Traduction des sens du Noble Coran - Traduction en yorouba * - Lexique des traductions

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Traduction des sens Verset: (3) Sourate: AL-MÂÏDAH
حُرِّمَتۡ عَلَيۡكُمُ ٱلۡمَيۡتَةُ وَٱلدَّمُ وَلَحۡمُ ٱلۡخِنزِيرِ وَمَآ أُهِلَّ لِغَيۡرِ ٱللَّهِ بِهِۦ وَٱلۡمُنۡخَنِقَةُ وَٱلۡمَوۡقُوذَةُ وَٱلۡمُتَرَدِّيَةُ وَٱلنَّطِيحَةُ وَمَآ أَكَلَ ٱلسَّبُعُ إِلَّا مَا ذَكَّيۡتُمۡ وَمَا ذُبِحَ عَلَى ٱلنُّصُبِ وَأَن تَسۡتَقۡسِمُواْ بِٱلۡأَزۡلَٰمِۚ ذَٰلِكُمۡ فِسۡقٌۗ ٱلۡيَوۡمَ يَئِسَ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ مِن دِينِكُمۡ فَلَا تَخۡشَوۡهُمۡ وَٱخۡشَوۡنِۚ ٱلۡيَوۡمَ أَكۡمَلۡتُ لَكُمۡ دِينَكُمۡ وَأَتۡمَمۡتُ عَلَيۡكُمۡ نِعۡمَتِي وَرَضِيتُ لَكُمُ ٱلۡإِسۡلَٰمَ دِينٗاۚ فَمَنِ ٱضۡطُرَّ فِي مَخۡمَصَةٍ غَيۡرَ مُتَجَانِفٖ لِّإِثۡمٖ فَإِنَّ ٱللَّهَ غَفُورٞ رَّحِيمٞ
A ṣe é ní èèwọ̀ fún yín ẹran òkúǹbete àti ẹ̀jẹ̀ àti ẹran ẹlẹ́dẹ̀ àti èyí tí wọ́n pa pẹ̀lú orúkọ tí kì í ṣe “Allāhu” àti ẹran tí wọ́n fún lọ́rùn pa àti ẹran tí wọ́n lù pa àti ẹran tí ó ré lulẹ̀ tí ó kú àti ẹran tí wọ́n kàn pa àti èyí tí ẹranko abìjàwàrà jẹ kù àfi èyí tí ẹ bá rí dú (ṣíwájú kí ó tó kú) àti èyí tí wọ́n pa sídìí òrìṣà. Èèwọ̀ sì ni fún yín láti yẹṣẹ́ wò.¹ Ìwọ̀nyẹn ni ìbàjẹ́. Lónìí ni àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ sọ̀rètí nù nípa ẹ̀sìn yín. Nítorí náà, ẹ má ṣe páyà wọn. Ẹ páyà Mi. Mo parí ẹ̀sìn yín fún yín lónìí. Mo sì ṣe àṣepé ìdẹ̀ra Mi fún yín. Mo sì yọ́nú sí ’Islām ní ẹ̀sìn fún yín. Nítorí náà, ẹni tí ìnira ebi bá mú (jẹ ẹran èèwọ̀) nínú ebi tó lágbára gan-an, tí kì í ṣe ẹni tí ẹ̀ṣẹ̀ ń wùú dá, dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.²
1. Ìtúmọ̀ “ wa ’an tẹstẹƙsimū bil ’azlām” ni pé “ (Èèwọ̀ sì ni fún yín láti fi àwọn ọfà kékeré mọ ìpín oore àti aburú yín nínú kádàrá yín.” Ìyẹn ni mo túmọ̀ ní ṣókí pé (Èèwọ̀ sì ni fún yín láti yẹṣẹ́ wò). Nínú ìṣe àwọn Lárúbáwá ìgbà àìmọ̀kan wọn ni pé, àwọn náà máa ń yẹṣẹ́ wò fún ìdáwọ́lé wọn àti ìṣẹ̀mí wọn. Wọ́n máa kọ “ṣe é” sára ọfà kékeré kan. Wọ́n máa tún kọ “má ṣe é” sára ọfà kékeré = = kan. Wọn kò sì níí kọ n̄ǹkan kan sára ìkẹta. Wọ́n máa kó ọfà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà sínú koto ọparun kan. Bí ó bá fẹ́ ṣe n̄ǹkan kan tí ó fẹ́ mọ bí n̄ǹkan náà yóò ṣe rí, ó máa lọ síbi koto ọparun rẹ̀. Ó máa mú ọfà kan jáde nínú mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Bí ọwọ́ rẹ̀ bá ba ọfà “ṣe é”, ó máa lọ ṣe n̄ǹkan náà pẹ̀lú àdìsọ́kàn rẹ̀ pé ó máa dára. Bí ọwọ́ rẹ̀ bá sì ba ọfà “má ṣe é”, ó máa gbé ohun tí ó fẹ́ ṣe jù sílẹ̀ pẹ̀lú àdìsọ́kà rẹ̀ pé kò níí dára. Àmọ́ bí ó bá mú ọfà èyí tí kò kọ n̄ǹkan kan sí lára, ó máa tún un mú.
’Islām sì ṣe èyí ní èèwọ̀. Nítorí náà, ohunkóhun tí wọ́n bá ń lò bí irú èyí, bíi títẹ èèpẹ̀, wíwo ìràwọ̀, fífa tẹ̀sùnbáà, dídábigba, lílo ọ̀san-ìn, dídífá, dída ọ̀pẹ̀lẹ̀, dída ẹ́ẹ̀ẹ́dínógún, lílọ nínú ẹ̀mí, ríríran, síso okùn mọ́ tákáǹdá al-Ƙur’ān àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ láti fi mọ ìkọ̀kọ̀, bíi ohun tó sọnù, ẹni tí ó jalè, ìkángun ìdáwọ́lé àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ tàbí láti fi mọ kádàrá ẹ̀dá, èèwọ̀ ni gbogbo rẹ̀ pátápátá.
2. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Baƙọrah; 2:173.
Les exégèses en arabe:
 
Traduction des sens Verset: (3) Sourate: AL-MÂÏDAH
Lexique des sourates Numéro de la page
 
Traduction des sens du Noble Coran - Traduction en yorouba - Lexique des traductions

Traduction des sens du Noble Coran en langue yorouba par Cheikh Abû Rahimah Mikhaïl Aikweiny et publiée en l'an 1432 de l'Hégire.

Fermeture