Traduction des sens du Noble Coran - Traduction en yorouba * - Lexique des traductions

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Traduction des sens Verset: (145) Sourate: AL-AN’ÂM
قُل لَّآ أَجِدُ فِي مَآ أُوحِيَ إِلَيَّ مُحَرَّمًا عَلَىٰ طَاعِمٖ يَطۡعَمُهُۥٓ إِلَّآ أَن يَكُونَ مَيۡتَةً أَوۡ دَمٗا مَّسۡفُوحًا أَوۡ لَحۡمَ خِنزِيرٖ فَإِنَّهُۥ رِجۡسٌ أَوۡ فِسۡقًا أُهِلَّ لِغَيۡرِ ٱللَّهِ بِهِۦۚ فَمَنِ ٱضۡطُرَّ غَيۡرَ بَاغٖ وَلَا عَادٖ فَإِنَّ رَبَّكَ غَفُورٞ رَّحِيمٞ
Sọ pé: “Èmi kò rí nínú ohun tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí mi tí wọ́n ṣe ní èèwọ̀ fún ẹni tí ó ń jẹ ẹ́ àfi ohun tí ó bá jẹ́ ẹran òkúǹbete tàbí ẹ̀jẹ̀ tí ó tú jáde lára ẹran (yálà nípasẹ̀ dídúńbú, gígún tàbí títalọ́fà)¹, tàbí ẹran ẹlẹ́dẹ̀ nítorí pé dájúdájú ẹ̀gbin ni, tàbí ẹran ìyapa (àṣẹ Allāhu) tí wọ́n pa pẹ̀lú pípe orúkọ mìíràn lé e lórí yàtọ̀ sí (orúkọ) Allāhu. Nítorí náà, ẹni tí ìnira (ebi) bá mú, yàtọ̀ sí ẹni tó ń wá èèwọ̀ kiri àti olùtayọ-ẹnu-ààlà,² dájúdájú Olúwa rẹ ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.³
1. Láti ọ̀dọ̀ ọmọ ‘Umọr, láti ọ̀dọ̀ Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -, ó sọ pé: “A ṣe òkúǹbete méjì àti ẹ̀jẹ̀ méjì ní ẹ̀tọ́ fún wa; òkúǹbete méjì náà ni ẹja àti tata. Ẹ̀jẹ̀ méjì náà - mo rò ó sí pé Ànábì sọ pé - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ẹ̀dọ̀ àti àwọ́n.” (Sunanul-Baehaƙiy al-Kubrọ̄; 18776)
2. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Baƙọrah; 2:173.
3. Āyah yìí kò kó gbogbo ohun jíjẹ àti ohun mímu tó jẹ́ harām sínú tán nítorí pé, Allāhu - tó ga jùlọ - kàn fi fọ èsì sí ọ̀rọ̀ ẹnu àti èrò-ọkàn àwọn ọ̀ṣẹbọ ni, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe jẹyọ ṣíwájú nínú āyah 138-139.
Lẹ́yìn náà, ohun tí Òjíṣẹ́ Rẹ̀ - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - bá ṣe ní ẹ̀tọ́ nínú hadīth rẹ̀ tó fẹsẹ̀ rinlẹ̀, ìbáà má sìí nínú al-Ƙur’ān, ẹ̀tọ́ ni nítorí sūrah al-’Ahzāb; 33:36.
Bákan náà, ohun tí Òjíṣẹ́ Rẹ̀ - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - bá ṣe ní èèwọ̀ nínú hadīth rẹ̀ tó fẹsẹ̀ rinlẹ̀, ìbáà má sìí nínú al-Ƙur’ān, èèwọ̀ ni nítorí sūrah at-Taobah; 9:29.
Irú èyí kò túmọ̀ sí ìtakora láààrin al-Ƙur’ān àti hadīth bí kò ṣe pé hadīth jẹ́ ìmísí mìíràn tó ń ṣàlàyé al-Ƙur’ān. Nípa èyí ló mú kí gbogbo ẹranko tó ní eyín ọ̀gán àti àwọn ẹyẹ tó ń fi èékánná dọdẹ àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ilé di èèwọ̀ fún jíjẹ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú hadīth Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -.
Les exégèses en arabe:
 
Traduction des sens Verset: (145) Sourate: AL-AN’ÂM
Lexique des sourates Numéro de la page
 
Traduction des sens du Noble Coran - Traduction en yorouba - Lexique des traductions

Traduction des sens du Noble Coran en langue yorouba par Cheikh Abû Rahimah Mikhaïl Aikweiny et publiée en l'an 1432 de l'Hégire.

Fermeture