítorí kí Ó lè dán apá kan yín wò lára apá kan ni. Àwọn mùsùlùmí tí wọ́n sì pa sí ojú-ọ̀nà Allāhu, Allāhu kò níí sọ iṣẹ́ wọn dòfo.
1. “títí kò fi níí sí ogun ẹ̀sìn mọ́” Ìgbà wo ni ìyẹn máa ṣẹlẹ̀ nílé ayé? Mujāhid - kí Allāhu kẹ́ ẹ - sọ pé, “Títí di ìgbà tí Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - yóò fi sọ̀kalẹ̀ láti ojú sánmọ̀ ní òpin ayé.” Ìyẹn ni pé, ó di ìgbà tí Ànábì ‘Īsā bá tó sọ̀kalẹ̀ láti ojú sánmọ̀ kí ogun ẹ̀sìn tó kásẹ̀ nílẹ̀. Ƙọtādah - kí Allāhu kẹ́ ẹ - sọ pé, “Títí di ìgbà tí kò bá sí ìbọ̀rìsà mọ́ nílé ayé.” Ibn Kathīr.
Kíyè sí i! Nígbà tí ogun ẹ̀sìn ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ní àsìkò Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -, kò sí kíkó ẹrú ogun wálé. Èyí jẹ́ òfin ìpìlẹ̀ tí ó wà nínú sūrah Al-’Anfāl; 8:67. Àmọ́ lẹ́yìn tí ọwọ́ pípa ti dun àwọn aláìgbàgbọ́ dáadáa lójú ogun ẹ̀sìn, tí àwọn èèkàn èèkan nínú wọn ti bá ogun lọ, ẹ̀tọ́ wà nígbà náà láti máa sọ wọ́n di ẹrú ogun. Èyí sì ni ó jẹyọ nínú āyah òkè yìí.
Les exégèses en arabe:
سَيَهۡدِيهِمۡ وَيُصۡلِحُ بَالَهُمۡ
Ó máa fi ọ̀nà (Ọgbà Ìdẹ̀ra) mọ̀ wọ́n. Ó sì máa tún ọ̀rọ̀ wọn ṣe sí dáadáa.
Les exégèses en arabe:
وَيُدۡخِلُهُمُ ٱلۡجَنَّةَ عَرَّفَهَا لَهُمۡ
Ó máa fi wọ́n wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra, èyí tí Ó ti fi mọ̀ wọ́n.¹
1. Allāhu - Onímọ̀ ìkọ̀kọ̀ àti gban̄gba - ti fi Ọgbà Ìdẹ̀ra Rẹ̀ mọ̀ wá pẹ̀lú oríkì kíkún àti àkàwé tó lágbára tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí ọkàn wa fi ń jẹ̀rankàn rẹ̀ pẹ̀lú ṣíṣe àwọn iṣẹ́ tí Allāhu máa fi ṣíjú àánú Rẹ̀ wò wá ní ọjọ́ Àjíǹde.
Les exégèses en arabe:
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ إِن تَنصُرُواْ ٱللَّهَ يَنصُرۡكُمۡ وَيُثَبِّتۡ أَقۡدَامَكُمۡ
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, tí ẹ bá ran (ẹ̀sìn) Allāhu lọ́wọ́, (Allāhu) máa ràn ẹ̀yin náà lọ́wọ́. Ó sì máa mú ẹsẹ̀ yín dúró ṣinṣin (nínú ẹ̀sìn).
Les exégèses en arabe:
وَٱلَّذِينَ كَفَرُواْ فَتَعۡسٗا لَّهُمۡ وَأَضَلَّ أَعۡمَٰلَهُمۡ
Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, ìparun ni fún wọn. (Allāhu) sì máa sọ iṣẹ́ wọn di òfò.
Les exégèses en arabe:
ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمۡ كَرِهُواْ مَآ أَنزَلَ ٱللَّهُ فَأَحۡبَطَ أَعۡمَٰلَهُمۡ
Ìyẹn nítorí pé, dájúdájú wọ́n kórira ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀. Nítorí náà, (Allāhu) sì ba iṣẹ́ wọn jẹ́.
Les exégèses en arabe:
۞ أَفَلَمۡ يَسِيرُواْ فِي ٱلۡأَرۡضِ فَيَنظُرُواْ كَيۡفَ كَانَ عَٰقِبَةُ ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِمۡۖ دَمَّرَ ٱللَّهُ عَلَيۡهِمۡۖ وَلِلۡكَٰفِرِينَ أَمۡثَٰلُهَا
Ṣé wọn kò rìn kiri lórí ilẹ̀ kí wọ́n wo bí ìkángun àwọn tó ṣíwájú wọn ṣe rí? Allāhu pa wọ́n rẹ́. Irú rẹ̀ tún wà fún àwọn aláìgbàgbọ́.
Les exégèses en arabe:
ذَٰلِكَ بِأَنَّ ٱللَّهَ مَوۡلَى ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَأَنَّ ٱلۡكَٰفِرِينَ لَا مَوۡلَىٰ لَهُمۡ
Ìyẹn nítorí pé dájúdájú Allāhu ni Olùrànlọ́wọ́ àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo. Dájúdájú àwọn aláìgbàgbọ́, kò sí olùrànlọ́wọ́ kan fún wọn.
Les exégèses en arabe:
إِنَّ ٱللَّهَ يُدۡخِلُ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ جَنَّٰتٖ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُۖ وَٱلَّذِينَ كَفَرُواْ يَتَمَتَّعُونَ وَيَأۡكُلُونَ كَمَا تَأۡكُلُ ٱلۡأَنۡعَٰمُ وَٱلنَّارُ مَثۡوٗى لَّهُمۡ
Dájúdájú Allāhu yóò fi àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra, èyí tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Àwọn tó sì ṣàì gbàgbọ́, àwọn ń gbádùn, wọ́n sì ń jẹ (kiri) gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹran-ọ̀sìn ṣe ń jẹ (kiri). Iná sì ni ibùgbé fún wọn.
Les exégèses en arabe:
وَكَأَيِّن مِّن قَرۡيَةٍ هِيَ أَشَدُّ قُوَّةٗ مِّن قَرۡيَتِكَ ٱلَّتِيٓ أَخۡرَجَتۡكَ أَهۡلَكۡنَٰهُمۡ فَلَا نَاصِرَ لَهُمۡ
Mélòó mélòó nínú àwọn (ará) ìlú tí ó lágbára ju (ará) ìlú rẹ, tí ó lé ọ jáde, tí A sì ti pa wọ́n rẹ́. Kò sì sí alárànṣe kan fún wọn.
Les exégèses en arabe:
أَفَمَن كَانَ عَلَىٰ بَيِّنَةٖ مِّن رَّبِّهِۦ كَمَن زُيِّنَ لَهُۥ سُوٓءُ عَمَلِهِۦ وَٱتَّبَعُوٓاْ أَهۡوَآءَهُم
Ǹjẹ́ ẹni tí ó wà lórí ẹ̀rí tó yanjú láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀, ṣé ó dà bí ẹni tí wọ́n ṣe iṣẹ́ aburú rẹ̀ ní ọ̀ṣọ́ fún, tí wọ́n sì tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn?
Les exégèses en arabe:
مَّثَلُ ٱلۡجَنَّةِ ٱلَّتِي وُعِدَ ٱلۡمُتَّقُونَۖ فِيهَآ أَنۡهَٰرٞ مِّن مَّآءٍ غَيۡرِ ءَاسِنٖ وَأَنۡهَٰرٞ مِّن لَّبَنٖ لَّمۡ يَتَغَيَّرۡ طَعۡمُهُۥ وَأَنۡهَٰرٞ مِّنۡ خَمۡرٖ لَّذَّةٖ لِّلشَّٰرِبِينَ وَأَنۡهَٰرٞ مِّنۡ عَسَلٖ مُّصَفّٗىۖ وَلَهُمۡ فِيهَا مِن كُلِّ ٱلثَّمَرَٰتِ وَمَغۡفِرَةٞ مِّن رَّبِّهِمۡۖ كَمَنۡ هُوَ خَٰلِدٞ فِي ٱلنَّارِ وَسُقُواْ مَآءً حَمِيمٗا فَقَطَّعَ أَمۡعَآءَهُمۡ
Àpèjúwe Ọgbà Ìdẹ̀ra èyí tí wọ́n ṣe ní àdéhùn fún àwọn olùbẹ̀rù Allāhu (nìyí): àwọn omi odò wà nínú rẹ̀ tí kò níí yí padà àti àwọn odò wàrà tí adùn rẹ̀ kò níí yí padà àti àwọn odò ọtí dídùn fún àwọn tó máa mu ún àti àwọn odò oyin mímọ́. Gbogbo èso wà fún wọn nínú rẹ̀ àti àforíjìn láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. (Ṣé ẹni tí ó wà nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra yìí) dà bí olùṣegbére nínú Iná bí, tí wọ́n ń fún wọn ní omi tó gbóná parí mu, tí ó sì máa já àwọn ìfun wọn pútupùtu?
Les exégèses en arabe:
وَمِنۡهُم مَّن يَسۡتَمِعُ إِلَيۡكَ حَتَّىٰٓ إِذَا خَرَجُواْ مِنۡ عِندِكَ قَالُواْ لِلَّذِينَ أُوتُواْ ٱلۡعِلۡمَ مَاذَا قَالَ ءَانِفًاۚ أُوْلَٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ طَبَعَ ٱللَّهُ عَلَىٰ قُلُوبِهِمۡ وَٱتَّبَعُوٓاْ أَهۡوَآءَهُمۡ
Ó wà nínú wọn, ẹni tí ó ń tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ rẹ títí di ìgbà tí wọ́n bá jáde kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ tán, wọn yó sì wí fún àwọn onímọ̀-ẹ̀sìn pé: “Kí l’ó sọ lẹ́ẹ̀ẹ̀ kan ná?” Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí Allāhu ti dí ọkàn wọn pa. Wọ́n sì tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn.
Les exégèses en arabe:
وَٱلَّذِينَ ٱهۡتَدَوۡاْ زَادَهُمۡ هُدٗى وَءَاتَىٰهُمۡ تَقۡوَىٰهُمۡ
Àwọn tó sì tẹ̀lé ìmọ̀nà, (Allāhu) ṣàlékún ìmọ̀nà fún wọn. Ó sì máa fún wọn ní ìbẹ̀rù wọn (nínú Allāhu).
Les exégèses en arabe:
فَهَلۡ يَنظُرُونَ إِلَّا ٱلسَّاعَةَ أَن تَأۡتِيَهُم بَغۡتَةٗۖ فَقَدۡ جَآءَ أَشۡرَاطُهَاۚ فَأَنَّىٰ لَهُمۡ إِذَا جَآءَتۡهُمۡ ذِكۡرَىٰهُمۡ
Ṣé wọ́n ń retí kiní kan bí kò ṣe Àkókò náà, tí ó máa dé bá wọn ní òjijì? Àwọn àmì rẹ̀ kúkú ti dé. Nítorí náà, báwo ni ìrántí (yó ṣe wúlò fún) wọ́n nígbà tí ó bá dé bá wọn?
Les exégèses en arabe:
فَٱعۡلَمۡ أَنَّهُۥ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا ٱللَّهُ وَٱسۡتَغۡفِرۡ لِذَنۢبِكَ وَلِلۡمُؤۡمِنِينَ وَٱلۡمُؤۡمِنَٰتِۗ وَٱللَّهُ يَعۡلَمُ مُتَقَلَّبَكُمۡ وَمَثۡوَىٰكُمۡ
Nítorí náà, mọ̀ pé dájúdájú kò sí ọlọ́hun tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Allāhu. Kí o sì tọrọ àforíjìn fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ¹ àti fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin. Allāhu mọ lílọ-bíbọ̀ yín àti ibùgbé yín.
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah Gọ̄fir; 40:55.
Les exégèses en arabe:
وَيَقُولُ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَوۡلَا نُزِّلَتۡ سُورَةٞۖ فَإِذَآ أُنزِلَتۡ سُورَةٞ مُّحۡكَمَةٞ وَذُكِرَ فِيهَا ٱلۡقِتَالُ رَأَيۡتَ ٱلَّذِينَ فِي قُلُوبِهِم مَّرَضٞ يَنظُرُونَ إِلَيۡكَ نَظَرَ ٱلۡمَغۡشِيِّ عَلَيۡهِ مِنَ ٱلۡمَوۡتِۖ فَأَوۡلَىٰ لَهُمۡ
Àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo ń sọ pé: “Kí ni kò jẹ́ kí wọ́n sọ sūrah kan kalẹ̀?” Nígbà tí wọ́n bá sọ sūrah aláìnípọ́n-na kalẹ̀,¹ tí wọ́n sì sọ ọ̀rọ̀ ogun ẹ̀sìn nínú rẹ̀, ìwọ yóò rí àwọn tí àrùn wà nínú ọkàn wọn, tí wọn yóò máa wò ọ́ ní wíwò bí ẹni pé wọ́n ti dákú lọ pọnrangandan. Ohun tí ó sì dára jùlọ fún wọn
1. Wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah āli-‘Imrọ̄n; 3:7.
Les exégèses en arabe:
طَاعَةٞ وَقَوۡلٞ مَّعۡرُوفٞۚ فَإِذَا عَزَمَ ٱلۡأَمۡرُ فَلَوۡ صَدَقُواْ ٱللَّهَ لَكَانَ خَيۡرٗا لَّهُمۡ
ni ìtẹ̀lé àṣẹ (Allāhu) àti (sísọ) ọ̀rọ̀ rere. Nígbà tí ọ̀rọ̀ náà (ìyẹn ogun ẹ̀sìn) sì ti di dandan, wọn ìbá gbà pé Allāhu sọ òdodo, ìbá dára jùlọ fún wọn.
Les exégèses en arabe:
فَهَلۡ عَسَيۡتُمۡ إِن تَوَلَّيۡتُمۡ أَن تُفۡسِدُواْ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَتُقَطِّعُوٓاْ أَرۡحَامَكُمۡ
Ó súnmọ́ pé tí ẹ̀yin bá kọ̀yìn sí ogun ẹ̀sìn, (ẹ̀ ń lọ sí oko ìparun nìyẹn, ẹ sì máa padà síbi ìwà ìgbà àìmọ̀kan) tí ẹ̀yin yóò máa ṣèbàjẹ́ lórí ilẹ̀, tí ẹ óò sì máa já okùn-ìbí yín?¹
1. Ìtúmọ̀ mìíràn fún āyah yìí, “Ó súnmọ́ pé (ẹ̀yin aláìsàn ọkàn wọ̀nyí) bí ẹ bá dé orí ipò àṣẹ, ẹ óò máa ṣèbàjẹ́ lórí ilẹ̀ àti pé ẹ óò máa já okùn-ìbí yín?”
Les exégèses en arabe:
أُوْلَٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ لَعَنَهُمُ ٱللَّهُ فَأَصَمَّهُمۡ وَأَعۡمَىٰٓ أَبۡصَٰرَهُمۡ
Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí Allāhu ti ṣẹ́bi lé. Nítorí náà, Ó di wọ́n létí pa. Ó sì fọ́ ìríran wọn.
Les exégèses en arabe:
أَفَلَا يَتَدَبَّرُونَ ٱلۡقُرۡءَانَ أَمۡ عَلَىٰ قُلُوبٍ أَقۡفَالُهَآ
Ṣé wọn kò níí ronú nípa al-Ƙur’ān ni tàbí àwọn àgádágodo ti wà lórí ọkàn wọn ni?
Les exégèses en arabe:
إِنَّ ٱلَّذِينَ ٱرۡتَدُّواْ عَلَىٰٓ أَدۡبَٰرِهِم مِّنۢ بَعۡدِ مَا تَبَيَّنَ لَهُمُ ٱلۡهُدَى ٱلشَّيۡطَٰنُ سَوَّلَ لَهُمۡ وَأَمۡلَىٰ لَهُمۡ
Dájúdájú àwọn tó pẹ̀yìn dà (sí ’Islām) lẹ́yìn tí ìmọ̀nà ti fojú hàn sí wọn, Èṣù ló ṣe ìṣìnà ní ọ̀ṣọ́ fún wọn. Ó sì fún wọn ní ìrètí asán nípa ẹ̀mí gígùn.
Les exégèses en arabe:
ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمۡ قَالُواْ لِلَّذِينَ كَرِهُواْ مَا نَزَّلَ ٱللَّهُ سَنُطِيعُكُمۡ فِي بَعۡضِ ٱلۡأَمۡرِۖ وَٱللَّهُ يَعۡلَمُ إِسۡرَارَهُمۡ
Ìyẹn nítorí pé (àwọn aláìsàn ọkàn) ń sọ fún àwọn tó kórira ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀ (ìyẹn àwọn yẹhudi) pé: “Àwa yóò tẹ̀lé yin nínú apá kan ọ̀rọ̀ náà.”¹ Allāhu sì mọ àṣírí wọn.
1. Ìyẹn ni pé, àwọn aláìsàn ọkàn nínú àwọn mùsùlùmí, ìyẹn àwọn tí wọn ń sá fún ogun ẹ̀sìn, wọ́n lọ bá àwọn yẹhudi, ìyẹn àwọn tí wọ́n kírira pé Ànábì ìkẹ́yìn dìde láààrin àwọn ọmọ Ànábì ’Ismā‘īl. Igun alágàbàǹgebè sì ń sàdéhùn àtìlẹ́yìn fún igun yẹhudi.
Les exégèses en arabe:
فَكَيۡفَ إِذَا تَوَفَّتۡهُمُ ٱلۡمَلَٰٓئِكَةُ يَضۡرِبُونَ وُجُوهَهُمۡ وَأَدۡبَٰرَهُمۡ
Báwo ni (ó ṣe máa rí fún wọn) nígbà tí àwọn mọlāika bá gba ẹ̀mí wọn, tí wọn yó sì máa lù wọ́n lójú, lù wọ́n lẹ́yìn?
Les exégèses en arabe:
ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمُ ٱتَّبَعُواْ مَآ أَسۡخَطَ ٱللَّهَ وَكَرِهُواْ رِضۡوَٰنَهُۥ فَأَحۡبَطَ أَعۡمَٰلَهُمۡ
Ìyẹn nítorí pé, dájúdájú wọ́n tẹ̀lé ohun tí ó bí Allāhu nínú. Wọ́n sì kórira ìyọ́nú Rẹ̀. Nítorí náà, Allāhu ba àwọn iṣẹ́ wọn jẹ́.
Les exégèses en arabe:
أَمۡ حَسِبَ ٱلَّذِينَ فِي قُلُوبِهِم مَّرَضٌ أَن لَّن يُخۡرِجَ ٱللَّهُ أَضۡغَٰنَهُمۡ
Tàbí àwọn tí àrùn wà nínú ọkàn wọn ń lérò pé Allāhu kò níí ṣe àfihàn àdìsọ́kàn burúkú wọn ni?
Les exégèses en arabe:
وَلَوۡ نَشَآءُ لَأَرَيۡنَٰكَهُمۡ فَلَعَرَفۡتَهُم بِسِيمَٰهُمۡۚ وَلَتَعۡرِفَنَّهُمۡ فِي لَحۡنِ ٱلۡقَوۡلِۚ وَٱللَّهُ يَعۡلَمُ أَعۡمَٰلَكُمۡ
Àti pé tí A bá fẹ́ Àwa ìbá fi wọ́n hàn ọ́, ìwọ ìbá sì mọ̀ wọ́n pẹ̀lú àmì wọn. Dájúdájú ìwọ yóò mọ̀ wọ́n níbi pé wọ́n máa ń pẹ́kọrọ ọ̀rọ̀.¹ Allāhu sì mọ àwọn iṣẹ́ (ọwọ́) yín.
1. Ìyẹn ni pé, àwọn aláìsàn-ọkàn máa ń pẹ́kọrọ nínú ìsọ̀rọ̀ wọn. Wọn kò sì níí rìn sàn-án lórí ọ̀rọ̀ nítorí àbòsí ọwọ́ wọn sì ni.
Les exégèses en arabe:
وَلَنَبۡلُوَنَّكُمۡ حَتَّىٰ نَعۡلَمَ ٱلۡمُجَٰهِدِينَ مِنكُمۡ وَٱلصَّٰبِرِينَ وَنَبۡلُوَاْ أَخۡبَارَكُمۡ
Dájúdájú A máa dan yín wò títí A fi máa ṣàfi hàn àwọn olùjagun-ẹ̀sìn àti àwọn onísùúrù nínú yín. A sì máa gbìdánwò àwọn ìró yín wò.¹
1. Àwọn ìró yín ni àwọn ìròyìn tí àwọn ènìyàn fi mọ̀ yín nípa ìṣọwọ́-ṣẹ̀sìn yín àti àwọn àdìsọ́kàn yín.
Les exégèses en arabe:
إِنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ وَصَدُّواْ عَن سَبِيلِ ٱللَّهِ وَشَآقُّواْ ٱلرَّسُولَ مِنۢ بَعۡدِ مَا تَبَيَّنَ لَهُمُ ٱلۡهُدَىٰ لَن يَضُرُّواْ ٱللَّهَ شَيۡـٔٗا وَسَيُحۡبِطُ أَعۡمَٰلَهُمۡ
Dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n sì ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, tí wọ́n tún yapa Òjíṣẹ́ Allāhu lẹ́yìn tí ìmọ̀nà ti fojú hàn sí wọn, wọn kò lè kó ìnira kiní kan bá Allāhu. (Allāhu) yó sì ba iṣẹ́ wọn jẹ́.
Les exégèses en arabe:
۞ يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ أَطِيعُواْ ٱللَّهَ وَأَطِيعُواْ ٱلرَّسُولَ وَلَا تُبۡطِلُوٓاْ أَعۡمَٰلَكُمۡ
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ tẹ̀lé (ọ̀rọ̀) Allāhu, ẹ tẹ̀lé (ọ̀rọ̀) Òjíṣẹ́ náà, kí ẹ sì má ṣe ba àwọn iṣẹ́ yín jẹ́.
Les exégèses en arabe:
إِنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ وَصَدُّواْ عَن سَبِيلِ ٱللَّهِ ثُمَّ مَاتُواْ وَهُمۡ كُفَّارٞ فَلَن يَغۡفِرَ ٱللَّهُ لَهُمۡ
Dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n sì ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, lẹ́yìn náà tí wọ́n kú nígbà tí wọ́n jẹ́ aláìgbàgbọ́, Allāhu kò níí foríjìn wọ́n.
Les exégèses en arabe:
فَلَا تَهِنُواْ وَتَدۡعُوٓاْ إِلَى ٱلسَّلۡمِ وَأَنتُمُ ٱلۡأَعۡلَوۡنَ وَٱللَّهُ مَعَكُمۡ وَلَن يَتِرَكُمۡ أَعۡمَٰلَكُمۡ
Ẹ má ṣe káàárẹ̀, kí ẹ sì má ṣe pèpè fún kòsógunmọ́, nígbà tí ẹ bá ń lékè lọ́wọ́. Allāhu wà pẹ̀lú yín; kò sì níí kó àdínkù bá ẹ̀san àwọn iṣẹ́ yín.¹
1. Lẹ́yìn tí ìtayọ ẹnu-ààlà ti wáyé láti ọ̀dọ̀ àwọn ọ̀ṣẹbọ àti àwọn ahlul-kitāb sí àwa mùsùlùmí, tí wọ́n ti fọwọ́ ara wọn fa ogun, tí Allāhu sì ti pa á láṣẹ fún àwa mùsùlùmí láti jàjà gbára fún ẹ̀sìn wa, ẹ̀mí wa àti dúkìá wa, ogun ẹ̀sìn kò níí kásẹ̀ nílẹ̀ mọ́ lórí ilẹ̀ ayé àfi pẹ̀lú ọ̀kan nínú n̄ǹkan méjì; yálà kí àwọn aláìgbàgbọ́ wọ̀nyẹn gba ’Islām nítorí pé, òhun nìkan ni ẹ̀sìn òdodo tàbí kí wọ́n máa san owó ìsákọ́lẹ̀ fún ìjọba ’Islām láì níí fi ẹ̀sìn irọ́ wọn dí àwa mùsùlùmí lọ́wọ́. Èyí ni òfin tí ó máa múlẹ̀ ní èyíkéyìí orílẹ̀-èdè ’Islām. Àmọ́ nígbà tí Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - bá sọ̀kalẹ̀ láti ojú sánmọ̀ kò níí sí owó ìsákọ́lẹ̀ mọ́ àfi gbígba ’Islām nìkan.
Les exégèses en arabe:
إِنَّمَا ٱلۡحَيَوٰةُ ٱلدُّنۡيَا لَعِبٞ وَلَهۡوٞۚ وَإِن تُؤۡمِنُواْ وَتَتَّقُواْ يُؤۡتِكُمۡ أُجُورَكُمۡ وَلَا يَسۡـَٔلۡكُمۡ أَمۡوَٰلَكُمۡ
Eré àti ìranù ni ìṣẹ̀mí ayé. (Àmọ́) tí ẹ bá gbàgbọ́ (nínú Allāhu), tí ẹ sì bẹ̀rù (Rẹ̀), Ó máa fún yín ní àwọn ẹ̀san yín. Kò sì níí bèèrè àwọn dúkìá yín (pé kí ẹ fi gbogbo rẹ̀ yọ Zakāh).
Les exégèses en arabe:
إِن يَسۡـَٔلۡكُمُوهَا فَيُحۡفِكُمۡ تَبۡخَلُواْ وَيُخۡرِجۡ أَضۡغَٰنَكُمۡ
Tí (Allāhu) bá bèèrè rẹ̀ ní ọwọ́ yín (pé, kí ẹ fi gbogbo rẹ̀ yọ Zakāh), tí Ó sì won̄koko mọ yín, ẹ máa ṣahun. Ó sì máa mú àrùn ọkàn yín jadé (àṣírí yín yó sì tú síta).
Les exégèses en arabe:
هَٰٓأَنتُمۡ هَٰٓؤُلَآءِ تُدۡعَوۡنَ لِتُنفِقُواْ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ فَمِنكُم مَّن يَبۡخَلُۖ وَمَن يَبۡخَلۡ فَإِنَّمَا يَبۡخَلُ عَن نَّفۡسِهِۦۚ وَٱللَّهُ ٱلۡغَنِيُّ وَأَنتُمُ ٱلۡفُقَرَآءُۚ وَإِن تَتَوَلَّوۡاْ يَسۡتَبۡدِلۡ قَوۡمًا غَيۡرَكُمۡ ثُمَّ لَا يَكُونُوٓاْ أَمۡثَٰلَكُم
Ẹ̀yin náà mà nìwọ̀nyí tí wọ́n ń pè láti náwó sí ojú-ọ̀nà Allāhu. Ṣùgbọ́n ẹni tó ń ṣahun wà nínú yín. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣahun, ó ṣe é fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Allāhu ni Ọlọ́rọ̀. Ẹ̀yin sì ni aláìní. Tí ẹ bá gbúnrí, (Allāhu) máa fi ìjọ mìíràn pààrọ̀ yín. Lẹ́yìn náà, wọn kò sì níí dà bí irú yín.
Les exégèses en arabe:
 
Traduction des sens Sourate: MOUHAMMAD
Lexique des sourates Numéro de la page
 
Traduction des sens du Noble Coran - Traduction en yorouba - Lexique des traductions

Traduction des sens du Noble Coran en langue yorouba par Cheikh Abû Rahimah Mikhaïl Aikweiny et publiée en l'an 1432 de l'Hégire.

Fermeture