Traduction des sens du Noble Coran - Traduction en yorouba * - Lexique des traductions

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Traduction des sens Verset: (7) Sourate: AL-WÂQI’AH
وَكُنتُمۡ أَزۡوَٰجٗا ثَلَٰثَةٗ
ẹ̀yin sì máa jẹ́ oríṣi mẹ́ta.¹
1. Àwọn nasọ̄rọ̄ lérò pé āyah tó pín ẹ̀dá sí mẹ́ta ní ọjọ́ Àjíǹde tako āyah tó pín wọn sí ìjọ méjì.
Èsì: Kò sí ìtakora láààrin wọn. Nínú sūrah yìí, Allāhu - tó ga jùlọ - sọ pé oríṣi ìjọ mẹ́ta ni àwọn ẹ̀dá máa pín sí ní ọjọ́ Àjíǹde. Ìjọ ọ̀tún, ìjọ òsì àti ìjọ aṣíwájú. Àmọ́ nínú sūrah al-Balad; 90:18 - 19 àti sūrah az-Zalzalah; 99:6 - 8, Allāhu - tó ga jùlọ - pín wọn sí ìjọ méjì. Ìjọ méjì = = kúkú ni gbogbo ẹ̀dá ní ọ̀run, ìjọ ọ̀tún àti ìjọ òsì nítorí pé, Ọgbà Ìdẹ̀ra wà fún ìjọ ọ̀tún, Ọgbà Iná sì wá fún ìjọ òsì. Àmọ́, Allāhu - tó ga jùlọ - ṣe àtúnpín ìjọ ọ̀tún sí ìjọ ọ̀tún àti ìjọ aṣíwájú nítorí pé, ìgbádùn ìkíní kejì yàtọ̀ gan-an síra wọn. Ìdí nìyí tí Allāhu fi sọ nípa ìgbádùn ìjọ aṣíwájú láti āyah 10 sí āyah 26. Ó sọ nípa ìgbádùn ìjọ ọ̀tún láti āyah 27 sí āyah 40. Ó sì sọ nípa oníran-ànran ìyà ìjọ òsì láti āyah 41 sí āyah 56.
Les exégèses en arabe:
 
Traduction des sens Verset: (7) Sourate: AL-WÂQI’AH
Lexique des sourates Numéro de la page
 
Traduction des sens du Noble Coran - Traduction en yorouba - Lexique des traductions

Traduction des sens du Noble Coran en langue yorouba par Cheikh Abû Rahimah Mikhaïl Aikweiny et publiée en l'an 1432 de l'Hégire.

Fermeture